ORIN DAFIDI 18:1-24

ORIN DAFIDI 18:1-24 YCE

Mo fẹ́ràn rẹ, OLUWA, agbára mi. OLUWA ni àpáta mi, ibi ààbò mi, ati olùgbàlà mi; Ọlọrun mi, àpáta mi, ninu ẹni tí ààbò mi wà. Òun ni asà mi, ìwo ìgbàlà mi ati ibi ìsásí mi. Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ, ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. Ikú wé mọ́ mi bí okùn, ìparun sì bò mí mọ́lẹ̀ bíi rírú omi. Isà òkú yí mi ká, tàkúté ikú sì dojú kọ mí. Ninu ìpọ́njú mi mo ké pe OLUWA, Ọlọrun mi ni mo ké pè. Ó gbọ́ ohùn mi láti inú ilé mímọ́ rẹ̀, ó sì tẹ́tí sí igbe mi. Ilẹ̀ ayé wárìrì, ó sì mì tìtì, ìpìlẹ̀ àwọn òkè mì jìgìjìgì; wọ́n wárìrì nítorí tí ó bínú. Èéfín ṣẹ́ jáde láti ihò imú rẹ̀, iná ajónirun yọ jáde láti ẹnu rẹ̀; ẹ̀yinná sì ń jò bùlà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá. Ó dẹ ojú ọ̀run sílẹ̀, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá, ìkùukùu tó ṣókùnkùn biribiri sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó gun orí Kerubu, ó sì fò, ó fò lọ sókè lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́. Ó fi òkùnkùn bora bí aṣọ, ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn, tí ó sì kún fún omi ni ó fi ṣe ìbòrí. Ninu ìmọ́lẹ̀ níwájú rẹ, ẹ̀yinná ati yìnyín ń fọ́n jáde, láti inú ìkùukùu. OLUWA sán ààrá láti ọ̀run, Ọ̀gá Ògo fọhùn, òjò dídì ati ẹ̀yinná sì fọ́n jáde. Ó ta ọfà rẹ̀ jáde, ó sì fọ́n wọn ká, ó jẹ́ kí mànàmáná kọ, ó sì tú wọn ká. Nígbà náà ni ìsàlẹ̀ òkun hàn ketekete, ìpìlẹ̀ ayé sì fojú hàn gbangba nítorí ìbáwí rẹ, OLUWA, ati nítorí agbára èémí ihò imú rẹ. Ó nawọ́ láti òkè wá, ó sì dì mí mú, ó fà mí jáde láti inú ibú omi. Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi tí ó lágbára, ati lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi; nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ. Wọ́n gbógun tì mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi, ṣugbọn OLUWA ni aláfẹ̀yìntì mi. Ó mú mi jáde wá síbi tí ó láàyè, ó yọ mí jáde nítorí tí inú rẹ̀ dùn sí mi. OLUWA ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ ni ó ṣe pín mi lérè. Nítorí tí mo ti pa ọ̀nà OLUWA mọ́, n kò ṣe ibi nípa yíyà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi. Nítorí pé gbogbo òfin rẹ̀ ni mo tẹ̀lé, n kò sì yà kúrò ninu ìlànà rẹ̀. Mo wà ní àìlẹ́bi níwájú rẹ̀, mo sì ti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà ni OLUWA ṣe san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; ati gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ lójú rẹ̀.