ÌFIHÀN 13
13
Àwọn Ẹranko Meji
1Mo wá rí ẹranko kan tí ń ti inú òkun jáde bọ̀. Ó ní ìwo mẹ́wàá ati orí meje. Adé mẹ́wàá wà lórí ìwo rẹ̀. Ó kọ orúkọ àfojúdi sára orí rẹ̀ kọ̀ọ̀kan.#a Dan 7:3; b Ifi 17:3, 7-12 2Ẹranko náà tí mo rí dàbí àmọ̀tẹ́kùn. Ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí ti ìkookò. Ẹnu rẹ̀ dàbí ti kinniun. Ẹranko Ewèlè náà fún un ní agbára rẹ̀, ati ìtẹ́ rẹ̀ ati àṣẹ ńlá rẹ̀.#Dan 7:4-6 3Ó dàbí ẹni pé wọ́n ti ṣá ọ̀kan ninu àwọn orí ẹranko náà lọ́gbẹ́. Ọgbẹ́ ọ̀hún tó ohun tí ó yẹ kí ó pa á ṣugbọn ó ti jinná. Gbogbo eniyan ni wọ́n ń tẹ̀lé ẹranko yìí tí wọ́n fi ń ṣe ìran wò. 4Wọ́n ń júbà Ẹranko Ewèlè náà nítorí pé ó fi àṣẹ fún ẹranko yìí. Wọ́n sì ń júbà ẹranko náà, wọ́n ń sọ pé, “Ta ni ó dàbí ẹranko yìí? Ta ni ó tó bá a jà?”
5A fún un ní ẹnu láti fi sọ̀rọ̀ tí ó ju ẹnu rẹ̀ lọ, ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. A fún un ní àṣẹ fún oṣù mejilelogoji. 6Ó bá ya ẹnu, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ó ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí orúkọ Ọlọrun ati sí àgọ́ rẹ̀, ati sí àwọn tí wọ́n ń gbé ọ̀run.#Dan 7:8, 25; 11:36 7A fún un ní agbára láti gbógun ti àwọn eniyan Ọlọrun ati láti ṣẹgun wọn. A tún fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ẹ̀yà ati orílẹ̀-èdè ati oríṣìíríṣìí èdè ati gbogbo eniyan.#Dan 7:21 8Gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú ayé tí a kò kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè bá ń júbà rẹ̀. Láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé ni a kò ti kọ orúkọ wọn sinu ìwé Ọ̀dọ́ Aguntan tí a pa.#O. Daf 69:28
9Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́! 10Bí ẹnikẹ́ni bá níláti lọ sí ìgbèkùn, yóo lọ sí ìgbèkùn. Bí ẹnikẹ́ni bá fi idà pa eniyan, idà ni a óo fi pa òun náà. Níhìn-ín ni ìfaradà ati ìdúró ṣinṣin àwọn eniyan Ọlọrun yóo ti hàn.#Jer 15:2; 43:11
11Mo tún rí ẹranko mìíràn tí ó jáde láti inú ilẹ̀. Ó ní ìwo meji bíi ti Ọ̀dọ́ Aguntan. Ó ń sọ̀rọ̀ bíi ti Ẹranko Ewèlè. 12Ó ń lo àṣẹ bíi ti ẹranko àkọ́kọ́, lójú ẹranko àkọ́kọ́ fúnrarẹ̀. Ó mú kí ayé ati àwọn tí ó ń gbé inú rẹ̀ júbà ẹranko àkọ́kọ́, tí ọgbẹ́ rẹ̀ ti san. 13Ó ń ṣe iṣẹ́ abàmì ńláńlá. Ó mú kí iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá sí ayé lójú àwọn eniyan. 14Ó fi iṣẹ́ abàmì tí a fi fún un láti ṣe níwájú ẹranko náà tan àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé jẹ. Ó sọ fún wọn pé kí wọ́n yá ère ẹranko tí a ti fi idà ṣá lọ́gbẹ́ tí ó tún yè. 15A fún un ní agbára láti fi èémí sinu ère ẹranko náà, kí ère ẹranko náà lè fọhùn, kí ó lè pa àwọn tí kò bá júbà ère ẹranko náà. 16Lẹ́yìn náà, gbogbo eniyan, ati àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan ńláńlá ati ọlọ́rọ̀ ati talaka, ati ẹrú ati òmìnira ni ẹranko yìí mú kí wọ́n ṣe àmì sí ọwọ́ ọ̀tún tabi iwájú wọn. 17Kò sí ẹni tí ó lè ra ohunkohun tabi kí ó ta ohunkohun àfi ẹni tí ó bá ní àmì orúkọ ẹranko náà tabi ti iye orúkọ rẹ̀ lára.
18Ohun tí ó gba ọgbọ́n nìyí. Ẹni tí ó bá ní òye ni ó lè mọ ìtumọ̀ àmì orúkọ ẹranko náà, nítorí pé bí orúkọ eniyan kan gan-an ni àmì yìí rí. Ìtumọ̀ iye àmì náà ni ọtalelẹgbẹta, ó lé mẹfa (666).
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌFIHÀN 13: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: