RUTU 4
4
Boasi Ṣú Rutu Lópó
1Boasi bá lọ sí ẹnu ibodè ìlú, ó jókòó níbẹ̀. Bí ìbátan ọkọ Rutu tí ó súnmọ́ ọn, tí Boasi sọ nípa rẹ̀ ti ń kọjá lọ, ó pè é, ó ní, “Ọ̀rẹ́, yà sí ibí, kí o sì jókòó.” Ọkunrin náà bá yà, ó sì jókòó. 2Boasi pe àwọn mẹ́wàá ninu àwọn àgbààgbà ìlú, ó ní, “Ẹ wá jókòó sí ibí.” Wọ́n bá jókòó. 3Lẹ́yìn náà, ó pe ìbátan ọkọ Rutu yìí, ó ní, “Naomi tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ àwọn ará Moabu pada dé, fẹ́ ta ilẹ̀ kan tí ó jẹ́ ti Elimeleki ìbátan wa. 4Nítorí náà, mo rò ó ninu ara mi pé, kí n kọ́ sọ fún ọ pé kí o rà á, níwájú àwọn tí wọ́n jókòó níhìn-ín, ati níwájú àwọn àgbààgbà, àwọn eniyan wa; bí o bá gbà láti rà á pada, rà á. Ṣugbọn bí o kò bá fẹ́ rà á pada, sọ fún mi, kí n lè mọ̀, nítorí pé kò sí ẹni tí ó tún lè rà á pada, àfi ìwọ, èmi ni mo sì tẹ̀lé ọ.” Ọkunrin yìí dáhùn pé òun óo ra ilẹ̀ náà pada.
5Boasi bá fi kún un pé, “Ọjọ́ tí o bá ra ilẹ̀ yìí ní ọwọ́ Naomi, bí o bá ti ń ra ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni óo ra Rutu, ará ilẹ̀ Moabu, opó ọmọ Naomi; kí orúkọ òkú má baà parun lára ogún rẹ̀.”
6Ìbátan Elimeleki yìí dáhùn, ó ní, “Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, n kò ní lè ra ilẹ̀ náà pada, nítorí kò ní jẹ́ kí àwọn ọmọ tèmi lè jogún mi bí ó ti yẹ. Bí o bá fẹ́, o lè fi ọwọ́ mú ohun tí ó jẹ́ ẹ̀tọ́ mi yìí, nítorí pé n kò lè rà á pada.”
7Ní àkókò yìí, ohun tí ó jẹ́ àṣà àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ètò ìràpada ati pàṣípààrọ̀ ohun ìní ni pé ẹni tí yóo bá ta nǹkan yóo bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀, yóo sì kó o fún ẹni tí yóo rà á. Bàtà yìí ni ó dàbí ẹ̀rí ati èdìdì láàrin ẹni tí ń ta nǹkan ati ẹni tí ń rà á, ní ilẹ̀ Israẹli.
8Nítorí náà, nígbà tí ìbátan náà wí fún Boasi pé, “Rà á bí o bá fẹ́.” Ó bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ fún Boasi,#Diut 25:9 9Boasi bá sì sọ fún àwọn àgbààgbà ati gbogbo àwọn eniyan, ó ní, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí lónìí pé mo ti ra gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti Elimeleki ati ti Kilioni ati ti Maloni lọ́wọ́ Naomi. 10Ati pé, mo ṣú Rutu, ará Moabu, opó Maloni lópó, ó sì di aya mi; kí orúkọ òkú má baà parun lára ohun ìní rẹ̀, ati pé kí á má baà mú orúkọ rẹ̀ kúrò láàrin àwọn arakunrin rẹ̀ ati ní ẹnu ọ̀nà àtiwọ ìlú baba rẹ̀. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí lónìí.”#Diut 25:5-6
11Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní ẹnu ọ̀nà ibodè ati àwọn àgbààgbà náà dáhùn pé, “Àwa ni ẹlẹ́rìí, kí OLUWA kí ó ṣe obinrin tí ń bọ̀ wá di aya rẹ bíi Rakẹli ati Lea, tí wọ́n bí ọpọlọpọ ọmọ fún Jakọbu. Yóo dára fún ọ ní Efurata, o óo sì di olókìkí ní Bẹtilẹhẹmu.#Jẹn 29:31 12Àwọn ọmọ tí OLUWA yóo jẹ́ kí obinrin yìí bí fún ọ yóo kún ilé rẹ fọ́fọ́, bí ọmọ ti kún ilé Peresi, tí Tamari bí fún Juda.”#Jẹn 38:27-30
Boasi ati Ìrandíran Rẹ̀
13Boasi bá ṣú Rutu lópó, Rutu sì di aya rẹ̀. Nígbà tí Boasi bá a lòpọ̀, ó lóyún, ó bí ọmọkunrin kan. 14Àwọn obinrin bá sọ fún Naomi pé, “Ìyìn ni fún OLUWA, tí kò ṣe ọ́ ní aláìní ìbátan, kí OLUWA ṣe ọmọ náà ní olókìkí ní Israẹli. 15Ọmọ yìí yóo mú kí adùn ayé rẹ sọjí, yóo sì jẹ́ olùtọ́jú fún ọ ní ọjọ́ ogbó rẹ, nítorí iyawo ọmọ rẹ tí ó fẹ́ràn rẹ, tí ó sì ju ọmọkunrin meje lọ ni ó bímọ fún ọ.” 16Naomi bá gba ọmọ náà, ó tẹ́ ẹ sí àyà rẹ̀, ó sì di olùtọ́jú rẹ̀.
17Àwọn obinrin àdúgbò bá sọ ọmọ náà ní Obedi, wọ́n ń sọ káàkiri pé, “A bí ọmọkunrin kan fún Naomi.” Obedi yìí ni baba Jese tíí ṣe baba Dafidi.
18Àwọn atọmọdọmọ Peresi nìwọ̀nyí: Peresi ni baba Hesironi; 19Hesironi bí Ramu, Ramu bí Aminadabu; 20Aminadabu bí Naṣoni; Naṣoni bí Salimoni; 21Salimoni bí Boasi, Boasi bí Obedi; 22Obedi bí Jese, Jese sì bí Dafidi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
RUTU 4: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: