ORIN DAFIDI 107:8-9

ORIN DAFIDI 107:8-9 YCE

Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún àwọn ọmọ eniyan. Nítorí pé ó fi omi tẹ́ àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ lọ́rùn, ó sì fi oúnjẹ dáradára bọ́ àwọn tí ebi ń pa ní àbọ́yó.