ORIN DAFIDI 101

101
Ìlérí Ọba
1N óo kọrin ìfẹ́ ati ìdájọ́ òdodo,
OLUWA, ìwọ ni n óo máa kọrin ìyìn sí.
2N óo múra láti hu ìwà pípé pẹlu ọgbọ́n;
nígbà wo ni o óo wá sọ́dọ̀ mi?
N óo máa fi tọkàntọkàn rin ìrìn pípé ninu ilé mi.
3N kò ní gba nǹkan burúkú láyè níwájú mi.
Mo kórìíra ìṣe àwọn tí wọ́n tàpá sí Ọlọrun.
N kò sì ní bá wọn lọ́wọ́ sí nǹkankan.
4Èròkérò yóo jìnnà sí ọkàn mi,
n kò sì ní ṣe ohun ibi kankan,
5Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ níbi,
n óo pa á run,
n kò sì ní gba alágbèéré ati onigbeeraga láàyè.
6N óo máa fi ojurere wo àwọn olóòótọ́ ní ilẹ̀ náà,
kí wọ́n lè máa bá mi gbé;
ẹni tí ó bá sì ń hu ìwà pípé ni yóo máa sìn mí.
7Ẹlẹ́tàn kankan kò ní gbé inú ilé mi;
bẹ́ẹ̀ ni òpùrọ́ kankan kò ní dúró níwájú mi.
8Ojoojumọ ni n óo máa pa àwọn eniyan burúkú run ní ilẹ̀ náà,
n óo lé gbogbo àwọn aṣebi kúrò ninu ìlú OLUWA.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 101: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀