ORIN DAFIDI 23

23
OLUWA ni Olùṣọ́ Mi
1OLUWA ni Olùṣọ́-aguntan mi,
n kò ní ṣe àìní ohunkohun.
2Ó mú mi dùbúlẹ̀ ninu pápá koríko tútù,
ó mú mi lọ sí ibi tí omi ti dákẹ́ rọ́rọ́;
3ó sọ agbára mi dọ̀tun.
Ó tọ́ mi sí ọ̀nà òdodo
nítorí orúkọ rẹ̀.
4Àní, bí mo tilẹ̀ ń rìn ninu òkùnkùn létí bèbè ikú,#23:4 tabi “bí mo tilẹ̀ ń rìn létí bèbè ikú.”
n kò ní bẹ̀rù ibi kankan;
nítorí tí o wà pẹlu mi;
ọ̀gọ rẹ ati ọ̀pá rẹ ń fi mí lọ́kàn balẹ̀.#Ifi 7:17
5O gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú mi,
níṣojú àwọn ọ̀tá mi;
o da òróró sí mi lórí;
o sì bu ife mi kún ní àkúnwọ́sílẹ̀.
6Dájúdájú, ire ati àánú yóo máa tẹ̀lé mi kiri,
ní gbogbo ọjọ́ ayé mi;
èmi óo sì máa gbé inú ilé OLUWA laelae.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 23: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀