ORIN SOLOMONI 6
6
1Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ,
ìwọ, arẹwà jùlọ láàrin àwọn obinrin?
Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí,
kí á lè bá ọ wá a?
Obinrin
2Olùfẹ́ mi ti lọ sinu ọgbà rẹ̀,
níbi ebè igi turari,
ó da ẹran rẹ̀ lọ sinu ọgbà,
ó lọ já òdòdó lílì.
3Olùfẹ́ mi ló ni mí,
èmi ni mo sì ni olùfẹ́ mi.
Láàrin òdòdó lílì,
ni ó ti ń da ẹran rẹ̀.
Orin Karun-un
Ọkunrin
4Olùfẹ́ mi, o dára bíi Tirisa.
O lẹ́wà bíi Jerusalẹmu,
O níyì bíi ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun tí ń gbé ọ̀págun.
5Yíjú kúrò lọ́dọ̀ mi,
nítorí wọn kò jẹ́ kí n gbádùn.
Irun orí rẹ dàbí ọ̀wọ́ ewúrẹ́ ninu agbo,
tí ń sọ̀kalẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Gileadi.
6Eyín rẹ dàbí ọ̀wọ́ aguntan,
tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ wẹ̀ tán,
gbogbo wọn gún régé,
kò sì sí ọ̀kan tí ó yọ ninu wọn,
7Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ìlàjì èso pomegiranate lábẹ́ ìbòjú rẹ.
8Àwọn ayaba ìbáà tó ọgọta,
kí àwọn obinrin mìíràn sì tó ọgọrin,
kí àwọn iranṣẹbinrin sì pọ̀, kí wọn má lóǹkà,
9sibẹ, ọ̀kan ṣoṣo ni àdàbà mi, olùfẹ́ mi tí ó péye.
Ọmọlójú ìyá rẹ̀,
ẹni tí kò ní àbààwọ́n lójú ẹni tí ó bí i.
Àwọn iranṣẹbinrin ń pe ìyá rẹ̀ ní olóríire.
Àwọn ayaba ati àwọn obinrin mìíràn ní ààfin sì ń yìn ín.
10Ta ni ń yọ bọ̀ bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ yìí,
tí ó mọ́ bí ọjọ́,
tí ó lẹ́wà bí òṣùpá.
Tí ó sì bani lẹ́rù,
bí àwọn ọmọ ogun tí wọn dira ogun?
11Mo lọ sinu ọgbà igi eléso,
mo lọ wo ẹ̀ka igi tútù ní àfonífojì,
pé bóyá àwọn àjàrà ti rúwé,
ati pé bóyá àwọn igi èso pomegiranate tí ń tanná.
12Kí n tó fura,
ìfẹ́ tí ṣe mí bí ẹni tí ó wà ninu ọkọ̀ ogun,
tí ara ń wá bíi kí ó bọ́ sójú ogun.
Àwọn Obinrin
13Máa pada bọ̀, máa pada bọ̀, ìwọ ọmọbinrin ará Ṣulamu.
Máa pada bọ̀, kí á lè máa fi ọ́ ṣe ìran wò.
Obinrin
Ẹ óo ṣe máa fi ará Ṣulamu ṣe ìran wò
bí ẹni wo ẹni tí ó ń jó
níwájú ọ̀wọ́ ọmọ ogun meji?
Ọkunrin
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN SOLOMONI 6: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010