ORIN DAFIDI 119
119
Òfin OLUWA
1Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ìgbé ayé wọn kò lábàwọ́n,
àní àwọn tí ń rìn gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA.
2Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́,
tí wọn ń fi tọkàntọkàn ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
3Àwọn tí wọn kò dẹ́ṣẹ̀,
ṣugbọn tí wọn ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
4O ti pàṣẹ pé kí á fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́,
5Ìbá ti dára tó
tí mo bá lè dúró ṣinṣin ninu ìlànà rẹ!
6Òun ni ojú kò fi ní tì mí,
nítorí pé òfin rẹ ni mò ń tẹ̀lé.
7N óo yìn ọ́ pẹlu inú mímọ́,
bí mo ṣe ń kọ́ ìlànà òdodo rẹ.
8N óo máa pa òfin rẹ mọ́,
má kọ̀ mí sílẹ̀ patapata.
Pípa Òfin OLUWA mọ́
9Báwo ni ọdọmọkunrin ṣe lè mú kí ọ̀nà rẹ̀ mọ́?
Nípa títẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ ni.
10Tọkàntọkàn ni mo fi ń ṣe ìfẹ́ rẹ,
má jẹ́ kí n ṣìnà kúrò ninu òfin rẹ.
11Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ sọ́kàn,
kí n má baà ṣẹ̀ ọ́.
12Ìyìn ni fún ọ, OLUWA,
kọ́ mi ní ìlànà rẹ!
13Mo fi ẹnu mi kéde gbogbo àṣẹ tí o pa.
14Mo láyọ̀ ninu pípa òfin rẹ mọ́,
bí ẹni tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀.
15N óo máa ṣe àṣàrò ninu òfin rẹ,
n óo sì kọjú sí ọ̀nà rẹ.
16N óo láyọ̀ ninu àwọn ìlànà rẹ,
n kò ní gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ.
Ayọ̀ ninu Òfin OLUWA
17Ṣe ọpọlọpọ oore fún èmi iranṣẹ rẹ,
kí n lè wà láàyè,
kí n sì máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
18Là mí lójú, kí n lè rí àwọn nǹkan ìyanu
tí ó wà ninu òfin rẹ.
19Àlejò ni mí láyé,
má fi òfin rẹ pamọ́ fún mi.
20Òùngbẹ títẹ̀lé òfin rẹ ń gbẹ ọkàn mi, nígbà gbogbo.
21O bá àwọn onigbeeraga wí, àwọn ẹni ègún,
tí wọn kò pa òfin rẹ mọ́.
22Mú ẹ̀gàn ati àbùkù wọn kúrò lára mi,
nítorí pé mo ti pa òfin rẹ mọ́.
23Bí àwọn ìjòyè tilẹ̀ gbìmọ̀ràn ọ̀tẹ̀ nítorí mi,
sibẹ, èmi iranṣẹ rẹ yóo ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ.
24Àwọn òfin rẹ ni dídùn inú mi,
àwọn ni olùdámọ̀ràn mi.
Ìpinnu láti Pa Òfin OLUWA mọ́
25Mo di ẹni ilẹ̀,
sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
26Nígbà tí mo jẹ́wọ́ gbogbo ìṣe mi, o dá mi lóhùn;
kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
27La òfin rẹ yé mi,
n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí iṣẹ́ ìyanu rẹ.
28Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi nítorí ìbànújẹ́,
mú mi lọ́kàn le gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
29Mú ìwà èké jìnnà sí mi,
kí o sì fi oore ọ̀fẹ́ kọ́ mi ní òfin rẹ.
30Mo ti yan ọ̀nà òtítọ́,
mo ti fi ọkàn sí òfin rẹ.
31Mo pa òfin rẹ mọ́, OLUWA,
má jẹ́ kí ojú ó tì mí.
32N óo yára láti pa òfin rẹ mọ́,
nígbà tí o bá mú òye mi jinlẹ̀ sí i.
Adura fún Òye
33OLUWA, kọ́ mi ní ìlànà rẹ,
n óo sì pa wọ́n mọ́ dé òpin.
34Là mí lóye, kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́,
kí n sì máa fi tọkàntọkàn pa wọ́n mọ́.
35Tọ́ mi sí ọ̀nà nípa òfin rẹ,
nítorí pé mo láyọ̀ ninu rẹ̀.
36Mú kí ọkàn mi fà sí òfin rẹ,
kí ó má fà sí ọrọ̀ ayé.
37Yí ojú mi kúrò ninu wíwo nǹkan asán,
sọ mí di alààyè ní ọ̀nà rẹ.
38Mú ìlérí rẹ ṣẹ fún iranṣẹ rẹ,
àní, ìlérí tí o ṣe fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ.
39Mú ẹ̀gàn tí ń bà mí lẹ́rù kúrò,
nítorí pé ìlànà rẹ dára.
40Wò ó, ọkàn mi fà sí ati máa tẹ̀lé ìlànà rẹ,
sọ mí di alààyè nítorí òdodo rẹ!
Gbígbẹ́kẹ̀lé ninu Òfin OLUWA
41Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn mí, OLÚWA,
kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
42Nígbà náà ni n óo lè dá àwọn tí ń gàn mí lóhùn,
nítorí mo gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
43Má gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ lẹ́nu mi rárá,
nítorí ìrètí mi ń bẹ ninu ìlànà rẹ.
44N óo máa pa òfin rẹ mọ́ nígbà gbogbo, lae ati laelae.
45N óo máa rìn fàlàlà,
nítorí pé mo tẹ̀lé ìlànà rẹ.
46N óo máa sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba,
ojú kò sì ní tì mí.
47Mo láyọ̀ ninu òfin rẹ,
nítorí tí mo fẹ́ràn rẹ̀.
48Mo bọ̀wọ̀ fún àṣẹ rẹ tí mo fẹ́ràn,
n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ.
Igbẹkẹle ninu Òfin OLUWA
49Ranti ọ̀rọ̀ tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ,
èyí tí ó fún mi ní ìrètí.
50Ohun tí ó ń tù mí ninu ní àkókò ìpọ́njú ni pé:
ìlérí rẹ mú mi wà láàyè.
51Àwọn onigbeeraga ń kẹ́gàn mi gidigidi,
ṣugbọn n ò kọ òfin rẹ sílẹ̀.
52Mo ranti òfin rẹ àtijọ́,
OLUWA, ọkàn mi sì balẹ̀.
53Inú mi á máa ru,
nígbà tí mo bá rí àwọn eniyan burúkú,
tí wọn ń rú òfin rẹ.
54Òfin rẹ ni mò ń fi ń ṣe orin kọ,
lákòókò ìrìn àjò mi láyé.
55Mo ranti orúkọ rẹ lóru;
OLUWA, mo sì pa òfin rẹ mọ́:
56Èyí ni ìṣe mi:
Èmi a máa pa òfin rẹ mọ́.
Ìfọkànsí Òfin OLUWA
57OLUWA, ìwọ nìkan ni mo ní;
mo ṣe ìlérí láti pa òfin rẹ mọ́.
58Tọkàntọkàn ni mò ń wá ojurere rẹ,
ṣe mí lóore gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
59Nígbà tí mo ronú nípa ìṣe mi,
mo yipada sí ìlànà rẹ;
60mo yára, bẹ́ẹ̀ ni n kò lọ́ra láti pa òfin rẹ mọ́.
61Bí okùn àwọn eniyan burúkú tilẹ̀ wé mọ́ mi,
n kò ní gbàgbé òfin rẹ.
62Mo dìde lọ́gànjọ́ láti yìn ọ́,
nítorí ìlànà òdodo rẹ.
63Ọ̀rẹ́ gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ ni mí,
àní, àwọn tí wọn ń pa òfin rẹ mọ́.
64OLUWA, ayé kún fún ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;
kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
Iyebíye ni Òfin OLUWA
65OLUWA, o ti ṣeun fún èmi iranṣẹ rẹ,
gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
66Fún mi ní òye ati ìmọ̀ pípé,
nítorí mo ní igbagbọ ninu àṣẹ rẹ.
67Kí o tó jẹ mí níyà, mo yapa kúrò ninu òfin rẹ;
ṣugbọn nisinsinyii, mò ń mú àṣẹ rẹ ṣẹ.
68OLUWA rere ni ọ́, rere ni o sì ń ṣe;
kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
69Àwọn onigbeeraga ti wé irọ́ mọ́ mi lẹ́sẹ̀,
ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́.
70Ọkàn wọn ti yigbì,#119:70 tabi isébọ́.
ṣugbọn èmi láyọ̀ ninu òfin rẹ.
71Ìpọ́njú tí mo rí ṣe mí ní anfaani,
ó mú kí n kọ́ nípa ìlànà rẹ.
72Òfin rẹ níye lórí fún mi,
ó ju ẹgbẹẹgbẹrun wúrà ati fadaka lọ.
Òdodo ni Òfin OLUWA
73Ìwọ ni o mọ mí, ìwọ ni o dá mi,
fún mi ní òye kí n lè kọ́ òfin rẹ.
74Inú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yóo máa dùn
nígbà tí wọ́n bá rí mi,
nítorí pé mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ.
75OLUWA, mo mọ̀ pé ìdájọ́ rẹ tọ̀nà,
ati pé lórí ẹ̀tọ́ ni o pọ́n mi lójú.
76Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ máa tù mí ninu,
gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí o ṣe fún èmi, iranṣẹ rẹ.
77Ṣàánú mi, kí n lè wà láàyè,
nítorí pé òfin rẹ ni ìdùnnú mi.
78Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn onigbeeraga,
nítorí wọ́n ṣe àrékérekè sí mi láìnídìí;
ní tèmi, n óo máa ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ.
79Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ tọ̀ mí wá,
kí wọ́n lè mọ òfin rẹ.
80Níti pípa òfin rẹ mọ́, jẹ́ kí n pé,
kí ojú má baà tì mí.
Adura Ìdáǹdè
81Mo wá ìgbàlà rẹ títí, àárẹ̀ mú ọkàn mi;
ṣugbọn mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ.
82Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi,
níbi tí mo tí ń retí ìmúṣẹ ìlérí rẹ.
Mo ní, “Nígbà wo ni o óo tù mí ninu?”
83Mo dàbí agbè ọtí tí ó ti di àlòpatì,
sibẹ, n kò gbàgbé ìlànà rẹ.
84Èmi iranṣẹ rẹ yóo ti dúró pẹ́ tó?
Nígbà wo ni ìwọ óo dájọ́ fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi?
85Àwọn onigbeeraga ti gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí,
àní, àwọn tí kì í pa òfin rẹ mọ́.
86Gbogbo òfin rẹ ló dájú;
ràn mí lọ́wọ́, nítorí wọ́n ń fi ìwà èké ṣe inúnibíni mi.
87Wọ́n fẹ́rẹ̀ pa mí run láyé,
ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀.
88Dá ẹ̀mí mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,
kí n lè máa mú gbogbo àṣẹ rẹ ṣẹ.
Igbagbọ ninu Òfin OLUWA
89OLUWA, títí lae ni ọ̀rọ̀ rẹ fìdí múlẹ̀ lọ́run.
90Òtítọ́ rẹ wà láti ìrandíran;
o ti fi ìdí ayé múlẹ̀, ó sì dúró.
91Ohun gbogbo wà gẹ́gẹ́ bí ìlànà rẹ, títí di òní,
nítorí pé iranṣẹ rẹ ni gbogbo wọn.
92Bí kò bá jẹ́ pé òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi,
ǹ bá ti ṣègbé ninu ìpọ́njú.
93Lae, n kò ní gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ,
nítorí pé, nípasẹ̀ wọn ni o fi mú mi wà láyé.
94Ìwọ ni o ni mí, gbà mí;
nítorí pé mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.
95Àwọn eniyan burúkú ba dè mí,
wọ́n fẹ́ pa mí run,
ṣugbọn mò ń ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ.
96Mo ti rí i pé kò sí ohun tí ó lè pé tán,
àfi òfin rẹ nìkan ni kò lópin.
Ìfẹ́ sí Òfin OLUWA
97Mo fẹ́ràn òfin rẹ lọpọlọpọ!
Òun ni mo fi ń ṣe àṣàrò tọ̀sán-tòru.
98Ìlànà rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,
nítorí pé òun ni ó ń darí mi nígbà gbogbo.
99Òye mi ju ti àwọn olùkọ́ mi lọ,
nítorí pé ìlànà rẹ ni mo fi ń ṣe àṣàrò.
100Òye mi ju ti àwọn àgbà lọ,
nítorí pé mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.
101N kò rin ọ̀nà ibi kankan,
kí n lè pa òfin rẹ mọ́.
102N kò yapa kúrò ninu òfin rẹ,
nítorí pé o ti kọ́ mi.
103Ọ̀rọ̀ rẹ dùn mọ́ mi pupọ,
ó dùn ju oyin lọ.
104Nípa ẹ̀kọ́ rẹ ni mo fi ní òye,
nítorí náà mo kórìíra gbogbo ìwà èké.
Ìmọ́lẹ̀ láti Inú Òfin OLUWA
105Ọ̀rọ̀ rẹ ni àtùpà fún ẹsẹ̀ mi,
òun ni ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà mi.
106Mo ti búra, n óo sì mú un ṣẹ,
pé n óo máa pa òfin òdodo rẹ mọ́.
107Ojú ń pọ́n mi lọpọlọpọ,
sọ mí di alààyè, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
108Gba ẹbọ ìyìn àtọkànwá mi, OLUWA,
kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
109Ayé mi wà ninu ewu nígbà gbogbo,
ṣugbọn n kò gbàgbé òfin rẹ.
110Àwọn eniyan burúkú ti dẹ okùn sílẹ̀ dè mí,
ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀.
111Ìlànà rẹ ni ogún mi títí lae,
nítorí pé òun ni ayọ̀ mi.
112Mo ti pinnu láti máa tẹ̀lé ìlànà rẹ nígbà gbogbo,
àní, títí dé òpin.
Ààbò ninu Òfin OLUWA
113Mo kórìíra àwọn oníyèméjì,
ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ.
114Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi ati asà mi,
mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ.
115Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin aṣebi,
kí n lè pa òfin Ọlọrun mi mọ́.
116Gbé mi ró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, kí n lè wà láàyè,
má sì dójú ìrètí mi tì mí.
117Gbé mi ró, kí n lè wà láìléwu,
kí n lè máa ka ìlànà rẹ sí nígbà gbogbo.
118O ti kọ gbogbo àwọn tí ó yapa kúrò ninu ìlànà rẹ sílẹ̀,
nítorí pé asán ni gbogbo ẹ̀tàn wọn.
119O ti pa àwọn eniyan burúkú tì, bí ìdàrọ́ irin,
nítorí náà ni mo ṣe fẹ́ràn ìlànà rẹ.
120Mo wárìrì nítorí pé mo bẹ̀rù rẹ,
mo sì bẹ̀rù ìdájọ́ rẹ.
Pípa Òfin OLUWA mọ́
121Mo ti ṣe ohun tí ó tọ́ tí ó sì yẹ,
má fi mí sílẹ̀ fún àwọn tí wọn ń ni mí lára.
122Ṣe ìlérí ìrànlọ́wọ́ fún ire èmi iranṣẹ rẹ,
má sì jẹ́ kí àwọn onigbeeraga ni mí lára.
123Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi,
níbi tí mo tí ń retí ìgbàlà rẹ,
ati ìmúṣẹ ìlérí òdodo rẹ.
124Ṣe sí èmi iranṣẹ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,
kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
125Iranṣẹ rẹ ni mí,
fún mi lóye, kí n lè mọ ìlànà rẹ.
126OLUWA, ó tó àkókò fún ọ láti ṣe nǹkankan,
nítorí àwọn eniyan ń rú òfin rẹ.
127Nítorí náà ni èmi ṣe fẹ́ràn òfin rẹ
ju wúrà lọ; àní, ju ojúlówó wúrà.
128Nítorí náà, èmi ń tẹ̀lé gbogbo ẹ̀kọ́ rẹ,
mo sì kórìíra gbogbo ọ̀nà èké.
Ìfẹ́ láti Pa Òfin OLUWA Mọ́
129Òfin rẹ dára,
nítorí náà ni mo ṣe ń pa wọ́n mọ́.
130Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ a máa fúnni ní ìmọ́lẹ̀,
a sì máa fi òye fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.
131Mo la ẹnu, mò ń mí hẹlẹ,
nítorí pé mò ń lépa òfin rẹ.
132Kọjú sí mi kí o ṣe mí lóore
bí o ti máa ń ṣe
sí àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ.
133Mú ẹsẹ̀ mi dúró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ,
má sì jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ kankan jọba lórí mi.
134Gbà mí lọ́wọ́ ìnilára àwọn eniyan,
kí n lè máa tẹ̀lé ìlànà rẹ.
135Jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí ara èmi iranṣẹ rẹ;
kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
136Omijé ń dà lójú mi pòròpòrò,
nítorí pé àwọn eniyan kò pa òfin rẹ mọ́.
Títọ́ Òfin OLUWA
137Olódodo ni ọ́, OLUWA,
ìdájọ́ rẹ sì tọ́.
138Òdodo ni o fi pa àṣẹ rẹ,
òtítọ́ patapata ni.
139Mò ń tara gidigidi,
nítorí pé àwọn ọ̀tá mi gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ.
140A ti yẹ ọ̀rọ̀ rẹ wò fínnífínní, ó dúró ṣinṣin,
mo sì fẹ́ràn rẹ̀.
141Bí mo tilẹ̀ kéré, tí ayé sì kẹ́gàn mi,
sibẹ n kò gbàgbé ìlànà rẹ.
142Òdodo rẹ wà títí lae,
òtítọ́ sì ni òfin rẹ.
143Ìyọnu ati ìpayà dé bá mi,
ṣugbọn mo láyọ̀ ninu òfin rẹ.
144Òdodo ni ìlànà rẹ títí lae,
fún mi ní òye kí n lè wà láàyè.
Adura Ìdáǹdè
145Tọkàntọkàn ni mo fi ń ké pè ọ́,
OLUWA, dá mi lóhùn;
n óo sì máa tẹ̀lé ìlànà rẹ.
146Mo ké pè ọ́; gbà mí,
n óo sì máa mú àṣẹ rẹ ṣẹ.
147Mo jí ní òwúrọ̀ kutukutu, mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́;
mò ń retí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ rẹ.
148N kò fi ojú ba oorun ní gbogbo òru,
kí n lè máa ṣe àṣàrò lórí ọ̀rọ̀ rẹ.
149Gbóhùn mi nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,
OLÚWA, dá mi sí nítorí òtítọ́ rẹ.
150Àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi súnmọ́ tòsí;
wọ́n jìnnà sí òfin rẹ.
151Ṣugbọn ìwọ wà nítòsí, OLUWA,
òtítọ́ sì ni gbogbo òfin rẹ.
152Ó pẹ́ tí mo ti kọ́ ninu ìlànà rẹ,
pé o ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí lae.
Ẹ̀bẹ̀ fún Ìrànlọ́wọ́
153Wo ìpọ́njú mi, kí o gbà mí,
nítorí n kò gbàgbé òfin rẹ.
154Gba ẹjọ́ mi rò, kí o sì gbà mí,
sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
155Ìgbàlà jìnnà sí àwọn eniyan burúkú,
nítorí wọn kò wá ìlànà rẹ.
156Àánú rẹ pọ̀, OLUWA,
sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ rẹ.
157Àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi ati àwọn ọ̀tá mi pọ̀,
ṣugbọn n kò yapa kúrò ninu ìlànà rẹ.
158Mò ń wo àwọn ọ̀dàlẹ̀ pẹlu ìríra,
nítorí wọn kì í pa òfin rẹ mọ́.
159Wo bí mo ti fẹ́ ẹ̀kọ́ rẹ tó!
Dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.
160Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ,
gbogbo òfin òdodo rẹ ni yóo máa wà títí lae.
Fífi Ara Ẹni fún Òfin OLUWA
161Àwọn ìjòyè ń ṣe inúnibíni mi láìnídìí,
ṣugbọn mo bẹ̀rù ọ̀rọ̀ rẹ tọkàntọkàn.
162Mo láyọ̀ ninu ọ̀rọ̀ rẹ,
bí ẹni pé mo ní ọpọlọpọ ìkógun.
163Mo kórìíra èké ṣíṣe, ara mi kọ̀ ọ́,
ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ.
164Nígbà meje lojoojumọ ni mò ń yìn ọ́
nítorí òfin òdodo rẹ.
165Alaafia ńláńlá ń bẹ fún àwọn tí ó fẹ́ràn òfin rẹ,
kò sí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.
166Mò ń retí ìgbàlà rẹ, OLUWA,
mo sì ń pa àwọn òfin rẹ mọ́.
167Mò ń pa àṣẹ rẹ mọ́,
mo fẹ́ràn wọn gidigidi.
168Mo gba ẹ̀kọ́ rẹ, mo sì ń tẹ̀lé ìlànà rẹ;
gbogbo ìṣe mi ni ò ń rí.
Adura Ìrànlọ́wọ́
169Jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ, OLUWA,
fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
170Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi dé iwájú rẹ,
kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
171Ẹnu mi yóo kún fún ìyìn rẹ,
pé o ti kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
172N óo máa fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe orin kọ,
nítorí pé gbogbo òfin rẹ ni ó tọ̀nà.
173Múra láti ràn mí lọ́wọ́,
nítorí pé mo ti gba ẹ̀kọ́ rẹ.
174Ọkàn mi ń fà sí ìgbàlà rẹ, OLUWA;
òfin rẹ sì ni inú dídùn mi.
175Dá mi sí kí n lè máa yìn ọ́,
sì jẹ́ kí òfin rẹ ràn mí lọ́wọ́.
176Mo ti ṣìnà bí aguntan tó sọnù;
wá èmi, iranṣẹ rẹ, rí,
nítorí pé n kò gbàgbé òfin rẹ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 119: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
ORIN DAFIDI 119
119
Òfin OLUWA
1Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ìgbé ayé wọn kò lábàwọ́n,
àní àwọn tí ń rìn gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA.
2Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́,
tí wọn ń fi tọkàntọkàn ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
3Àwọn tí wọn kò dẹ́ṣẹ̀,
ṣugbọn tí wọn ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
4O ti pàṣẹ pé kí á fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́,
5Ìbá ti dára tó
tí mo bá lè dúró ṣinṣin ninu ìlànà rẹ!
6Òun ni ojú kò fi ní tì mí,
nítorí pé òfin rẹ ni mò ń tẹ̀lé.
7N óo yìn ọ́ pẹlu inú mímọ́,
bí mo ṣe ń kọ́ ìlànà òdodo rẹ.
8N óo máa pa òfin rẹ mọ́,
má kọ̀ mí sílẹ̀ patapata.
Pípa Òfin OLUWA mọ́
9Báwo ni ọdọmọkunrin ṣe lè mú kí ọ̀nà rẹ̀ mọ́?
Nípa títẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ ni.
10Tọkàntọkàn ni mo fi ń ṣe ìfẹ́ rẹ,
má jẹ́ kí n ṣìnà kúrò ninu òfin rẹ.
11Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ sọ́kàn,
kí n má baà ṣẹ̀ ọ́.
12Ìyìn ni fún ọ, OLUWA,
kọ́ mi ní ìlànà rẹ!
13Mo fi ẹnu mi kéde gbogbo àṣẹ tí o pa.
14Mo láyọ̀ ninu pípa òfin rẹ mọ́,
bí ẹni tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀.
15N óo máa ṣe àṣàrò ninu òfin rẹ,
n óo sì kọjú sí ọ̀nà rẹ.
16N óo láyọ̀ ninu àwọn ìlànà rẹ,
n kò ní gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ.
Ayọ̀ ninu Òfin OLUWA
17Ṣe ọpọlọpọ oore fún èmi iranṣẹ rẹ,
kí n lè wà láàyè,
kí n sì máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
18Là mí lójú, kí n lè rí àwọn nǹkan ìyanu
tí ó wà ninu òfin rẹ.
19Àlejò ni mí láyé,
má fi òfin rẹ pamọ́ fún mi.
20Òùngbẹ títẹ̀lé òfin rẹ ń gbẹ ọkàn mi, nígbà gbogbo.
21O bá àwọn onigbeeraga wí, àwọn ẹni ègún,
tí wọn kò pa òfin rẹ mọ́.
22Mú ẹ̀gàn ati àbùkù wọn kúrò lára mi,
nítorí pé mo ti pa òfin rẹ mọ́.
23Bí àwọn ìjòyè tilẹ̀ gbìmọ̀ràn ọ̀tẹ̀ nítorí mi,
sibẹ, èmi iranṣẹ rẹ yóo ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ.
24Àwọn òfin rẹ ni dídùn inú mi,
àwọn ni olùdámọ̀ràn mi.
Ìpinnu láti Pa Òfin OLUWA mọ́
25Mo di ẹni ilẹ̀,
sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
26Nígbà tí mo jẹ́wọ́ gbogbo ìṣe mi, o dá mi lóhùn;
kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
27La òfin rẹ yé mi,
n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí iṣẹ́ ìyanu rẹ.
28Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi nítorí ìbànújẹ́,
mú mi lọ́kàn le gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
29Mú ìwà èké jìnnà sí mi,
kí o sì fi oore ọ̀fẹ́ kọ́ mi ní òfin rẹ.
30Mo ti yan ọ̀nà òtítọ́,
mo ti fi ọkàn sí òfin rẹ.
31Mo pa òfin rẹ mọ́, OLUWA,
má jẹ́ kí ojú ó tì mí.
32N óo yára láti pa òfin rẹ mọ́,
nígbà tí o bá mú òye mi jinlẹ̀ sí i.
Adura fún Òye
33OLUWA, kọ́ mi ní ìlànà rẹ,
n óo sì pa wọ́n mọ́ dé òpin.
34Là mí lóye, kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́,
kí n sì máa fi tọkàntọkàn pa wọ́n mọ́.
35Tọ́ mi sí ọ̀nà nípa òfin rẹ,
nítorí pé mo láyọ̀ ninu rẹ̀.
36Mú kí ọkàn mi fà sí òfin rẹ,
kí ó má fà sí ọrọ̀ ayé.
37Yí ojú mi kúrò ninu wíwo nǹkan asán,
sọ mí di alààyè ní ọ̀nà rẹ.
38Mú ìlérí rẹ ṣẹ fún iranṣẹ rẹ,
àní, ìlérí tí o ṣe fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ.
39Mú ẹ̀gàn tí ń bà mí lẹ́rù kúrò,
nítorí pé ìlànà rẹ dára.
40Wò ó, ọkàn mi fà sí ati máa tẹ̀lé ìlànà rẹ,
sọ mí di alààyè nítorí òdodo rẹ!
Gbígbẹ́kẹ̀lé ninu Òfin OLUWA
41Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn mí, OLÚWA,
kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
42Nígbà náà ni n óo lè dá àwọn tí ń gàn mí lóhùn,
nítorí mo gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
43Má gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ lẹ́nu mi rárá,
nítorí ìrètí mi ń bẹ ninu ìlànà rẹ.
44N óo máa pa òfin rẹ mọ́ nígbà gbogbo, lae ati laelae.
45N óo máa rìn fàlàlà,
nítorí pé mo tẹ̀lé ìlànà rẹ.
46N óo máa sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba,
ojú kò sì ní tì mí.
47Mo láyọ̀ ninu òfin rẹ,
nítorí tí mo fẹ́ràn rẹ̀.
48Mo bọ̀wọ̀ fún àṣẹ rẹ tí mo fẹ́ràn,
n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ.
Igbẹkẹle ninu Òfin OLUWA
49Ranti ọ̀rọ̀ tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ,
èyí tí ó fún mi ní ìrètí.
50Ohun tí ó ń tù mí ninu ní àkókò ìpọ́njú ni pé:
ìlérí rẹ mú mi wà láàyè.
51Àwọn onigbeeraga ń kẹ́gàn mi gidigidi,
ṣugbọn n ò kọ òfin rẹ sílẹ̀.
52Mo ranti òfin rẹ àtijọ́,
OLUWA, ọkàn mi sì balẹ̀.
53Inú mi á máa ru,
nígbà tí mo bá rí àwọn eniyan burúkú,
tí wọn ń rú òfin rẹ.
54Òfin rẹ ni mò ń fi ń ṣe orin kọ,
lákòókò ìrìn àjò mi láyé.
55Mo ranti orúkọ rẹ lóru;
OLUWA, mo sì pa òfin rẹ mọ́:
56Èyí ni ìṣe mi:
Èmi a máa pa òfin rẹ mọ́.
Ìfọkànsí Òfin OLUWA
57OLUWA, ìwọ nìkan ni mo ní;
mo ṣe ìlérí láti pa òfin rẹ mọ́.
58Tọkàntọkàn ni mò ń wá ojurere rẹ,
ṣe mí lóore gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
59Nígbà tí mo ronú nípa ìṣe mi,
mo yipada sí ìlànà rẹ;
60mo yára, bẹ́ẹ̀ ni n kò lọ́ra láti pa òfin rẹ mọ́.
61Bí okùn àwọn eniyan burúkú tilẹ̀ wé mọ́ mi,
n kò ní gbàgbé òfin rẹ.
62Mo dìde lọ́gànjọ́ láti yìn ọ́,
nítorí ìlànà òdodo rẹ.
63Ọ̀rẹ́ gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ ni mí,
àní, àwọn tí wọn ń pa òfin rẹ mọ́.
64OLUWA, ayé kún fún ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;
kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
Iyebíye ni Òfin OLUWA
65OLUWA, o ti ṣeun fún èmi iranṣẹ rẹ,
gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
66Fún mi ní òye ati ìmọ̀ pípé,
nítorí mo ní igbagbọ ninu àṣẹ rẹ.
67Kí o tó jẹ mí níyà, mo yapa kúrò ninu òfin rẹ;
ṣugbọn nisinsinyii, mò ń mú àṣẹ rẹ ṣẹ.
68OLUWA rere ni ọ́, rere ni o sì ń ṣe;
kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
69Àwọn onigbeeraga ti wé irọ́ mọ́ mi lẹ́sẹ̀,
ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́.
70Ọkàn wọn ti yigbì,#119:70 tabi isébọ́.
ṣugbọn èmi láyọ̀ ninu òfin rẹ.
71Ìpọ́njú tí mo rí ṣe mí ní anfaani,
ó mú kí n kọ́ nípa ìlànà rẹ.
72Òfin rẹ níye lórí fún mi,
ó ju ẹgbẹẹgbẹrun wúrà ati fadaka lọ.
Òdodo ni Òfin OLUWA
73Ìwọ ni o mọ mí, ìwọ ni o dá mi,
fún mi ní òye kí n lè kọ́ òfin rẹ.
74Inú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yóo máa dùn
nígbà tí wọ́n bá rí mi,
nítorí pé mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ.
75OLUWA, mo mọ̀ pé ìdájọ́ rẹ tọ̀nà,
ati pé lórí ẹ̀tọ́ ni o pọ́n mi lójú.
76Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ máa tù mí ninu,
gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí o ṣe fún èmi, iranṣẹ rẹ.
77Ṣàánú mi, kí n lè wà láàyè,
nítorí pé òfin rẹ ni ìdùnnú mi.
78Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn onigbeeraga,
nítorí wọ́n ṣe àrékérekè sí mi láìnídìí;
ní tèmi, n óo máa ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ.
79Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ tọ̀ mí wá,
kí wọ́n lè mọ òfin rẹ.
80Níti pípa òfin rẹ mọ́, jẹ́ kí n pé,
kí ojú má baà tì mí.
Adura Ìdáǹdè
81Mo wá ìgbàlà rẹ títí, àárẹ̀ mú ọkàn mi;
ṣugbọn mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ.
82Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi,
níbi tí mo tí ń retí ìmúṣẹ ìlérí rẹ.
Mo ní, “Nígbà wo ni o óo tù mí ninu?”
83Mo dàbí agbè ọtí tí ó ti di àlòpatì,
sibẹ, n kò gbàgbé ìlànà rẹ.
84Èmi iranṣẹ rẹ yóo ti dúró pẹ́ tó?
Nígbà wo ni ìwọ óo dájọ́ fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi?
85Àwọn onigbeeraga ti gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí,
àní, àwọn tí kì í pa òfin rẹ mọ́.
86Gbogbo òfin rẹ ló dájú;
ràn mí lọ́wọ́, nítorí wọ́n ń fi ìwà èké ṣe inúnibíni mi.
87Wọ́n fẹ́rẹ̀ pa mí run láyé,
ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀.
88Dá ẹ̀mí mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,
kí n lè máa mú gbogbo àṣẹ rẹ ṣẹ.
Igbagbọ ninu Òfin OLUWA
89OLUWA, títí lae ni ọ̀rọ̀ rẹ fìdí múlẹ̀ lọ́run.
90Òtítọ́ rẹ wà láti ìrandíran;
o ti fi ìdí ayé múlẹ̀, ó sì dúró.
91Ohun gbogbo wà gẹ́gẹ́ bí ìlànà rẹ, títí di òní,
nítorí pé iranṣẹ rẹ ni gbogbo wọn.
92Bí kò bá jẹ́ pé òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi,
ǹ bá ti ṣègbé ninu ìpọ́njú.
93Lae, n kò ní gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ,
nítorí pé, nípasẹ̀ wọn ni o fi mú mi wà láyé.
94Ìwọ ni o ni mí, gbà mí;
nítorí pé mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.
95Àwọn eniyan burúkú ba dè mí,
wọ́n fẹ́ pa mí run,
ṣugbọn mò ń ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ.
96Mo ti rí i pé kò sí ohun tí ó lè pé tán,
àfi òfin rẹ nìkan ni kò lópin.
Ìfẹ́ sí Òfin OLUWA
97Mo fẹ́ràn òfin rẹ lọpọlọpọ!
Òun ni mo fi ń ṣe àṣàrò tọ̀sán-tòru.
98Ìlànà rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,
nítorí pé òun ni ó ń darí mi nígbà gbogbo.
99Òye mi ju ti àwọn olùkọ́ mi lọ,
nítorí pé ìlànà rẹ ni mo fi ń ṣe àṣàrò.
100Òye mi ju ti àwọn àgbà lọ,
nítorí pé mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.
101N kò rin ọ̀nà ibi kankan,
kí n lè pa òfin rẹ mọ́.
102N kò yapa kúrò ninu òfin rẹ,
nítorí pé o ti kọ́ mi.
103Ọ̀rọ̀ rẹ dùn mọ́ mi pupọ,
ó dùn ju oyin lọ.
104Nípa ẹ̀kọ́ rẹ ni mo fi ní òye,
nítorí náà mo kórìíra gbogbo ìwà èké.
Ìmọ́lẹ̀ láti Inú Òfin OLUWA
105Ọ̀rọ̀ rẹ ni àtùpà fún ẹsẹ̀ mi,
òun ni ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà mi.
106Mo ti búra, n óo sì mú un ṣẹ,
pé n óo máa pa òfin òdodo rẹ mọ́.
107Ojú ń pọ́n mi lọpọlọpọ,
sọ mí di alààyè, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
108Gba ẹbọ ìyìn àtọkànwá mi, OLUWA,
kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
109Ayé mi wà ninu ewu nígbà gbogbo,
ṣugbọn n kò gbàgbé òfin rẹ.
110Àwọn eniyan burúkú ti dẹ okùn sílẹ̀ dè mí,
ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀.
111Ìlànà rẹ ni ogún mi títí lae,
nítorí pé òun ni ayọ̀ mi.
112Mo ti pinnu láti máa tẹ̀lé ìlànà rẹ nígbà gbogbo,
àní, títí dé òpin.
Ààbò ninu Òfin OLUWA
113Mo kórìíra àwọn oníyèméjì,
ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ.
114Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi ati asà mi,
mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ.
115Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin aṣebi,
kí n lè pa òfin Ọlọrun mi mọ́.
116Gbé mi ró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, kí n lè wà láàyè,
má sì dójú ìrètí mi tì mí.
117Gbé mi ró, kí n lè wà láìléwu,
kí n lè máa ka ìlànà rẹ sí nígbà gbogbo.
118O ti kọ gbogbo àwọn tí ó yapa kúrò ninu ìlànà rẹ sílẹ̀,
nítorí pé asán ni gbogbo ẹ̀tàn wọn.
119O ti pa àwọn eniyan burúkú tì, bí ìdàrọ́ irin,
nítorí náà ni mo ṣe fẹ́ràn ìlànà rẹ.
120Mo wárìrì nítorí pé mo bẹ̀rù rẹ,
mo sì bẹ̀rù ìdájọ́ rẹ.
Pípa Òfin OLUWA mọ́
121Mo ti ṣe ohun tí ó tọ́ tí ó sì yẹ,
má fi mí sílẹ̀ fún àwọn tí wọn ń ni mí lára.
122Ṣe ìlérí ìrànlọ́wọ́ fún ire èmi iranṣẹ rẹ,
má sì jẹ́ kí àwọn onigbeeraga ni mí lára.
123Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi,
níbi tí mo tí ń retí ìgbàlà rẹ,
ati ìmúṣẹ ìlérí òdodo rẹ.
124Ṣe sí èmi iranṣẹ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,
kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
125Iranṣẹ rẹ ni mí,
fún mi lóye, kí n lè mọ ìlànà rẹ.
126OLUWA, ó tó àkókò fún ọ láti ṣe nǹkankan,
nítorí àwọn eniyan ń rú òfin rẹ.
127Nítorí náà ni èmi ṣe fẹ́ràn òfin rẹ
ju wúrà lọ; àní, ju ojúlówó wúrà.
128Nítorí náà, èmi ń tẹ̀lé gbogbo ẹ̀kọ́ rẹ,
mo sì kórìíra gbogbo ọ̀nà èké.
Ìfẹ́ láti Pa Òfin OLUWA Mọ́
129Òfin rẹ dára,
nítorí náà ni mo ṣe ń pa wọ́n mọ́.
130Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ a máa fúnni ní ìmọ́lẹ̀,
a sì máa fi òye fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.
131Mo la ẹnu, mò ń mí hẹlẹ,
nítorí pé mò ń lépa òfin rẹ.
132Kọjú sí mi kí o ṣe mí lóore
bí o ti máa ń ṣe
sí àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ.
133Mú ẹsẹ̀ mi dúró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ,
má sì jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ kankan jọba lórí mi.
134Gbà mí lọ́wọ́ ìnilára àwọn eniyan,
kí n lè máa tẹ̀lé ìlànà rẹ.
135Jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí ara èmi iranṣẹ rẹ;
kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
136Omijé ń dà lójú mi pòròpòrò,
nítorí pé àwọn eniyan kò pa òfin rẹ mọ́.
Títọ́ Òfin OLUWA
137Olódodo ni ọ́, OLUWA,
ìdájọ́ rẹ sì tọ́.
138Òdodo ni o fi pa àṣẹ rẹ,
òtítọ́ patapata ni.
139Mò ń tara gidigidi,
nítorí pé àwọn ọ̀tá mi gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ.
140A ti yẹ ọ̀rọ̀ rẹ wò fínnífínní, ó dúró ṣinṣin,
mo sì fẹ́ràn rẹ̀.
141Bí mo tilẹ̀ kéré, tí ayé sì kẹ́gàn mi,
sibẹ n kò gbàgbé ìlànà rẹ.
142Òdodo rẹ wà títí lae,
òtítọ́ sì ni òfin rẹ.
143Ìyọnu ati ìpayà dé bá mi,
ṣugbọn mo láyọ̀ ninu òfin rẹ.
144Òdodo ni ìlànà rẹ títí lae,
fún mi ní òye kí n lè wà láàyè.
Adura Ìdáǹdè
145Tọkàntọkàn ni mo fi ń ké pè ọ́,
OLUWA, dá mi lóhùn;
n óo sì máa tẹ̀lé ìlànà rẹ.
146Mo ké pè ọ́; gbà mí,
n óo sì máa mú àṣẹ rẹ ṣẹ.
147Mo jí ní òwúrọ̀ kutukutu, mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́;
mò ń retí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ rẹ.
148N kò fi ojú ba oorun ní gbogbo òru,
kí n lè máa ṣe àṣàrò lórí ọ̀rọ̀ rẹ.
149Gbóhùn mi nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,
OLÚWA, dá mi sí nítorí òtítọ́ rẹ.
150Àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi súnmọ́ tòsí;
wọ́n jìnnà sí òfin rẹ.
151Ṣugbọn ìwọ wà nítòsí, OLUWA,
òtítọ́ sì ni gbogbo òfin rẹ.
152Ó pẹ́ tí mo ti kọ́ ninu ìlànà rẹ,
pé o ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí lae.
Ẹ̀bẹ̀ fún Ìrànlọ́wọ́
153Wo ìpọ́njú mi, kí o gbà mí,
nítorí n kò gbàgbé òfin rẹ.
154Gba ẹjọ́ mi rò, kí o sì gbà mí,
sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
155Ìgbàlà jìnnà sí àwọn eniyan burúkú,
nítorí wọn kò wá ìlànà rẹ.
156Àánú rẹ pọ̀, OLUWA,
sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ rẹ.
157Àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi ati àwọn ọ̀tá mi pọ̀,
ṣugbọn n kò yapa kúrò ninu ìlànà rẹ.
158Mò ń wo àwọn ọ̀dàlẹ̀ pẹlu ìríra,
nítorí wọn kì í pa òfin rẹ mọ́.
159Wo bí mo ti fẹ́ ẹ̀kọ́ rẹ tó!
Dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.
160Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ,
gbogbo òfin òdodo rẹ ni yóo máa wà títí lae.
Fífi Ara Ẹni fún Òfin OLUWA
161Àwọn ìjòyè ń ṣe inúnibíni mi láìnídìí,
ṣugbọn mo bẹ̀rù ọ̀rọ̀ rẹ tọkàntọkàn.
162Mo láyọ̀ ninu ọ̀rọ̀ rẹ,
bí ẹni pé mo ní ọpọlọpọ ìkógun.
163Mo kórìíra èké ṣíṣe, ara mi kọ̀ ọ́,
ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ.
164Nígbà meje lojoojumọ ni mò ń yìn ọ́
nítorí òfin òdodo rẹ.
165Alaafia ńláńlá ń bẹ fún àwọn tí ó fẹ́ràn òfin rẹ,
kò sí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.
166Mò ń retí ìgbàlà rẹ, OLUWA,
mo sì ń pa àwọn òfin rẹ mọ́.
167Mò ń pa àṣẹ rẹ mọ́,
mo fẹ́ràn wọn gidigidi.
168Mo gba ẹ̀kọ́ rẹ, mo sì ń tẹ̀lé ìlànà rẹ;
gbogbo ìṣe mi ni ò ń rí.
Adura Ìrànlọ́wọ́
169Jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ, OLUWA,
fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
170Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi dé iwájú rẹ,
kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
171Ẹnu mi yóo kún fún ìyìn rẹ,
pé o ti kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
172N óo máa fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe orin kọ,
nítorí pé gbogbo òfin rẹ ni ó tọ̀nà.
173Múra láti ràn mí lọ́wọ́,
nítorí pé mo ti gba ẹ̀kọ́ rẹ.
174Ọkàn mi ń fà sí ìgbàlà rẹ, OLUWA;
òfin rẹ sì ni inú dídùn mi.
175Dá mi sí kí n lè máa yìn ọ́,
sì jẹ́ kí òfin rẹ ràn mí lọ́wọ́.
176Mo ti ṣìnà bí aguntan tó sọnù;
wá èmi, iranṣẹ rẹ, rí,
nítorí pé n kò gbàgbé òfin rẹ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010