ORIN DAFIDI 26

26
Adura Ẹni Rere
1Dá mi láre, OLUWA,
nítorí ninu ìwà pípé ni mò ń rìn,
mo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA láìṣiyèméjì.
2Yẹ̀ mí wò, OLUWA, dán mi wò;
yẹ inú mi wò, sì ṣe akiyesi ọkàn mi.
3Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ni mo tẹjúmọ́,
mo sì ń fi òtítọ́ bá ọ rìn.
4N kò jókòó ti àwọn èké,
n kò sì gba ìmọ̀ràn àwọn ẹlẹ́tàn;
5mo kórìíra wíwà pẹlu àwọn aṣebi,
n kò sì jẹ́ bá àwọn eniyan burúkú da nǹkan pọ̀.
6Ọwọ́ mi mọ́, n kò ní ẹ̀bi, OLUWA,
mo sì ń jọ́sìn yí pẹpẹ rẹ ká.
7Mò ń kọ orin ọpẹ́ sókè,
mo sì ń ròyìn iṣẹ́ ìyanu rẹ.
8OLUWA, mo fẹ́ràn ilé rẹ, tí ò ń gbé,
ati ibi tí ògo rẹ wà.
9Má pa mí run pẹlu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
má sì gba ẹ̀mí mi pẹlu ti àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ìpànìyàn,
10àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún iṣẹ́ ibi,
tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
11Ṣugbọn ní tèmi, èmi ń rìn ninu ìwà pípé;
rà mí pada, kí o sì ṣàánú mi.
12Mo dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú;
láwùjọ ọ̀pọ̀ eniyan ni n óo máa yin OLUWA.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 26: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀