ORIN DAFIDI 28

28
Adura Ìrànlọ́wọ́
1Ìwọ ni mo kígbe pè, OLUWA,
ìwọ ni ààbò mi, má di etí sí mi.
Nítorí bí o bá dákẹ́ sí mi
n óo dàbí àwọn òkú, tí wọ́n ti lọ sinu kòtò.
2Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi,
bí mo ti ń kígbe sí ọ pé kí o ràn mí lọ́wọ́;
tí mo gbé ọwọ́ mi sókè
sí ìhà ilé mímọ́ rẹ.
3Má ṣe kó mi lọ pẹlu àwọn eniyan burúkú,
pẹlu àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ ibi,
àwọn tí ń bá àwọn aládùúgbò wọn
sọ ọ̀rọ̀ alaafia,
ṣugbọn tí ètekéte ń bẹ ninu ọkàn wọn.
4San án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn,
àní gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ burúkú wọn;
san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn,
fún wọn ní èrè tí ó tọ́ sí wọn.
5Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ OLUWA sí,
wọn kò sì bìkítà fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,
OLUWA yóo sọ wọ́n di ilẹ̀,
kò sì ní gbé wọn dìde mọ́.#Ifi 22:12
6Ẹni ìyìn ni OLUWA!
Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
7OLUWA ni agbára ati asà mi,
òun ni mo gbẹ́kẹ̀lé;
ó ràn mí lọ́wọ́, ọkàn mi sì kún fún ayọ̀;
mo sì fi orin ìyìn dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.
8OLUWA ni agbára àwọn eniyan rẹ̀;
òun ni ààbò ìgbàlà fún ẹni àmì òróró rẹ̀.
9Gba àwọn eniyan rẹ là, OLUWA,
kí o sì bukun ilẹ̀ ìní rẹ.
Jẹ́ olùṣọ́-aguntan wọn,
kí o sì máa tọ́jú wọn títí lae.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 28: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀