ORIN DAFIDI 147

147
Ọlọrun Alágbára
1Ẹ yin OLUWA!
Nítorí tí ó dára láti máa kọ orin ìyìn sí Ọlọrun wa;
nítorí olóore ni, orin ìyìn sì yẹ ẹ́.
2OLUWA ní ń kọ́ ìlú Jerusalẹmu;
òun ni yóo kó àwọn ọmọ Israẹli tí a fọ́n ká jọ.
3Ó ń tu àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́ ninu,
ó sì ń dí ọgbẹ́ wọn.
4Òun ló mọ iye àwọn ìràwọ̀,
òun ló sì fún gbogbo wọn lórúkọ.
5OLUWA wa tóbi, ó sì lágbára pupọ
òye rẹ̀ kò ní ìwọ̀n.
6OLUWA ní ń gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ró,
òun ni ó sì ń sọ àwọn eniyan burúkú di ilẹ̀ẹ́lẹ̀.
7Ẹ kọ orin ọpẹ́ sí OLUWA,
ẹ fi hapu kọ orin dídùn sí Ọlọrun wa.
8Ẹni tí ó fi ìkùukùu bo ojú ọ̀run,
ó pèsè òjò fún ilẹ̀,
ó mú koríko hù lórí òkè.
9Òun ni ó ń fún àwọn ẹranko ní oúnjẹ,
tí ó sì ń bọ́ ọmọ ẹyẹ ìwò, tí ó ń ké.
10Kì í ṣe agbára ẹṣin ni inú rẹ̀ dùn sí,
kì í sì í ṣe inú agbára eniyan ni ayọ̀ rẹ̀ wà.
11Ṣugbọn inú OLUWA dùn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
àwọn tí ó ní ìrètí ninu ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.
12Gbé OLUWA ga, ìwọ Jerusalẹmu!
Yin Ọlọrun rẹ, ìwọ Sioni!
13Ó fún ẹnubodè rẹ ní agbára,
ó sì bukun àwọn tí ń gbé inú rẹ.
14Ó jẹ́ kí alaafia wà ní ààlà ilẹ̀ rẹ,
ó sì fi oúnjẹ tí ó dára bọ́ ọ lábọ̀ọ́yó.
15Ó pàṣẹ lórí ilẹ̀ ayé,
àṣẹ rẹ̀ sì múlẹ̀ kíá.
16Ó da òjò dídì bo ilẹ̀ bí ẹ̀gbọ̀n òwú,
ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú.
17Ó sọ yìnyín sílẹ̀ bí òkò,
ta ni ó lè fara da òtútù rẹ̀?
18Ó sọ̀rọ̀, wọ́n yọ́,
ó fẹ́ afẹ́fẹ́, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn.
19Ó ṣí ọ̀rọ̀ rẹ̀ payá fún Jakọbu,
ó sì fi òfin ati ìlànà rẹ̀ han Israẹli.
20Kò ṣe bẹ́ẹ̀ fún orílẹ̀-èdè kankan rí,
wọn kò sì mọ ìlànà rẹ̀.
Ẹ yin OLUWA!

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 147: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀