MAKU 16
16
Ajinde Jesu
(Mat 28:1-8; Luk 24:1-12; Joh 20:1-20)
1Lẹ́yìn tí Ọjọ́ Ìsinmi ti kọjá, Maria Magidaleni ati Maria ìyá Jakọbu ati Salomi ra òróró ìkunra, wọ́n fẹ́ lọ fi kun òkú Jesu. 2Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, wọ́n dé ibojì bí oòrùn ti ń yọ. 3-4Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn ṣàròyé pé, “Ta ni yóo bá wa yí òkúta kúrò ní ẹnu ibojì?” Bí wọ́n ti gbé ojú sókè, wọ́n rí i pé ẹnìkan ti yí òkúta náà kúrò, bẹ́ẹ̀ ni òkúta ọ̀hún sì tóbi gan-an. 5Nígbà tí wọ́n wo inú ibojì, wọ́n rí ọdọmọkunrin kan tí ó jókòó ní apá ọ̀tún wọn, tí ó wọ aṣọ funfun. Wọ́n bá ta gìrì.
6Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ṣé Jesu ará Nasarẹti tí a kàn mọ́ agbelebu ni ẹ̀ ń wá? Ó ti jí dìde. Kò sí níhìn-ín. Ẹ wò ó! Ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí nìyí. 7Ṣugbọn ẹ lọ, ẹ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati Peteru pé ó ti lọ ṣáájú yín sí Galili, níbẹ̀ ni ẹ óo gbé rí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fun yín.”#Mat 26:32; Mak 14:28
8Nígbà tí wọ́n jáde, aré ni wọ́n sá kúrò ní ibojì náà, nítorí ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, tí wọn ń dààmú. Wọn kò sọ ohunkohun fún ẹnikẹ́ni, nítorí ẹ̀rù ń bà wọ́n.#16:8 Ẹsẹ ikẹjọ yìí ni ìparí Ìyìn Rere Jesu láti ọwọ́ Maku ninu àwọn Bibeli tí ó jẹ́ ògbólógbòó jùlọ. Ṣugbọn àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn fi gbolohun kúkúrú parí Ìyìn Rere yìí. Ọpọlọpọ Bibeli àtijọ́ ní ìparí tí ó gùn. Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn ní mejeeji, ati gbolohun kúkúrú ati èyí tí ó gùn.
(ÌPARÍ ÌYÌN RERE NÍ ṢÓKÍ)
[ 9Àwọn obinrin náà sọ ohun gbogbo tí a rán wọn fún Peteru ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní ṣókí. 10Lẹ́yìn èyí, Jesu fúnrarẹ̀ rán wọn lọ jákèjádò ayé láti kéde ìyìn rere ìgbàlà ayérayé, ìyìn rere tí ó ní ọ̀wọ̀, tí kò sì lè díbàjẹ́ lae.]
(ÌPARÍ ÌYÌN RERE TÍ Ó GÙN)
Jesu Fara han Maria Magidaleni
(Mat 28:9-10; Joh 20:11-18)
[ 9Nígbà tí Jesu jí dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, ó kọ́ fara han Maria Magidaleni, tí Jesu lé ẹ̀mí èṣù meje kúrò ninu rẹ̀ nígbà kan. 10Ó lọ sọ fún àwọn tí ó ti ń bá Jesu gbé níbi tí wọn ti ń ṣọ̀fọ̀, tí wọn ń sunkún. 11Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jesu wà láàyè ati pé Maria ti rí i, wọn kò gbàgbọ́.
Jesu Fara Han Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Meji
(Luk 24:13-35)
12Lẹ́yìn náà, ó fara han àwọn meji kan ninu wọn ní ọ̀nà mìíràn, bí wọ́n ti ń rìn lọ sí ìgbèríko kan. 13Wọ́n bá pada lọ ròyìn fún àwọn ìyókù. Sibẹ wọn kò gbàgbọ́.
Jesu Fara Han Àwọn Mọkanla
(Mat 28:16-20; Luk 24:36-49; Joh 20:19-23; A. Apo 1:6-8)
14Lẹ́yìn náà ó fara han àwọn mọkanla bí wọ́n ti ń jẹun. Ó bá wọn wí fún aigbagbọ ati ọkàn líle wọn, nítorí wọn kò gba àwọn tí wọ́n rí i, tí wọ́n sọ pé ó ti jinde gbọ́.#16:14 Bibeli àtijọ́ kan fi gbolohun yìí kún ẹsẹ 14: Ṣugbọn wọ́n wá àwáwí, wọ́n sọ fún Kristi pé, “Ìgbà wa rúdurùdu ati ti aigbagbọ yìí wà lábẹ́ Satani. Òun ni kò jẹ́ kí òtítọ́ Ọlọrun ní agbára lórí àwọn ẹ̀mí èṣù. Nítorí èyí fi òdodo rẹ hàn nisinsinyii.” Kristi dá wọn lóhùn pé, “Òpin ti dé sí iye ọdún àṣẹ Satani, ṣugbọn ohun burúkú mìíràn súnmọ́ tòsí. Nítorí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni a ṣe fi mí fún ìdájọ́ ikú, kí wọ́n lè yí pada sí òtítọ́, kí wọ́n má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́, kí wọ́n lè jogún ọlá òdodo ti ẹ̀mí aidibajẹ tí ó wà ní ọ̀run.” 15Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ máa waasu ìyìn rere fún gbogbo ẹ̀dá. 16Ẹni tí ó bá gbàgbọ́, tí ó bá ṣe ìrìbọmi, yóo ní ìgbàlà. Ẹni tí kò bá gbàgbọ́ yóo gba ìdálẹ́bi. 17Àwọn àmì tí yóo máa bá àwọn tí ó gbàgbọ́ lọ nìwọ̀nyí; wọn yóo máa lé ẹ̀mí burúkú jáde ní orúkọ mi; wọn yóo máa fi àwọn èdè titun sọ̀rọ̀; 18wọn yóo gbé ejò lọ́wọ́, wọn yóo mu òògùn olóró, ṣugbọn kò ní ṣe wọ́n léṣe; wọn yóo gbé ọwọ́ lé àwọn aláìsàn, ara wọn yóo sì dá.”
Ìgòkè-Re-Ọ̀run Ti Jesu
(Luk 24:50-53; A. Apo 1:9-11)
19Lẹ́yìn tí Jesu Oluwa ti bá wọn sọ̀rọ̀ tán, a gbé e lọ sí òkè ọ̀run, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun. 20Nígbà tí wọ́n túká lọ, wọ́n ń waasu ní ibi gbogbo, Oluwa ń bá wọ́n ṣiṣẹ́, ó ń fi ìdí ọ̀rọ̀ ìyìn rere múlẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́ àmì tí ó ń bá wọn lọ.]
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
MAKU 16: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: