ÌFIHÀN 11
11
Àwọn Ẹlẹ́rìí Meji
1Wọ́n fún mi ní ọ̀pá kan, bí èyí tí wọ́n fi ń wọn aṣọ. Wọ́n sọ fún mi pé, “Dìde! Lọ wọn Tẹmpili Ọlọrun ati pẹpẹ ìrúbọ, kí o ka iye àwọn tí wọ́n n jọ́sìn níbẹ̀.#Isi 40:3; Sak 2:1-2 2Má wulẹ̀ wọn àgbàlá Tẹmpili tí ó wà lóde, nítorí a ti fi fún àwọn alaigbagbọ. Wọn yóo gba ìlú mímọ́ fún oṣù mejilelogoji.#Luk 21:24 3N óo fún àwọn ẹlẹ́rìí mi meji láṣẹ láti kéde iṣẹ́ mi fún ọtalelẹgbẹfa (1260) ọjọ́. Aṣọ ọ̀fọ̀ ni wọn yóo wọ̀ ní gbogbo àkókò náà.”
4Àwọn wọnyi ni igi olifi meji ati ọ̀pá fìtílà meji tí ó dúró níwájú Oluwa ayé.#Sak 4:3, 11-14 5Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ pa wọ́n lára, iná ni yóo yọ lẹ́nu wọn, yóo sì jó àwọn ọ̀tá wọn run. Irú ikú bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ṣe wọ́n ní ibi yóo kú. 6Wọ́n ní àṣẹ láti ti ojú ọ̀run pa, tí òjò kò fi ní rọ̀ ní gbogbo àkókò tí wọn bá ń kéde. Wọ́n tún ní àṣẹ láti sọ gbogbo omi di ẹ̀jẹ̀. Wọ́n sì lè mú kí àjàkálẹ̀ àrùn oríṣìíríṣìí bá ayé, bí wọ́n bá fẹ́.#a 1 A. Ọba 17:1; b Eks 7:17-19 d Ais 4:8
7Nígbà tí wọ́n bá parí ẹ̀rí tí wọn níí jẹ́, ẹranko tí ó jáde láti inú kànga tí ó jìn tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò lè dé ìsàlẹ̀ rẹ̀, yóo wá bá wọn jagun. Yóo ṣẹgun wọn, yóo sì pa wọ́n.#a Dan 7:7; Ifi 13:5-7; 17:8; b Dan 7:21 8Òkú wọn yóo wà ní títì ìlú ńlá tí a ti kan Oluwa wọn mọ́ agbelebu. Àfiwé orúkọ rẹ̀ ni Sodomu ati Ijipti.#Ais 1:9-10 9Àwọn eniyan láti inú gbogbo ẹ̀yà, ati gbogbo orílẹ̀-èdè yóo máa wo òkú wọn fún ọjọ́ mẹta ati ààbọ̀. Wọn kò ní jẹ́ kí wọ́n sin wọ́n. 10Àwọn ọmọ aráyé yóo máa yọ̀ wọ́n, inú wọn yóo sì máa dùn. Wọn yóo máa fún ara wọn lẹ́bùn. Nítorí pé ìyọlẹ́nu ni àwọn akéde meji wọnyi jẹ́ fún àwọn tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ ayé. 11Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta ati ààbọ̀ yìí, èémí ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wọ inú wọn, ni wọ́n bá jí, wọn bá dìde dúró. Ẹ̀rù ba àwọn tí ó rí wọn gan-an.#Isi 37:10 12Wọ́n wá gbọ́ ohùn líle láti ọ̀run wá tí ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gòkè wá síhìn-ín.” Ni wọ́n bá gòkè lọ sọ́run ninu ìkùukùu, lójú àwọn ọ̀tá wọn.#2 A. Ọba 2:11 13Ilẹ̀ mì tìtì, ìdámẹ́wàá ìlú bá wó. Ẹẹdẹgbaarin (7,000) eniyan ni ó kú nígbà tí ilẹ̀ náà mì. Ẹ̀rù ba àwọn tí ó kù, wọ́n sì fi ògo fún Ọlọrun ọ̀run.#Ifi 6:12; 16:18
14Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú keji kọjá. Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kẹta fẹ́rẹ̀ dé.
Kàkàkí Keje
15Angẹli keje fun kàkàkí rẹ̀, àwọn ohùn líle kan ní ọ̀run bá sọ pé, “Ìjọba ayé di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀. Yóo jọba lae ati laelae.”#Eks 15:18; Dan 2:44; 7:14, 27 16Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun tí wọ́n jókòó lórí ìtẹ́ wọn níwájú Ọlọrun bá dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun. 17Wọ́n ní,
“A fi ìyìn fún ọ, Oluwa, Ọlọrun Olodumare,
ẹni tí ó wà, tí ó ti wà,
nítorí o ti gba agbára ńlá rẹ, o sì ń jọba.
18Inú àwọn orílẹ̀-èdè ru,
ṣugbọn àkókò ibinu rẹ dé,
ó tó àkókò láti ṣe ìdájọ́ àwọn òkú,
ati láti fi èrè fún àwọn iranṣẹ rẹ, àwọn wolii, àwọn eniyan rẹ,
ati àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ, ìbáà ṣe àwọn mẹ̀kúnnù tabi àwọn eniyan ńláńlá.
Àkókò dé láti pa àwọn tí ó ń ba ayé jẹ́ run.”#a O. Daf 2:5; 110:5; b O. Daf 115:13
19Tẹmpili Ọlọrun ti ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run, tí a fi lè rí àpótí majẹmu ninu rẹ̀. Mànàmáná wá bẹ̀rẹ̀ sí kọ, ààrá ń sán, ilẹ̀ ń mì tìtì; yìnyín sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ sílẹ̀.#2 Makab 2:4-8 a Ifi 8:5; 16:18; b Ifi 16:21
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌFIHÀN 11: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: