ÌWÉ ÒWE 17
17
1Kí á fi alaafia jẹun, láìsí ọbẹ̀,
ó sàn ju kí á máa fi ẹran jẹun pẹlu ìyọnu lọ.
2Ẹrú tí ó bá mọ ìwà hù, yóo di ọ̀gá lórí ọmọ tí ń hùwà ìbàjẹ́,
yóo sì jókòó pín ninu ogún bí ẹni pé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ni.
3Iná ni a fi ń dán fadaka ati wúrà wò,
ṣugbọn OLUWA ní ń dán ọkàn wò.
4Aṣebi a máa tẹ́tí sí ẹni ibi,
òpùrọ́ a sì máa fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ìkà.
5Ẹni tí ń fi talaka ṣẹ̀sín, ẹlẹ́dàá talaka ní ń tàbùkù,
ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí wahala ẹni ẹlẹ́ni kò ní lọ láìjìyà.
6Ọmọ ọmọ ni adé arúgbó,
òbí sì ni ògo àwọn ọmọ.
7Ọ̀rọ̀ rere ṣe àjèjì sí ẹnu òmùgọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni irọ́ pípa kò yẹ àwọn olórí.
8Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ dàbí òògùn ajẹ́-bí-idán lójú ẹni tí ń fúnni,
ibi gbogbo tí olúwarẹ̀ bá lọ ni ó ti ń ṣe àṣeyege.
9Ẹni tí ń dárí ji ni ń wá ìfẹ́,
ẹni tí ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ a máa ya ọ̀rẹ́ nípá.
10Ìbáwí a máa dun ọlọ́gbọ́n
ju kí wọ́n nà òmùgọ̀ ní ọgọrun-un pàṣán lọ.
11Ọ̀tẹ̀ ṣá ni ti eniyan burúkú ní gbogbo ìgbà,
ìkà òjíṣẹ́ ni a óo sì rán sí i.
12Ó sàn kí eniyan pàdé ẹranko beari tí a kó lọ́mọ,
ju kí ó pàdé òmùgọ̀ ninu agọ̀ rẹ̀ lọ.
13Ẹni tí ó fibi san oore,
ibi kò ní kúrò ninu ilé rẹ̀ lae.
14Ìbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí kí eniyan ya odò tí wọn sé,
dá a dúró kí ó tó di ńlá.
15Ẹni tí ń gbé àre fún ẹlẹ́bi
ati ẹni tí ń gbé ẹ̀bi fún aláre,
OLUWA kórìíra ekinni-keji wọn.
16Owó kò wúlò lọ́wọ́ òmùgọ̀ pé kí ó fi ra ọgbọ́n,
nígbà tí kò ní òye?
17Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo,
ṣugbọn a bí arakunrin láti dúró tini ní ìgbà ìpọ́njú.
18Ẹni tí kò bá gbọ́n níí jẹ́jẹ̀ẹ́,
láti ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀.
19Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀,
ẹni tí ó bá fẹ́ràn kí á máa fi owó ṣe àṣehàn ń wá ìparun.
20Ẹni tí ó ní ọkàn ẹ̀tàn kò ní ṣe àṣeyege,
ẹlẹ́nu meji yóo bọ́ sinu ìyọnu.
21Ìbànújẹ́ ni kí eniyan bí ọmọ tí kò gbọ́n,
kò sí ayọ̀ fún baba òmùgọ̀.
22Ọ̀yàyà jẹ́ òògùn tí ó dára fún ara,
ṣugbọn ìbànújẹ́ a máa mú kí eniyan rù.
23Eniyan burúkú a máa gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ níkọ̀kọ̀,
láti yí ìdájọ́ po.
24Ẹni tí ó ní òye a máa tẹjúmọ́ ọgbọ́n,
ṣugbọn ojú òmùgọ̀ kò gbé ibìkan,
ó ń wo òpin ilẹ̀ ayé.
25Òmùgọ̀ ọmọ jẹ́ ìbànújẹ́ baba rẹ̀,
ati ọgbẹ́ ọkàn fún ìyá tí ó bí i.
26Kò tọ̀nà láti fi ipá mú aláìṣẹ̀ san owó ìtanràn,
nǹkan burúkú ni kí á na gbajúmọ̀ tí kò rú òfin.
27Ẹni tí ó bá ní ìmọ̀ a máa kó ahọ́n rẹ̀ ní ìjánu,
ẹni tí ó bá jẹ́ olóye eniyan a máa ṣe jẹ́ẹ́.
28A máa ka òmùgọ̀ pàápàá kún ọlọ́gbọ́n,
bí ó bá pa ẹnu rẹ̀ mọ́,
olóye ni àwọn eniyan yóo pè é,
bí ó bá panu mọ́ tí kò sọ̀rọ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌWÉ ÒWE 17: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010