ORIN DAFIDI 85
85
Adura Ire Orílẹ̀-Èdè
1OLUWA, o fi ojurere wo ilẹ̀ rẹ;
o dá ire Jakọbu pada.
2O dárí àìdára àwọn eniyan rẹ jì wọ́n;
o sì bo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.
3O mú ìrúnú rẹ kúrò;
o dáwọ́ ibinu gbígbóná rẹ dúró.
4Tún mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun Olùgbàlà wa;
dáwọ́ inú tí ń bí ọ sí wa dúró.
5Ṣé o óo máa bínú sí wa títí lae ni?
Ṣé ibinu rẹ yóo máa tẹ̀síwájú láti ìran dé ìran ni?
6Ṣé o ò ní tún sọ wá jí ni,
kí àwọn eniyan rẹ lè máa yọ̀ ninu rẹ?
7Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn wá, OLUWA;
kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ.
8Jẹ́ kí n gbọ́ ohun tí Ọlọrun, OLUWA yóo wí,
nítorí pé ọ̀rọ̀ alaafia ni yóo sọ fún àwọn eniyan rẹ̀,
àní, àwọn olùfọkànsìn rẹ̀,
ṣugbọn kí wọn má yipada sí ìwà òmùgọ̀.
9Nítòótọ́, ìgbàlà rẹ̀ wà nítòsí fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀;
kí ògo rẹ̀ lè wà ní ilẹ̀ wa.
10Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ yóo pàdé;
òdodo ati alaafia yóo dì mọ́ ara wọn.
11Òtítọ́ yóo rú jáde láti inú ilẹ̀;
òdodo yóo sì bojú wolẹ̀ láti ojú ọ̀run.
12Dájúdájú, OLUWA yóo fúnni ní ohun tí ó dára;
ilẹ̀ wa yóo sì mú èso jáde lọpọlọpọ.
13Òdodo yóo máa rìn lọ níwájú rẹ̀,
yóo sì sọ ipasẹ̀ rẹ̀ di ọ̀nà.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 85: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010