FILEMONI 1
1
1Èmi Paulu, ẹlẹ́wọ̀n nítorí ti Kristi Jesu, ati Timoti, arakunrin wa, ni à ń kọ ìwé yìí sí Filemoni, àyànfẹ́ wa ati alábàáṣiṣẹ́ wa, 2ati sí Afia, arabinrin wa ati sí Akipu: ọmọ-ogun ẹlẹgbẹ́ wa fún Kristi, ati sí ìjọ tí ó wà ninu ilé rẹ̀.#Kol 4:17
3Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu yín ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa, ati Oluwa Jesu Kristi.
Ìfẹ́ ati Igbagbọ Tí Filemoni Ní
4Nígbà gbogbo tí mo bá ń ranti rẹ ninu adura ni mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun. 5Mò ń gbọ́ ìròyìn ìfẹ́ ati igbagbọ tí o ní sí Oluwa Jesu, ati sí gbogbo àwọn onigbagbọ. 6Adura mi ni pé kí àjọṣepọ̀ tàwa-tìrẹ ninu igbagbọ lè ṣiṣẹ́, láti mú kí òye rẹ pọ̀ sí i nípa gbogbo ohun rere tí a ní ninu Kristi. 7Nítorí mo láyọ̀ pupọ, mo sì ní ìwúrí lọpọlọpọ nípa ìfẹ́ rẹ. Nítorí ohun tí ò ń ṣe ti tu àwọn onigbagbọ lára, arakunrin mi.
Ẹ̀bẹ̀ fún Onisimu
8Nítorí náà, bí mo tilẹ̀ ní ìgboyà pupọ ninu Kristi láti pàṣẹ ohun tí ó yẹ fún ọ, 9ṣugbọn nítorí ìfẹ́ tí ó wà láàrin wa, ẹ̀bẹ̀ ni n óo kúkú bẹ̀. Èmi Paulu, ikọ̀ Kristi, tí mo di ẹlẹ́wọ̀n nisinsinyii nítorí ti Kristi Jesu, 10mò ń bẹ̀ ọ́ nítorí ti ọmọ mi, Onisimu, ọmọ tí mo bí ninu ẹ̀wọ̀n.#Kol 4:9 11Nígbà kan rí kò wúlò fún ọ. Ṣugbọn nisinsinyii ó wúlò fún ọ ati fún mi.
12Òun ni mò ń rán pada sí ọ. Ó wá dàbí ẹni pé mò ń fi ọkàn èmi pàápàá ranṣẹ sí ọ. 13Ǹ bá dá a dúró, kó máa wà lọ́dọ̀ mi, kí ó lè máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi dípò rẹ lákòókò tí mo wà ninu ẹ̀wọ̀n nítorí iṣẹ́ ìyìn rere. 14Ṣugbọn n kò fẹ́ dá nǹkankan ṣe láìjẹ́ pé o lọ́wọ́ sí i, n kò fẹ́ kí ó jẹ́ pé túlààsì ni oore tí mo fẹ́ kí o ṣe. Inú rẹ ni mo fẹ́ kí ó ti wá.
15Bóyá ìdí nìyí tí ó fi sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà díẹ̀, kí o lè jèrè rẹ̀ ní gbogbo ìgbà; 16kì í tún ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú mọ́, ṣugbọn ní ipò tí ó ga ju ti ẹrú lọ, bí àyànfẹ́ arakunrin, tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi, ṣugbọn tí ó ṣọ̀wọ́n fún ọ jù mí lọ, gẹ́gẹ́ bí eniyan sí eniyan ati gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ.
17Nítorí náà bí o bá kà mí sí ẹni tí a jọ gba nǹkankan náà gbọ́, kí o gbà á pada tọwọ́-tẹsẹ̀ bí ẹni pé èmi alára ni o gbà. 18Ohunkohun tí ó bá ti ṣe sí ọ láìdára, tabi ohun tí ó bá jẹ ọ́, èmi ni kí o kà á sí lọ́rùn. 19Èmi, Paulu, ni mo fi ọwọ́ ara mi kọ ọ́ pé, n óo san án pada fún ọ. Kò tún nílò kí n sọ fún ọ pé ìwọ fúnrarẹ, o jẹ mí ní gbèsè ara rẹ. 20Arakunrin mi, mo fẹ́ kí o yọ̀ǹda ọ̀rọ̀ yìí fún mi nítorí Oluwa. Fi ọkàn mi balẹ̀ ninu Kristi.
21Pẹlu ìdánilójú pé o óo ṣe bí mo ti wí ni mo fi kọ ìwé yìí sí ọ; mo sì mọ̀ pé o óo tilẹ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. 22Ó ku nǹkankan: Tọ́jú ààyè sílẹ̀ dè mí, nítorí mo ní ìrètí pé, nípa adura yín, Ọlọrun yóo jẹ́ kí wọ́n dá mi sílẹ̀ fun yín.
Ìdágbére
23Epafirasi, ẹlẹ́wọ̀n ẹlẹgbẹ́ mi nítorí ti Kristi Jesu, kí ọ.#Kol 1:7; 4:12, 24Bẹ́ẹ̀ ni Maku, ati Arisitakọsi, ati Demasi ati Luku, àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi.#a A. Apo 12:12, 25; 13:13; 15:37-39; Kol 4:10; b A. Apo 19:29; 27:2; Kol 4:10; d Kol 4:14; 2 Tim 4:10, e Kol 4:14; 2 Tim 4:11
25Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu ẹ̀mí yín.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
FILEMONI 1: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: