NỌMBA 15
15
Àwọn Òfin nípa Ìrúbọ
1OLUWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, 2bí ẹ bá dé ilẹ̀ tí mo fún yín láti máa gbé, 3tí ẹ bá mú ninu agbo ẹran yín láti fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA tabi láti fi san ẹ̀jẹ́, tabi láti fi rú ẹbọ àtinúwá, tabi ẹbọ ní ọjọ́ àjọ yín, láti pèsè òórùn dídùn fún OLUWA; 4ẹni tí ó fẹ́ rúbọ yóo tọ́jú ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi idamẹrin òṣùnwọ̀n hini òróró kan pò fún ẹbọ ohun jíjẹ; 5ati idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ọtí fún ẹbọ ohun mímu, pẹlu ẹbọ sísun tabi ẹbọ ọ̀dọ́ aguntan kan. 6Fún ẹbọ àgbò, yóo wá ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi ìdámẹ́ta òṣùnwọ̀n hini òróró kan pò wá, 7pẹlu ìdámẹ́ta òṣùnwọ̀n hini ọtí fún ẹbọ ohun mímu; yóo jẹ́ òórùn dídùn sí OLUWA. 8Bí ẹ bá mú akọ mààlúù wá fún ọrẹ ẹbọ sísun, tabi fún ìrúbọ láti san ẹ̀jẹ́ tabi fún ẹbọ alaafia sí OLUWA, 9ẹ óo mú ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi ìdajì òṣùnwọ̀n hini òróró kan pò wá, 10pẹlu ìdajì òṣùnwọ̀n hini ọtí waini kan, fún ẹbọ ohun mímu, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun. Yóo jẹ́ òórùn dídùn sí OLUWA.
11“Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe pẹlu akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan tabi àgbò kọ̀ọ̀kan tabi ọ̀dọ́ àgbò kọ̀ọ̀kan tabi ọmọ aguntan kọ̀ọ̀kan. 12Ẹ óo mú àwọn nǹkan tí a kà sílẹ̀ wá pẹlu olukuluku ẹran tí ẹ bá fẹ́ fi rúbọ. 13Nígbà tí àwọn ọmọ onílẹ̀ bá fẹ́ rú ẹbọ sísun, tí ó jẹ́ òórùn dídùn sí OLUWA, wọn óo tẹ̀lé ìlànà yìí. 14Bí àjèjì kan tí ń gbé ààrin yín, tabi ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrin yín bá fẹ́ rú ẹbọ sísun, tí ó jẹ́ òórùn dídùn sí OLUWA, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóo tẹ̀lé ìlànà tí mo fi lélẹ̀ fun yín, ìlànà yìí yóo wà fún ìrandíran yín. 15Ìlànà kan náà ni yóo wà fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ati àwọn àjèjì tí wọ́n wà láàrin yín. Ìlànà yìí yóo wà títí lae ní ìrandíran yín. Bí ẹ ti rí níwájú OLUWA, bẹ́ẹ̀ náà ni àjèjì tí ó wà láàrin yín rí. 16Òfin ati ìlànà kan náà ni yóo wà fún ẹ̀yin ati àjèjì tí ń gbé pẹlu yín.”#Lef 24:22.
17OLUWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, 18Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí mò ń mu yín lọ, 19tí ẹ bá jẹ ninu oúnjẹ ilẹ̀ náà, ẹ óo mú ọrẹ wá fún OLUWA. 20Ẹ mú ọrẹ wá fún OLUWA lára àwọn àkàrà tí ẹ kọ́kọ́ ṣe gẹ́gẹ́ bí ọrẹ láti ibi ìpakà. 21Lára àwọn àkàrà tí ẹ bá kọ́kọ́ ṣe ni ẹ óo máa mú wá fi ṣe ọrẹ fún OLUWA ní ìrandíran yín.
22“Ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò pa àwọn òfin wọnyi, tí OLUWA fún Mose mọ́, 23àní àwọn òfin tí OLUWA tipasẹ̀ Mose fún yín, láti ọjọ́ tí OLUWA ti fún un ní òfin títí lọ, ní ìrandíran yín; 24bí gbogbo ìjọ eniyan Israẹli bá ṣẹ̀, láìmọ̀, wọn óo fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan rú ẹbọ sísun, olóòórùn dídùn sí OLUWA, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà. 25Alufaa yóo ṣe ètùtù fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli, a óo sì dáríjì wọ́n nítorí pé àṣìṣe ni; wọ́n sì ti mú ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wá fún OLUWA nítorí àṣìṣe wọn. 26A óo dáríjì gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ati àwọn àjèjì tí ń gbé ààrin wọn nítorí pé gbogbo wọn ni ó lọ́wọ́ sí àṣìṣe náà.
27“Bí ẹnikẹ́ni bá ṣẹ̀ láìmọ̀, yóo fi abo ewúrẹ́ ọlọ́dún kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. 28Alufaa yóo ṣe ètùtù niwaju pẹpẹ fún olúwarẹ̀ tí ó ṣe àṣìṣe, a óo sì dáríjì í.#Lef 4:27-31 29Òfin kan náà ni ó wà fún gbogbo àwọn tí o bá ṣẹ̀ láìmọ̀, ìbáà ṣe ọmọ Israẹli tabi àjèjì tí ń gbé láàrin ilẹ̀ Israẹli.
30“Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́nmọ̀ ṣẹ̀, kò náání OLUWA, ìbáà ṣe ọmọ Israẹli tabi àjèjì tí ń gbé láàrin wọn, a óo yọ olúwarẹ̀ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀; 31nítorí pé ó pẹ̀gàn ọ̀rọ̀ OLUWA, kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, a óo yọ ọ́ kúrò patapata, ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ yóo sì wà lórí rẹ̀.”
Ẹni Tí Ó Rú Òfin Ọjọ́ Ìsinmi
32Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli wà ninu aṣálẹ̀, wọ́n rí ọkunrin kan tí ń ṣẹ́gi ní ọjọ́ ìsinmi; 33àwọn tí wọ́n rí i mú un wá sọ́dọ̀ Mose ati Aaroni ati gbogbo ìjọ eniyan. 34Wọ́n fi sí àhámọ́ nítorí wọn kò tíì mọ ohun tí wọn yóo ṣe sí i. 35OLUWA sọ fún Mose pé, “Pípa ni kí ẹ pa ọkunrin náà, kí gbogbo ìjọ eniyan sọ ọ́ lókùúta pa lẹ́yìn ibùdó.” 36Gbogbo ìjọ eniyan bá mú un lọ sẹ́yìn ibùdó, wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta pa gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.
Òfin nípa Kókó Etí Aṣọ
37OLUWA sọ fún Mose pé, 38“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n ṣe oko jọnwọnjọnwọn sí etí aṣọ wọn ní ìrandíran wọn; kí wọ́n sì ta okùn aláwọ̀ aró mọ oko jọnwọnjọnwọn kọ̀ọ̀kan.#Diut 22:12 39Èyí ni ẹ óo máa wọ̀, tí yóo máa rán yín létí àwọn òfin OLUWA, kí ẹ lè máa pa wọ́n mọ́; kí ẹ má fi ìwọ̀ra tẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn yín ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú yín. 40Kí ẹ lè máa ranti àwọn òfin mi, kí ẹ máa pa wọ́n mọ́, kí ẹ sì jẹ́ ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọrun yín. 41Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín tí ó ko yín jáde wa láti ilẹ̀ Ijipti, láti jẹ́ Ọlọrun yín: Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
NỌMBA 15: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: