ORIN DAFIDI 106
106
Oore OLUWA fún Àwọn Eniyan Rẹ̀
1Ẹ yin OLUWA!
Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun
nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.#1Kron 16:34; 2Kron 5:13; 7:3; Ẹsr 3:11; O. Daf 100:5; 107:1; 118:1; 136:1; Jer 33:11
2Ta ló lè sọ iṣẹ́ agbára OLUWA tán?
Ta ló sì lè fi gbogbo ìyìn rẹ̀ hàn?
3Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣe ẹ̀tọ́,
àwọn tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà nígbà gbogbo.
4Ranti mi, OLUWA, nígbà tí o bá ń
ṣí ojurere wo àwọn eniyan rẹ.
Ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń gbà wọ́n là.
5Kí n lè rí ire àwọn àyànfẹ́ rẹ
kí n lè ní ìpín ninu ayọ̀ àwọn eniyan rẹ,
kí n sì lè máa ṣògo pẹlu àwọn tí ó jẹ́ eniyan ìní rẹ.
6A ti ṣẹ̀, àtàwa, àtàwọn baba wa,
a ti ṣe àìdára, a sì ti hùwà burúkú.
7Nígbà tí àwọn baba ńlá wa wà ní Ijipti,
wọn kò náání iṣẹ́ ìyanu rẹ,
wọn kò sì ranti bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ti pọ̀ tó.
Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo lẹ́bàá òkun pupa.
8Sibẹsibẹ, ó gbà wọ́n là, nítorí orúkọ rẹ̀;
kí ó lè fi títóbi agbára rẹ̀ hàn.
9Ó bá òkun pupa wí, òkun pupa gbẹ,
ó sì mú wọn la ibú já bí ẹni rìn ninu aṣálẹ̀.
10Ó gbà wọ́n là lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wọn,
ó sì kó wọn yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.
11Omi bo àwọn ọ̀tá wọn,
ẹyọ ẹnìkan kò sì là.
12Nígbà náà ni wọ́n tó gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́,
wọ́n sì kọrin yìn ín.#Eks 14:10-12 #Eks 14:21-23 #Eks 15:1-21
13Kò pẹ́ tí wọ́n tún fi gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀,
wọn kò sì dúró gba ìmọ̀ràn rẹ̀.
14Wọ́n ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ní aṣálẹ̀,
wọ́n sì dán Ọlọrun wò.
15Ó fún wọn ní ohun tí wọ́n bèèrè,
ṣugbọn ó fi àìsàn ajẹnirun ṣe wọ́n.#Nọm 11:4-34
16Nígbà tí wọ́n ṣe ìlara sí Mose ninu ibùdó,
ati sí Aaroni, ẹni mímọ́ OLÚWA.
17Ilẹ̀ yanu, ó gbé Datani mì,
ó sì bo Abiramu ati àwọn tí ó tẹ̀lé e mọ́lẹ̀.
18Iná sọ láàrin wọn,
ó sì jó àwọn eniyan burúkú náà run.#Nọm 16:1-35
19Wọ́n yá ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù ní Horebu,
wọ́n sì bọ ère tí wọ́n dà.
20Wọ́n gbé ògo Ọlọrun
fún ère mààlúù tí ń jẹ koríko.
21Wọ́n gbàgbé Ọlọrun, Olùgbàlà wọn,
tí ó ṣe iṣẹ́ ribiribi ní Ijipti,
22ó ṣe, iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu,
ati ohun ẹ̀rù lẹ́bàá òkun pupa.
23Nítorí náà ni ó ṣe wí pé òun yóo pa wọ́n run,
bí kì í bá ṣe ti Mose, àyànfẹ́ rẹ̀,
tí ó dúró níwájú rẹ̀, tí ó sì ṣìpẹ̀,
láti yí ibinu OLUWA pada, kí ó má baà pa wọ́n run.#Eks 32:1-14
24Wọn kò bìkítà fún ilẹ̀ dáradára náà,
wọn kò sì ní igbagbọ ninu ọ̀rọ̀ OLUWA.
25Wọ́n ń kùn ninu àgọ́ wọn,
wọn kò sì fetí sí ohùn OLUWA.
26Nítorí náà, ó gbé ọwọ́ sókè, ó búra fún wọn
pé òun yóo jẹ́ kí wọ́n kú sí aṣálẹ̀,#Nọm 14:1-35
27ati pé òun yóo fọ́n àwọn ìran wọn káàkiri
àwọn orílẹ̀-èdè.#Lef 26:33
28Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali ti Peori,
wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí wọ́n rú sí òkú.
29Wọ́n fi ìwà burúkú wọn mú OLUWA bínú,
àjàkálẹ̀ àrùn sì bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn.
30Nígbà náà ni Finehasi dìde, ó bẹ̀bẹ̀ fún wọn,
àjàkálẹ̀ àrùn sì dáwọ́ dúró.
31A sì kà á kún òdodo fún un,
láti ìrandíran títí lae.#Nọm 25:1-13
32Wọ́n mú OLUWA bínú lẹ́bàá omi Meriba,
wọ́n sì fi tiwọn kó bá Mose,
33nítorí wọ́n mú Mose bínú,
ọ̀rọ̀ tí kò yẹ sì ti ẹnu rẹ̀ jáde.#Nọm 20:2-13
34Wọn kò pa àwọn eniyan ilẹ̀ náà run,
gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún wọn,
35ṣugbọn wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè náà,
wọ́n sì kọ́ ìṣe wọn.
36Wọ́n bọ àwọn oriṣa wọn,
èyí sì fa ìpalára fún wọn.#A. Ada 2:1-3; 3:5-6
37Wọ́n fi àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn bọ oriṣa.#2A. Ọba 17:17
38Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,
àní, ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkunrin,
ati ti àwọn ọmọbinrin wọn,
tí wọ́n fi bọ àwọn oriṣa ilẹ̀ Kenaani;
wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ sọ ilẹ̀ náà di aláìmọ́.#Nọm 35:33
39Nítorí náà, wọ́n fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́,
wọ́n sì sọ ara wọn di alágbèrè.
40Nígbà náà ni inú bí OLUWA sí àwọn eniyan rẹ̀,
ó sì kórìíra àwọn ẹni ìní rẹ̀.
41Ó fi wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lọ́wọ́,
títí tí àwọn tí ó kórìíra wọn fi jọba lé wọn lórí.
42Àwọn ọ̀tá wọn ni wọ́n lára,
wọ́n sì fi agbára mú wọn sìn.
43Ọpọlọpọ ìgbà ni ó gbà wọ́n sílẹ̀,
ṣugbọn wọ́n ti pinnu láti máa tàpá sí i,
OLUWA sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
44Sibẹsibẹ, ninu ìnira wọn, ó ṣàánú wọn,
nígbà tí ó gbọ́ igbe wọn.
45Nítorí tiwọn, ó ranti majẹmu tí ó dá,
ó sì yí ìpinnu rẹ̀ pada nítorí ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.
46Ó jẹ́ kí àánú wọn ṣe gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn.#A. Ada 2:14-18
47Gbà wá, OLUWA, Ọlọrun wa,
kí o sì kó wa kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,
kí á lè máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ,
kí á sì lè máa ṣògo ninu ìyìn rẹ.
48Ẹni ìyìn ni OLUWA, Ọlọrun Israẹli,
lae ati laelae.
Kí gbogbo eniyan máa wí pé, “Amin!”#1Kron 16:35-36
Ẹ yin OLUWA!
ÌWÉ ORIN KARUN-UN
(Orin Dafidi 107–150)
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 106: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010