MAKU 4

4
Òwe Nípa Afunrugbin
(Mat 13:1-9; Luk 8:4-8)
1Jesu tún bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan lẹ́bàá òkun. Ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi níláti bọ́ sin ọkọ̀ ojú omi kan, ó bá jókòó níbẹ̀ lójú omi. Gbogbo àwọn eniyan wà ní èbúté, wọ́n jókòó lórí iyanrìn.#Luk 5:1-3 2Ó bá ń fi òwe kọ́ wọn ní ọpọlọpọ nǹkan. Ó wí fún wọn ninu ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé:
3“Ẹ fi etí sílẹ̀! Ọkunrin kan jáde lọ láti fúnrúgbìn. 4Bí ó ti ń fúnrúgbìn lọ, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ bá wá, wọ́n ṣà á jẹ. 5Irúgbìn mìíràn bọ́ sí orí òkúta tí erùpẹ̀ díẹ̀ bò lórí. Láìpẹ́, wọ́n yọ sókè nítorí erùpẹ̀ ibẹ̀ kò jinlẹ̀. 6Nígbà tí oòrùn mú, ó jó wọn pa, nítorí wọn kò ní gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀; wọ́n bá kú. 7Irúgbìn mìíràn bọ́ sí orí ilẹ̀ ẹlẹ́gùn-ún. Nígbà tí ẹ̀gún dàgbà, ó fún wọn pa, nítorí náà wọn kò so èso. 8Irúgbìn mìíràn bọ́ sí ilẹ̀ tí ó dára, wọ́n yọ sókè, wọ́n ń dàgbà, wọ́n sì ń so èso, òmíràn ọgbọ̀n, òmíràn ọgọta, òmíràn ọgọrun-un.”
9Lẹ́yìn náà Jesu ní, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”
Ìdí Tí Jesu Fi Ń Lo Òwe
(Mat 13:10-17; Luk 8:9-10)
10Nígbà tí ó ku òun nìkan, àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila bèèrè ìtumọ̀ àwọn òwe tí ó fi ń sọ̀rọ̀. 11Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọrun, ṣugbọn bí òwe bí òwe ni fún àwọn ẹlòmíràn tí ó wà lóde.
12Kí wọn baà lè la ojú sílẹ̀
ṣugbọn kí wọn má ríran;
kí wọn gbọ́ títí
ṣugbọn kí òye má yé wọn;
kí wọn má baà ronupiwada,
kí á má baà dáríjì wọ́n.”#Ais 6:9-10
Ìtumọ̀ Òwe Nípa Afunrugbin
(Mat 13:18-23; Luk 8:11-15)
13Ó wá wí fún wọn pé, “Nígbà tí òwe yìí kò ye yín, báwo ni ẹ óo ti ṣe mọ gbogbo àwọn òwe ìyókù? 14Afunrugbin fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ ìròyìn ayọ̀. 15Àwọn wọnyi ni ti ẹ̀bá ọ̀nà, níbi tí a fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà sí: àwọn tí ó jẹ́ pé, lẹsẹkẹsẹ tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, Satani wá, ó mú ọ̀rọ̀ tí a ti fún sinu ọkàn wọn lọ. 16Bákan náà ni àwọn ẹlòmíràn dàbí irúgbìn tí a fún sórí òkúta, nígbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọn á fi inú dídùn gbà á. 17Ṣugbọn nítorí tí wọn kò ní gbòǹgbò ninu ara wọn, àkókò díẹ̀ ni ọ̀rọ̀ náà gbé ninu wọn. Nígbà tí ìyọnu tabi inúnibíni bá dé nítorí ọ̀rọ̀ náà lẹsẹkẹsẹ wọn á kùnà. 18Àwọn mìíràn dàbí irúgbìn tí a fún sórí ilẹ̀ ẹlẹ́gùn-ún, wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, 19ṣugbọn ayé, ati ìtànjẹ ọrọ̀, ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mìíràn gba ọkàn wọn, ó sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, kò sì so èso. 20Àwọn mìíràn dàbí irúgbìn tí a fún sórí ilẹ̀ rere. Àwọn yìí ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n gbà á, tí wọ́n sì so èso, òmíràn ọgbọọgbọn, òmíràn ọgọọgọta, òmíran ọgọọgọrun-un.”
Fìtílà Tí A Fi Igbá Bò
(Luk 8:16-18)
21Jesu bi wọ́n pé, “Eniyan a máa gbé fìtílà wọlé kí ó fi igbá bò ó, tabi kí ó gbé e sí abẹ́ ibùsùn? Mo ṣebí lórí ọ̀pá fìtílà ni à ń gbé e kà.#Mat 5:15; Luk 11:33 22Nítorí kò sí ohun tí a fi pamọ́ tí a kò ní gbé jáde, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun ìkọ̀kọ̀ kan tí a kò ní yọ sí gbangba.#Mat 10:26; Luk 12:2 23Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́.”
24Ó tún wí fún wọn pé, “Ẹ fi ara balẹ̀ ro ohun tí ẹ bá gbọ́. Irú òfin tí ẹ bá fi ń ṣe ìdájọ́ fún eniyan ni a óo fi ṣe ìdájọ́ fún ẹ̀yin náà pẹlu èlé.#Mat 7:2; Luk 6:38 25Nítorí ẹni tí ó bá ní, a óo tún fi fún un sí i; ẹni tí kò bá sì ní, a óo gba ìba díẹ̀ tí ó ní lọ́wọ́ rẹ̀.”#Mat 13:12; 25:29; Luk 19:26
Òwe Nípa Ìdàgbà Irúgbìn
26Ó tún wí pé, “Bí ìjọba Ọlọrun ti rí nìyí: ó dàbí ọkunrin kan tí ó gbin irúgbìn sí oko; 27ó ń sùn lálẹ́, ó ń jí ní òwúrọ̀, irúgbìn ń hù, ó ń dàgbà ní ọ̀nà tí ọkunrin náà kò mọ̀. 28Ilẹ̀ fúnra ara rẹ̀ ni ó ń mú kí ohun ọ̀gbìn so èso: yóo kọ́ rú ewé, lẹ́yìn náà èso rẹ̀ yóo gbó. 29Nígbà tí ó bá gbó tán, lẹsẹkẹsẹ ọkunrin náà yóo yọ dòjé jáde nítorí pé àkókò ìkórè ti dé.”#Joẹl 3:13.
Òwe Nípa Wóró Musitadi
(Mat 13:31-32; Luk 13:18-19)
30Ó tún bèèrè pé, “Báwo ni à bá ṣe ṣe àlàyé ìjọba Ọlọrun, tabi òwe wo ni à bá fi ṣe àkàwé rẹ̀?” 31Ó ní, “Ó dàbí wóró musitadi kan tí a gbìn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó kéré jùlọ ninu gbogbo irúgbìn, 32ṣugbọn nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbà, ó wá tóbi ju gbogbo ewébẹ̀ lọ, ó ní ẹ̀ka ńláńlá, àwọn ẹyẹ wá ń tẹ́ ìtẹ́ wọn sábẹ́ òjìji rẹ̀.”
Jesu Ń Fi Òwe Pupọ Sọ̀rọ̀
(Mat 13:34-35)
33Pẹlu ọpọlọpọ irú òwe bẹ́ẹ̀ ni Jesu fi ń sọ̀rọ̀ ìyìn rere fún wọn, gẹ́gẹ́ bí òye wọn ti mọ láti lè gbọ́. 34Kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láì lo òwe. Ṣugbọn nígbà tí ó bá ku òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, a máa túmọ̀ gbogbo rẹ̀ fún wọn.
Jesu Bá Ìgbì Omi Wí
(Mat 8:23-37; Luk 8:22-25)
35Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí èbúté ní òdìkejì òkun.” 36Wọ́n bá fi àwọn eniyan sílẹ̀, wọ́n mú un lọ pẹlu wọn ninu ọkọ̀ tí ó wà. Àwọn ọkọ̀ mìíràn wà níbẹ̀ pẹlu. 37Ìjì líle kan bá dé, omi òkun bẹ̀rẹ̀ sí bì lu ọkọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí omi fi kún inú rẹ̀. 38Jesu wà ní ẹ̀yìn ọkọ̀, ó fi ìrọ̀rí kan rọrí, ó bá sùn lọ. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ jí i, wọ́n ní, “Olùkọ́ni, o kò tilẹ̀ bìkítà bí a bá ṣègbé sinu omi!”
39Ó bá dìde lójú oorun, ó bá afẹ́fẹ́ wí, ó wí fún òkun pé, “Pa rọ́rọ́.” Afẹ́fẹ́ bá rọlẹ̀. Ìdákẹ́rọ́rọ́ bá dé. 40Ó bá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ṣe lójo bẹ́ẹ̀? Ẹ kò ì tíì ní igbagbọ sibẹ?”
41Ẹ̀rù ńlá bà wọ́n. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bi ara wọn pé, “Ta ni èyí, tí afẹ́fẹ́ ati òkun ń gbọ́ràn sí lẹ́nu!”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MAKU 4: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀