FILIPI 1
1
Ìkíni
1Èmi Paulu ati Timoti, àwa iranṣẹ Kristi Jesu.
À ń kọ ìwé yìí sí gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun tí ó wà ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu, tí wọ́n wà ní Filipi pẹlu gbogbo àwọn alabojuto ati àwọn olùrànlọ́wọ́ wọn.#A. Apo 16:12
2Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa wa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu yín.
Adura fún Àwọn Ará Filipi
3Nígbà gbogbo tí mo bá ranti yín ni mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun mi. 4Nígbà gbogbo ni mò ń gbadura fún gbogbo yín pẹlu ayọ̀ ninu ọkàn mi. 5Nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ títí di àkókò yìí ni ẹ ti ń bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ ninu iṣẹ́ ìyìn rere. 6Ó dá mi lójú pé ẹni tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere ninu yín yóo ṣe é dé òpin títí di ọjọ́ tí Kristi Jesu yóo dé. 7Ẹ̀tọ́ ni fún mi láti ní irú èrò yìí nípa gbogbo yín, nítorí mo kó ọ̀rọ̀ yín lékàn. Nítorí pé nígbà tí mo wà ninu ẹ̀wọ̀n ati ìgbà tí mo ní anfaani láti gbèjà ara mi ati láti fi ìdí ọ̀rọ̀ ìyìn rere múlẹ̀, gbogbo yín ni ẹ jẹ́ alájọpín oore-ọ̀fẹ́ Kristi pẹlu mi. 8Mo fi Ọlọrun ṣe ẹ̀rí pé àárò gbogbo yín ń sọ mí, pẹlu ọkàn ìyọ́nú ti Kristi Jesu.
9Adura mi ni pé kí ìfẹ́ yín máa gbòòrò sí i, kí ìmọ̀ yín máa pọ̀ sí i, kí ẹ túbọ̀ máa ní làákàyè sí i, 10kí ẹ lè mọ àwọn ohun tí ó dára jùlọ. Kí ẹ lè jẹ́ aláìlábùkù, kí ẹ sì wà láìsí ohun ìkùnà kan ní ọjọ́ tí Kristi bá dé. 11Mo tún gbadura pé kí ẹ lè kún fún èso iṣẹ́ òdodo tí ó ti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi wá fún ògo ati ìyìn Ọlọrun.
Ìgbé-Ayé ninu Kristi
12Ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi mú kí iṣẹ́ ìyìn rere túbọ̀ tàn kalẹ̀ ni. 13Ó ti wá hàn sí gbogbo àwọn tí ó wà ní ààfin ati gbogbo àwọn eniyan yòókù pé nítorí ti Kristi ni mo ṣe wà ninu ẹ̀wọ̀n. 14Èyí fún ọpọlọpọ ninu àwọn onigbagbọ tí wọ́n mọ ìdí tí mo fi wà ninu ẹ̀wọ̀n ní ìgboyà gidigidi láti máa waasu ìyìn rere láì bẹ̀rù.
15Àwọn ẹlòmíràn ń waasu Kristi nítorí owú ati nítorí pé wọ́n fẹ́ràn asọ̀. Àwọn ẹlòmíràn sì wà tí wọn ń waasu Kristi pẹlu inú rere. 16Àwọn kan ń fi ìfẹ́ waasu Kristi nítorí wọ́n mọ̀ pé nítorí ti ọ̀rọ̀ ìyìn rere ni wọ́n ṣe sọ mí sẹ́wọ̀n.#A. Apo 28:30 17Àwọn kan ń sọ̀rọ̀ Kristi nítorí ohun tí wọn óo rí gbà níbẹ̀, kì í ṣe pẹlu inú kan, wọ́n rò pé àwọn lè mú kí ìrora mi ninu ẹ̀wọ̀n pọ̀ sí i.
18Kí ni àyọrísí gbogbo èyí? Lọ́nà kan tabi lọ́nà mìíràn, ìbáà ṣe pẹlu ẹ̀tàn ni, tabi pẹlu òtítọ́ inú, a sá ń waasu Kristi, èyí ni ó mú inú mi dùn. Inú mi yóo sì máa dùn ni, 19nítorí mo mọ̀ pé àyọrísí rẹ̀ ni pé a óo dá mi sílẹ̀ nípa adura yín ati nípa àtìlẹ́yìn Ẹ̀mí Jesu Kristi, 20gẹ́gẹ́ bí igbẹkẹle ati ìrètí mi pé n kò ní rí ohun ìtìjú kan. Ṣugbọn bí mo ti máa ń gbé Kristi ga ninu ara mi pẹlu ìgboyà nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ gan-an náà ni n óo tún máa gbé e ga nisinsinyii ìbáà jẹ́ pé mo wà láàyè tabi pé mo kú. 21Nítorí pé Kristi ni mo wà láàyè fún ní tèmi, bí mo bá sì kú, èrè ni ó jẹ́. 22Bí mo bá wà láàyè ninu ẹran-ara, iṣẹ́ tí ó lérè ni ó jẹ́ fún mi. N kò tilẹ̀ mọ èyí tí ǹ bá yàn. 23Ọkàn mi ń ṣe meji; ọkàn mi kan fẹ́ pé kí á dá mi sílẹ̀, kí n lọ sọ́dọ̀ Jesu, nítorí èyí ni ó dára jùlọ. 24Ṣugbọn ó tún ṣàǹfààní bí mo bá wà láàyè ninu ẹran-ara, nítorí tiyín. 25Èyí dá mi lójú, nítorí náà mo mọ̀ pé n óo wà láàyè. Bí mo bá wà ní ọ̀dọ̀ gbogbo yín, yóo mú ìlọsíwájú ati ayọ̀ ninu igbagbọ wá fun yín. 26Èyí yóo mú kí ìṣògo yín ninu Kristi Jesu lè pọ̀ sí i nítorí mi, nígbà tí mo bá tún yọ si yín.
27Nǹkankan tí ó ṣe pataki ni pé kí ẹ jẹ́ kí ìwà yín kí ó jẹ́ irú èyí tí ó bá ìyìn rere Kristi mu, tí ó jẹ́ pé bí mo bá wá tí mo ri yín, tabi bí n kò bá lè wá ṣugbọn tí mò ń gbúròó yín, kí n gbọ́ pé ẹ wà pọ̀ ninu ẹ̀mí kan ati ọkàn kan, ati pé gbogbo yín ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹlu igbagbọ ninu iṣẹ́ ìyìn rere. 28Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀rù àwọn alátakò bà yín rárá ninu ohunkohun. Èyí ni yóo jẹ́ ẹ̀rí ìparun wọn, yóo sì jẹ́ ẹ̀rí ìgbàlà yín. Ọlọrun ni yóo ṣe é. 29Nítorí anfaani ni èyí fun yín, kì í ṣe pé kí ẹ gba Kristi gbọ́ nìkan ni, ṣugbọn pé ẹ̀ ń jìyà fún Kristi. 30Irú ìyà kan náà tí ẹ rí ninu ìgbé-ayé mi, tí ẹ tún ń gbọ́ pé mò ń jẹ títí di àkókò yìí ni ẹ̀yin náà ń jẹ báyìí.#A. Apo 16:19-40
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
FILIPI 1: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: