NEHEMAYA 10
10
1Àwọn tí wọ́n fi ọwọ́ sí ìwé náà tí wọ́n sì fi èdìdì dì í nìwọ̀nyí: Nehemaya, gomina, ọmọ Hakalaya, ati Sedekaya. 2Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ alufaa wọnyi: Seraya, Asaraya, ati Jeremaya, 3Paṣuri, Amaraya, ati Malikija, 4Hatuṣi, Ṣebanaya, ati Maluki, 5Harimu, Meremoti, ati Ọbadaya, 6Daniẹli, Ginetoni, ati Baruku, 7Meṣulamu, Abija, ati Mijamini, 8Maasaya, Biligai, Ṣemaaya. Àwọn ni alufaa. 9Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ Lefi wọnyi: Jeṣua ọmọ Asanaya, Binui ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Henadadi, ati Kadimieli, 10ati àwọn arakunrin wọn: Ṣebanaya ati Hodaya, Kelita, Pelaaya, ati Hanani, 11Mika, Rehobu, ati Haṣabaya, 12Sakuri, Ṣerebaya, ati Ṣebanaya, 13Hodaya, Bani, ati Beninu. 14Àwọn ìjòyè wọn tí wọ́n fọwọ́ sí ìwé náà ni: Paroṣi, Pahati Moabu, Elamu, Satu, ati Bani, 15Bunni, Asigadi, ati Bebai, 16Adonija, Bigifai, ati Adini, 17Ateri, Hesekaya ati Aṣuri, 18Hodaya, Haṣumu, ati Besai, 19Harifi, Anatoti, ati Nebai, 20Magipiaṣi, Meṣulamu, ati Hesiri, 21Meṣesabeli, Sadoku, ati Jadua, 22Pelataya, Hanani, ati Anaaya, 23Hoṣea, Hananaya, ati Haṣubu, 24Haloheṣi, Pileha, ati Ṣobeki, 25Rehumu, Haṣabina, ati Maaseaya, 26Ahija, Hanani, ati Anani, 27Maluki, Harimu, ati Baana.
Àdéhùn náà
28Àwọn eniyan yòókù, àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, àwọn aṣọ́nà, àwọn akọrin, àwọn iranṣẹ tẹmpili ati àwọn tí wọ́n ti ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí òfin Ọlọrun, àwọn iyawo wọn, àwọn ọmọ wọn ọkunrin, àwọn ọmọ wọn obinrin, gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́njú mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, 29wọ́n parapọ̀ pẹlu àwọn arakunrin wọn ati àwọn ọlọ́lá wọn; wọ́n gégùn-ún, wọ́n sì búra pé àwọn ó máa pa òfin Ọlọrun mọ́, àwọn óo sì máa tẹ̀lé e, bí Mose iranṣẹ rẹ̀ ti fún wọn. Wọ́n óo máa ṣe gbogbo ohun tí OLUWA tíí ṣe Oluwa wọn paláṣẹ, wọn ó sì máa tẹ̀lé ìlànà ati òfin rẹ̀.
30A kò ní fi àwọn ọmọ wa obinrin fún àwọn ọmọ àwọn àlejò tí ń gbé ilẹ̀ wa, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní fẹ́ àwọn ọmọbinrin wọn fún àwọn ọmọ wa. #Eks 34:16; Diut 7:3
31Bí wọn bá sì kó ọjà tabi oúnjẹ wá tà ní ọjọ́ ìsinmi, a kò ní rà á lọ́wọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi tabi ní ọjọ́ mímọ́ kankan.
A óo sì yọ̀ǹda gbogbo èso ọdún keje keje, ati gbogbo gbèsè tí eniyan bá jẹ wá. #(a) Eks 23:10-11; Lef 25:1-7 (b) Diut 15:1-2
32A óo sì tún fẹnu kò sí ati máa dá ìdámẹ́ta ṣekeli wá fún iṣẹ́ ilé Ọlọrun wa lọdọọdun. #Eks 30:11-16
33A óo máa pèsè burẹdi ìfihàn ati ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo, ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, ẹbọ ọjọ́ ìsinmi, ati ti oṣù tuntun fún àwọn àsè tí wọ́n ti là sílẹ̀, ati fún gbogbo ohun mímọ́, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli kúrò, ati fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọrun wa.
34A ti dìbò láàrin àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn eniyan, bí wọn yóo ṣe máa ru igi wá sí ilé Ọlọrun wa, ní oníléjilé, ní ìdílé ìdílé, ní àwọn àkókò tí a yàn lọdọọdun, tí wọn yóo fi máa rúbọ lórí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin.
35A ti gbà á bí ojúṣe wa pé àkọ́so èso ilẹ̀ wa ati àkọ́so gbogbo èso igi wa lọdọọdun, ni a óo máa gbé wá sí ilé OLUWA. #Eks 23:19; 34:26; Diut 26:2
36A óo máa mú àwọn àkọ́bí ọmọ wa, ati ti àwọn mààlúù wa lọ sí ilé Ọlọrun wa, fún àwọn alufaa tí wọn ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àkọ́já ewébẹ̀ wa, ati àkọ́bí àwọn ẹran ọ̀sìn wa. 37Bẹ́ẹ̀ náà ni ìyẹ̀fun tí a kọ́kọ́ kù, ati ọrẹ wa, èso gbogbo igi, ọtí waini, ati òróró. A óo máa kó wọn tọ àwọn alufaa lọ sí gbọ̀ngàn ilé Ọlọrun wa. #Eks 13:2
A óo sì máa mú ìdámẹ́wàá èso ilẹ̀ wa lọ fún àwọn ọmọ Lefi, nítorí pé àwọn ọmọ Lefi ni wọ́n máa ń gba ìdámẹ́wàá káàkiri gbogbo ilẹ̀ wa. 38Àwọn alufaa, ọmọ Aaroni yóo wà pẹlu àwọn ọmọ Lefi nígbà tí àwọn ọmọ Lefi bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Lefi yóo yọ ìdámẹ́wàá gbogbo ìdámẹ́wàá tí wọ́n bá gbà lọ sí ilé Ọlọrun wa. Wọn óo kó o sinu gbọ̀ngàn ninu ilé ìpa-nǹkan-mọ́-sí. 39Àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ọmọ Lefi yóo dá oúnjẹ, waini ati òróró jọ sinu àwọn gbọ̀ngàn, níbi tí àwọn ohun èlò tí a ti yà sí mímọ́ fún lílò ní ilé Ọlọrun wa, pẹlu àwọn alufaa tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ati àwọn olùṣọ́ tẹmpili, ati àwọn akọrin. #Nọm 18:21 #Nọm 18:26
A kò ní fi ọ̀rọ̀ ilé Ọlọrun wa falẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
NEHEMAYA 10: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: