ORIN DAFIDI 9

9
Ọpẹ́ fún Ọlọrun nítorí Ìdájọ́ Òdodo Rẹ̀
1OLUWA, tọkàntọkàn ni n óo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ;
n óo ròyìn gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ.
2N óo yọ̀, inú mi yóo sì máa dùn nítorí rẹ;
n óo kọ orin ìyìn orúkọ rẹ, ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.
3Nígbà tí àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà,
wọ́n ṣubú, wọ́n sì parun níwájú rẹ.
4Nítorí ìwọ ni o fi ìdí ẹ̀tọ́ mi múlẹ̀, tí o sì dá mi láre;
ìwọ ni o jókòó lórí ìtẹ́, o sì ṣe ìdájọ́ òdodo.
5O bá àwọn orílẹ̀-èdè wí,
o pa àwọn eniyan burúkú run,
o sì pa orúkọ wọn rẹ́ títí lae.
6O pa àwọn ọ̀tá run patapata, o sọ ìlú wọn di ahoro,
o sì sọ wọ́n di ẹni ìgbàgbé.
7Ṣugbọn OLUWA gúnwà títí lae,
ó ti fi ìdí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀ múlẹ̀.
8Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé,
yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.
9OLUWA ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,
òun ni ibi ìsádi ní ìgbà ìpọ́njú.
10Àwọn tí ó mọ̀ ọ́ yóo gbẹ́kẹ̀lé ọ;
nítorí ìwọ, OLUWA, kìí kọ àwọn tí ń wá ọ sílẹ̀.
11Ẹ kọrin ìyìn sí OLUWA, tí ó gúnwà ní Sioni!
Ẹ kéde iṣẹ́ rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè!
12Nítorí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ranti,
kò sì gbàgbé igbe ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.
13OLUWA, ṣàánú fún mi!
Wò ó bí àwọn ọ̀tá mi ṣe ń pọ́n mi lójú.
Gbà mí kúrò létí bèbè ikú,
14kí n lè kọrin ìyìn rẹ,
kí n sì lè yọ ayọ̀ ìgbàlà rẹ lẹ́nu ibodè Sioni.
15Àwọn orílẹ̀-èdè ti jìn sinu kòtò tí wọ́n gbẹ́,
wọ́n sì ti kó sinu àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀.
16OLUWA ti fi ara rẹ̀ hàn, ó ti ṣe ìdájọ́,
àwọn eniyan burúkú sì ti kó sinu tàkúté ara wọn.
17Àwọn eniyan burúkú,
àní, gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọrun, ni yóo lọ sinu isà òkú.
18Nítorí pé OLUWA kò ní fi ìgbà gbogbo gbàgbé àwọn aláìní,
bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn talaka kò ní já sí òfo títí lae.
19Dìde, OLUWA, má jẹ́ kí eniyan ó borí,
jẹ́ kí á ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè níwájú rẹ.
20OLUWA, da ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ bò wọ́n,
jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé aláìlágbára eniyan ni àwọn.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 9: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀