ORIN DAFIDI 91
91
Ọlọrun Aláàbò wa
1Ẹni tí ń gbé abẹ́ ààbò Ọ̀gá Ògo,
tí ó wà lábẹ́ òjìji Olodumare,
2yóo wí fún OLUWA pé,
“Ìwọ ni ààbò ati odi mi,
Ọlọrun mi, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé.”
3Nítorí yóo yọ ọ́ ninu okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ
ati ninu àjàkálẹ̀ àrùn apanirun.
4Yóo da ìyẹ́ rẹ̀ bò ọ́,
lábẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀ ni o óo ti rí ààbò;
òtítọ́ rẹ̀ ni yóo jẹ́ asà ati apata rẹ.
5O ò ní bẹ̀rù ìdágìrì òru,
tabi ọfà tí ń fò kiri ní ọ̀sán,
6tabi àjàkálẹ̀ àrùn tí ń jà kiri ninu òkùnkùn,
tabi ìparun tí ń ṣeni lófò ní ọ̀sán gangan.
7Ẹgbẹrun lè ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,
tabi ẹgbaarun ni apá ọ̀tún rẹ;
ṣugbọn kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.
8Ojú nìkan ni óo kàn máa fi rí wọn,
tí o óo sì máa fi wo èrè àwọn eniyan burúkú.
9Nítorí tí ìwọ ti fi OLUWA ṣe ààbò rẹ,
o sì ti fi Ọ̀gá Ògo ṣe ibùgbé rẹ,
10ibi kankan kò ní dé bá ọ,
bẹ́ẹ̀ ni àjálù kankan kò ní súnmọ́ ilé rẹ.
11Nítorí yóo pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀, nítorí rẹ,
pé kí wọ́n máa pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ.
12Wọ́n óo fi ọwọ́ wọn gbé ọ sókè,
kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta.
13O óo rìn kọjá lórí kinniun ati paramọ́lẹ̀;
ẹgbọ̀rọ̀ kinniun ati ejò ńlá ni o óo fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.#Mat 4:6; Luk 4:10 #Mat 4:6; Luk 4:11 #Luk 10:19
14OLUWA ní, “Nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ sí mi,
n óo gbà á là;
n óo dáàbò bò ó, nítorí pé ó mọ orúkọ mi.
15Yóo pè mí, n óo sì dá a lóhùn;
n óo wà pẹlu rẹ̀ ninu ìṣòro,
n óo yọ ọ́ ninu rẹ̀, n óo dá a lọ́lá.
16N óo fi ẹ̀mí gígùn tẹ́ ẹ lọ́rùn,
n óo sì gbà á là.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 91: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010