ORIN DAFIDI 35
35
Adura ìrànlọ́wọ́
1OLUWA, gbógun ti àwọn tí ń gbógun tì mí;
gbé ìjà ko àwọn tí ń bá mi jà!
2Gbá asà ati apata mú,
dìde, kí o sì ràn mí lọ́wọ́!
3Fa ọ̀kọ̀ yọ kí o sì dojú kọ àwọn tí ń lépa mi!
Ṣe ìlérí fún mi pé, ìwọ ni olùgbàlà mi.
4Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi,
kí wọn ó tẹ́!
Jẹ́ kí àwọn tí ń gbìmọ̀ ibi sí mi dààmú,
kí wọ́n sì sá pada sẹ́yìn!
5Kí wọ́n dàbí fùlùfúlù ninu afẹ́fẹ́,
kí angẹli OLUWA máa lé wọn lọ!
6Jẹ́ kí ojú ọ̀nà wọn ṣóòkùn, kí ó sì máa yọ̀,
kí angẹli OLUWA máa lépa wọn!
7Nítorí wọ́n dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi láìnídìí,
wọ́n sì gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí láìnídìí.
8Jẹ́ kí ìparun dé bá wọn lójijì,
jẹ́ kí àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ dè mí mú wọn;
jẹ́ kí wọ́n kó sinu rẹ̀, kí wọ́n sì parun!
9Nígbà náà ni n óo máa yọ̀ ninu OLUWA,
n óo sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìgbàlà rẹ̀.
10N óo fi gbogbo ara wí pé,
“OLUWA, ta ni ó dàbí rẹ?
Ìwọ ni ò ń gba aláìlágbára
lọ́wọ́ ẹni tí ó lágbára
tí o sì ń gba aláìlágbára ati aláìní
lọ́wọ́ ẹni tí ó fẹ́ fi wọ́n ṣe ìjẹ.”
11Àwọn tí ń fi ìlara jẹ́rìí èké dìde sí mi;
wọ́n ń bi mí léèrè ohun tí n kò mọ̀dí.
12Wọ́n fi ibi san oore fún mi,
ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì.
13Bẹ́ẹ̀ sì ni, ní tèmi, nígbà tí wọn ń ṣàìsàn,
aṣọ ọ̀fọ̀ ni mo wọ̀;
mo fi ààwẹ̀ jẹ ara mi níyà;
mo gbadura pẹlu ìtẹríba patapata,
14bí ẹni pé mò ń ṣọ̀fọ̀ ọ̀rẹ́ mi, tabi arakunrin mi;
mò ń lọ káàkiri, bí ẹni tí ń pohùnréré ẹkún ìyá rẹ̀,
mo doríkodò, mo sì ń ṣọ̀fọ̀.
15Ṣugbọn nígbà tí èmi kọsẹ̀, wọ́n kó ara wọn jọ,
wọ́n ń yọ̀,
wọ́n kó tì mí;
pàápàá jùlọ, àwọn àlejò tí n kò mọ̀ rí
bẹ̀rẹ̀ sí purọ́ mọ́ mi léraléra.
16Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pẹ̀gàn mi, wọ́n ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà;
wọ́n sì ń wò mí bíi pé kí n kú.
Adura Ìdáláre
17OLUWA, yóo ti pẹ́ tó, tí o óo máa wò mí níran?
Yọ mí kúrò ninu ogun tí wọn gbé tì mí,
gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn kinniun!
18Nígbà náà ni n óo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ láàrin àwùjọ ọ̀pọ̀ eniyan;
láàrin ọpọlọpọ eniyan ni n óo máa yìn ọ́.
19Má jẹ́ kí àwọn tí ń bá mi ṣọ̀tá láìnídìí yọ̀ mí,
má sì jẹ́ kí àwọn tí ó kórìíra mi wò mí ní ìwò ẹ̀sín.#O. Daf 69:4; Joh 15:25
20Nítorí pé wọn kì í sọ̀rọ̀ alaafia sí àwọn tí wọn ń lọ jẹ́ẹ́jẹ́ wọn
àfi kí wọ́n máa pète oríṣìíríṣìí ẹ̀tàn.
21Wọ́n la ẹnu, wọ́n ń pariwo lé mi lórí,
wọ́n ń wí pé, “Ìn hín ìn, a rí ọ, ojú wa ló ṣe!”
22O ti rí i, OLUWA, má dákẹ́.
OLUWA, má jìnnà sí mi.
23Paradà, OLUWA, jí gìrì sí ọ̀ràn mi,
gbèjà mi, Ọlọrun mi, ati OLUWA mi!
24Dá mi láre, OLUWA, Ọlọrun mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ;
má sì jẹ́ kí wọ́n yọ̀ mí!
25Má jẹ́ kí wọ́n wí láàrin ara wọn pé,
“Ìn hín ìn, ọwọ́ wa ba ohun tí a fẹ́!”
Má jẹ́ kí wọn wí pé,
“A rẹ́yìn ọ̀tá wa.”
26Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí ń yọ̀ pé ìpọ́njú dé bá mi;
kí ìdààmú bá wọn;
bá mi da aṣọ ìtìjú ati ẹ̀tẹ́ bo àwọn tí ń gbé àgbéré sí mi.
27Kí àwọn tí ń wá ìdáláre mi
máa hó ìhó ayọ̀, kí inú wọn sì máa dùn,
kí wọ́n máa wí títí ayé pé,
“OLUWA tóbi,
inú rẹ̀ dùn sí alaafia àwọn iranṣẹ rẹ̀.”
28Nígbà náà ni n óo máa sọ̀rọ̀ òdodo rẹ,
n óo sì máa yìn ọ́ tọ̀sán-tòru.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 35: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010