ORIN DAFIDI 135
135
Orin Ìyìn
1Ẹ yin OLUWA.
Ẹ yin orúkọ OLUWA;
ẹ yìn ín, ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀,
2ẹ̀yin tí ẹ̀ ń jọ́sìn ninu ilé OLUWA,
tí ẹ wà ní àgbàlá ilé Ọlọrun wa.
3Ẹ yin OLUWA, nítorí pé ó ṣeun;
ẹ kọrin ìyìn sí i,
nítorí pé olóore ọ̀fẹ́ ni.
4Nítorí pé OLUWA ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀,
ó ti yan Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀.
5Èmi mọ̀ pé OLUWA tóbi,
ati pé ó ju gbogbo oriṣa lọ.
6Bí ó ti wu OLUWA ni ó ń ṣe
lọ́run ati láyé,
ninu òkun ati ninu ibú.
7Òun ló gbá ìkùukùu jọ láti òpin ilẹ̀ ayé,
ó fi mànàmáná fún òjò,
ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti inú ilé ìṣúra rẹ̀.
8Òun ló pa àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti,
ati teniyan ati tẹran ọ̀sìn.
9Ẹni tí ó rán iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu sí ilẹ̀ Ijipti,
ó rán sí Farao ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀.
10Ẹni tí ó pa orílẹ̀-èdè pupọ run;
ó pa àwọn ọba alágbára:
11Sihoni ọba àwọn Amori,
Ogu ọba Baṣani,
ati gbogbo ọba ilẹ̀ Kenaani.
12Ó pín ilẹ̀ wọn fún àwọn eniyan rẹ̀;
ó pín in fún Israẹli bí ohun ìní wọn.
13OLUWA, orúkọ rẹ yóo wà títí lae,
òkìkí rẹ óo sì máa kàn títí ayé.
14OLUWA yóo dá àwọn eniyan rẹ̀ láre,
yóo sì ṣàánú àwọn iranṣẹ rẹ̀.
15Wúrà ati fadaka ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù fi ṣe oriṣa wọn,
iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n.
16Wọ́n lẹ́nu, ṣugbọn wọn kò lè sọ̀rọ̀,
wọ́n lójú, ṣugbọn wọn kò lè ríran.
17Wọ́n létí, ṣugbọn wọn kò lè gbọ́ràn,
bẹ́ẹ̀ ni kò sí èémí kan ní ẹnu wọn.
18Àwọn tí ń ṣe wọ́n yóo dàbí wọn,
ati gbogbo àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé wọn.#O. Daf 115:4-8; Ifi 9:20
19Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ yin OLUWA,
ẹ̀yin ará ilé Aaroni, ẹ yin OLUWA!
20Ẹ̀yin ará ilé Lefi, ẹ yin OLUWA,
ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ yìn ín!
21Ẹ yin OLUWA ní Sioni,
ẹni tí ń gbé Jerusalẹmu!
Ẹ yin OLUWA!
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 135: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
ORIN DAFIDI 135
135
Orin Ìyìn
1Ẹ yin OLUWA.
Ẹ yin orúkọ OLUWA;
ẹ yìn ín, ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀,
2ẹ̀yin tí ẹ̀ ń jọ́sìn ninu ilé OLUWA,
tí ẹ wà ní àgbàlá ilé Ọlọrun wa.
3Ẹ yin OLUWA, nítorí pé ó ṣeun;
ẹ kọrin ìyìn sí i,
nítorí pé olóore ọ̀fẹ́ ni.
4Nítorí pé OLUWA ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀,
ó ti yan Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀.
5Èmi mọ̀ pé OLUWA tóbi,
ati pé ó ju gbogbo oriṣa lọ.
6Bí ó ti wu OLUWA ni ó ń ṣe
lọ́run ati láyé,
ninu òkun ati ninu ibú.
7Òun ló gbá ìkùukùu jọ láti òpin ilẹ̀ ayé,
ó fi mànàmáná fún òjò,
ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti inú ilé ìṣúra rẹ̀.
8Òun ló pa àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti,
ati teniyan ati tẹran ọ̀sìn.
9Ẹni tí ó rán iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu sí ilẹ̀ Ijipti,
ó rán sí Farao ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀.
10Ẹni tí ó pa orílẹ̀-èdè pupọ run;
ó pa àwọn ọba alágbára:
11Sihoni ọba àwọn Amori,
Ogu ọba Baṣani,
ati gbogbo ọba ilẹ̀ Kenaani.
12Ó pín ilẹ̀ wọn fún àwọn eniyan rẹ̀;
ó pín in fún Israẹli bí ohun ìní wọn.
13OLUWA, orúkọ rẹ yóo wà títí lae,
òkìkí rẹ óo sì máa kàn títí ayé.
14OLUWA yóo dá àwọn eniyan rẹ̀ láre,
yóo sì ṣàánú àwọn iranṣẹ rẹ̀.
15Wúrà ati fadaka ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù fi ṣe oriṣa wọn,
iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n.
16Wọ́n lẹ́nu, ṣugbọn wọn kò lè sọ̀rọ̀,
wọ́n lójú, ṣugbọn wọn kò lè ríran.
17Wọ́n létí, ṣugbọn wọn kò lè gbọ́ràn,
bẹ́ẹ̀ ni kò sí èémí kan ní ẹnu wọn.
18Àwọn tí ń ṣe wọ́n yóo dàbí wọn,
ati gbogbo àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé wọn.#O. Daf 115:4-8; Ifi 9:20
19Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ yin OLUWA,
ẹ̀yin ará ilé Aaroni, ẹ yin OLUWA!
20Ẹ̀yin ará ilé Lefi, ẹ yin OLUWA,
ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ yìn ín!
21Ẹ yin OLUWA ní Sioni,
ẹni tí ń gbé Jerusalẹmu!
Ẹ yin OLUWA!
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010