NỌMBA 21
21
Ìṣẹ́gun lórí Àwọn Ará Kenaani
1Nígbà tí ọba Aradi ará Kenaani tí ń gbé ìhà gúsù ní Nẹgẹbu Kenaani gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ń gba ọ̀nà Atarimu bọ̀, ó lọ bá wọn jagun, ó sì kó ninu wọn lẹ́rú. #Nọm 33:40 2Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ pé, Bí ó bá ti àwọn lẹ́yìn tí àwọn bá ṣẹgun àwọn eniyan náà, àwọn óo pa àwọn eniyan náà run patapata. 3OLUWA gbọ́ ohùn àwọn ọmọ Israẹli, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣẹgun àwọn ará Kenaani. Wọ́n run àwọn ati àwọn ìlú wọn patapata. Àwọn ọmọ Israẹli sì sọ ibẹ̀ ní Horima.
Ejò Idẹ
4Àwọn ọmọ Israẹli gbéra láti òkè Hori, wọ́n gba ọ̀nà Òkun Pupa, láti yípo lọ lẹ́yìn ilẹ̀ Edomu. Ṣugbọn sùúrù tán àwọn eniyan náà lójú ọ̀nà, #Diut 2:1 5wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun ati Mose, wọ́n ní, “Kí ló dé tí ẹ fi kó wa wá láti Ijipti, pé kí á wá kú ninu aṣálẹ̀ yìí? Kò sí oúnjẹ, kò sí omi, burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ yìí ti sú wa.” 6OLUWA bá rán ọpọlọpọ ejò amúbíiná sí àwọn eniyan náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bù wọ́n jẹ, ọpọlọpọ ninu wọn sì kú. #1 Kọr 10:9 7Wọ́n bá wá sọ́dọ̀ Mose, wọ́n ní, “A ti ṣẹ̀ nítorí tí a ti sọ̀rọ̀ òdì sí OLUWA ati sí ọ. Gbadura sí OLUWA kí ó mú ejò wọnyi kúrò lọ́dọ̀ wa.” Mose bá gbadura fún àwọn eniyan náà. 8OLUWA sọ fún Mose pé, “Fi idẹ rọ ejò amúbíiná kan, kí o gbé e kọ́ sórí ọ̀pá gígùn kan, ẹnikẹ́ni tí ejò bá bù jẹ, tí ó bá wo ejò idẹ náà yóo yè.” 9Mose bá rọ ejò idẹ kan, ó gbé e kọ́ sórí ọ̀pá gígùn kan, ẹnikẹ́ni tí ejò bá bù jẹ, tí ó bá ti wò ó, a sì yè. #2A. Ọba 18:4; Joh 3:14.
Láti Òkè Hori sí Àfonífojì Moabu
10Àwọn ọmọ Israẹli ṣí kúrò níbẹ̀, wọ́n pa àgọ́ wọn sí Obotu. 11Lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Obotu wọ́n pa àgọ́ sí Òkè-Abarimu ní aṣálẹ̀ tí ó wà níwájú Moabu, ní ìhà ìlà oòrùn. 12Wọ́n gbéra láti ibẹ̀, wọ́n lọ pa àgọ́ sí àfonífojì Seredi. 13Wọ́n tún ṣí kúrò ní àfonífojì Seredi, wọ́n pa àgọ́ wọn sí òdìkejì odò Arinoni, tí ó wà ní aṣálẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ láti agbègbè àwọn ará Amori. Odò Arinoni jẹ́ ààlà ilẹ̀ Moabu, ó wà láàrin ilẹ̀ Moabu ati ilẹ̀ Amori. 14Nítorí náà ni a ṣe kọ ọ́ sinu Ìwé Ogun OLUWA pé:
“Ìlú Wahebu ní agbègbè Sufa,
ati àwọn àfonífojì Arinoni,
15ati ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn àfonífojì náà
tí ó lọ títí dé ìlú Ari,
tí ó lọ dé ààlà Moabu.”
16Láti ibẹ̀, wọ́n ṣí lọ sí Beeri, níbi kànga tí ó wà níbẹ̀ ni OLUWA ti sọ fún Mose pé, “Pe àwọn eniyan náà jọ, n óo sì fún wọn ní omi.” 17Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí pe:
“Ẹ sun omi jáde, ẹ̀yin kànga!
Ẹ máa kọrin sí i!
18Kànga tí àwọn ọmọ aládé gbẹ́,
tí àwọn olórí wà
pẹlu ọ̀pá àṣẹ ọba ati ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ wọn.”
Wọ́n sì ṣí kúrò níbẹ̀ lọ sí aṣálẹ̀ Matana. 19Láti Matana, wọ́n ṣí lọ sí Nahalieli, láti Nahalieli wọ́n ṣí lọ sí Bamotu, 20láti Bamotu wọ́n ṣí lọ sí àfonífojì tí ó wà ní ilẹ̀ àwọn Moabu ní ìsàlẹ̀ òkè Pisiga tí ó kọjú sí aṣálẹ̀.
Ìṣẹ́gun lórí Ọba Sihoni ati Ọba Ogu
(Diut 2:26–3:11)
21Àwọn ọmọ Israẹli bá ranṣẹ sí Sihoni ọba àwọn ará Amori pé, 22“Jọ̀wọ́, gbà wá láàyè láti gba orí ilẹ̀ rẹ kọjá. Àwa ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa kò ní yà kúrò ní ojú ọ̀nà wọ inú oko yín, tabi ọgbà àjàrà yín. Bẹ́ẹ̀ ni a kò ní mu omi kànga yín. Ojú ọ̀nà ọba ni a óo máa rìn títí a óo fi la ilẹ̀ rẹ kọjá.” 23Sihoni kò gbà kí àwọn ọmọ Israẹli gba orí ilẹ̀ rẹ̀ kọjá. Ṣugbọn ó kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n sì bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní Jahasi ninu aṣálẹ̀. 24Àwọn ọmọ Israẹli pa pupọ ninu wọn, wọ́n gba ilẹ̀ wọn láti odò Arinoni lọ dé odò Jaboku títí dé ààlà àwọn ará Amoni. Wọn kò gba ilẹ̀ àwọn ará Amoni nítorí pé wọ́n jẹ́ alágbára. 25Àwọn ọmọ Israẹli gba gbogbo ìlú àwọn ará Amori, Heṣiboni ati àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè rẹ̀, wọ́n sì ń gbé inú wọn. 26Heṣiboni ni olú ìlú Sihoni, ọba àwọn ará Amori. Ọba yìí ni ó bá ọba Moabu jà, ó sì gba ilẹ̀ rẹ̀ títí dé odò Arinoni. 27Ìdí èyí ni àwọn akọrin òwe ṣe ń kọrin pé:
“Wá sí Heṣiboni!
Jẹ́ kí á tẹ ìlú ńlá Sihoni dó,
kí á sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.
28Ní àkókò kan, láti ìlú Heṣiboni,
àwọn ọmọ ogun Sihoni jáde lọ bí iná;
wọ́n run ìlú Ari ní Moabu,
ati àwọn oluwa ibi gíga Arinoni.
29Ẹ̀yin ará Moabu, ẹ gbé! #Jer 48:45-46
Ẹ di ẹni ìparun, ẹ̀yin ọmọ oriṣa Kemoṣi!
Ó ti sọ àwọn ọmọkunrin yín di ẹni tí ń sálọ fún ààbò;
ó sì sọ àwọn ọmọbinrin yín di ìkógun
fún Sihoni ọba àwọn ará Amori.
30Ṣugbọn nisinsinyii, a ti pa ìrandíran wọn run,
láti Heṣiboni dé Diboni,
láti Naṣimu dé Nofa lẹ́bàá Medeba.”
31Àwọn ọmọ Israẹli sì tẹ̀dó sí ilẹ̀ àwọn ará Amori. 32Mose rán eniyan lọ ṣe amí Jaseri, wọ́n sì gba àwọn ìlú agbègbè rẹ̀, wọ́n lé àwọn ará Amori tí ń gbé inú rẹ̀ kúrò.
33Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣí, wọ́n gba ọ̀nà Baṣani. Ogu ọba Baṣani sì bá wọn jagun ní Edirei. 34Ṣugbọn OLUWA sọ fún Mose pé, “Má bẹ̀rù rẹ̀, mo ti fi òun ati ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Kí o ṣe é bí o ti ṣe Sihoni ọba àwọn ará Amori tí ń gbé Heṣiboni.” 35Àwọn ọmọ Israẹli pa Ogu ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati gbogbo eniyan rẹ̀. Wọn kò dá ẹnìkan sí, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
NỌMBA 21: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: