SAKARAYA 14
14
Jerusalẹmu ati Àwọn Orílẹ̀-Èdè
1Wò ó! Ọjọ́ OLUWA ń bọ̀ tí wọn yóo pín àwọn ìkógun tí wọ́n kó ní ilẹ̀ Jerusalẹmu lójú yín. 2Nítorí n óo kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ láti gbógun ti ìlú Jerusalẹmu. Wọn yóo ṣẹgun rẹ̀, wọn yóo kó àwọn eniyan ibẹ̀ lẹ́rù lọ, wọn yóo sì fi tipátipá bá àwọn obinrin wọn lòpọ̀. Ìdajì àwọn ará ìlú náà yóo lọ sóko ẹrú, ṣugbọn ìdajì yòókù ninu wọn yóo wà láàrin ìlú. 3OLUWA yóo wá jáde, yóo bá àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi jà, bí ìgbà tí ó ń jà lójú ogun. 4Tó bá di àkókò náà, yóo dúró lórí òkè olifi tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jerusalẹmu; òkè olifi yóo sì pín sí meji. Àfonífojì tí ó gbòòrò yóo sì wà láàrin rẹ̀ láti apá ìlà oòrùn dé apá ìwọ̀ oòrùn. Apá kan òkè náà yóo lọ ìhà àríwá, apá keji yóo sì lọ sí ìhà gúsù. 5Ẹ óo sá àsálà gba ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó pín òkè náà sí meji. Ẹ óo sá bí àwọn baba ńlá yín ti sá nígbà tí ilẹ̀ mì tìtì ní àkókò Usaya, ọba Juda, OLUWA, Ọlọrun yín yóo wá dé, pẹlu gbogbo àwọn eniyan mímọ́ rẹ̀.
6Tó bá di ìgbà náà, kò ní sí òtútù tabi òjò dídì mọ́, 7kò ní sí òkùnkùn, kò ní sí ọ̀sán, kò ní sí òru bíkòṣe ìmọ́lẹ̀ nígbà gbogbo. Ṣugbọn OLUWA nìkan ló mọ ìgbà tí nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀.
8Tó bá di ìgbà náà, àwọn odò tí wọ́n kún fún omi ìyè yóo máa ṣàn jáde láti Jerusalẹmu. Apá kan wọn yóo máa ṣàn lọ sinu òkun tí ó wà ní ìwọ̀ oòrùn, apá keji yóo máa ṣàn lọ sí òkun tí ó wà ní ìlà oòrùn, yóo sì máa rí bẹ́ẹ̀ tòjò-tẹ̀ẹ̀rùn.#Ẹsr 47:1; Joh 7:38; Ifi 22:1 9OLUWA yóo wá jọba ní gbogbo ayé; Ọlọrun nìkan ni gbogbo aráyé yóo máa sìn nígbà náà, orúkọ kanṣoṣo ni wọn yóo sì mọ̀ ọ́n.
10A óo sọ gbogbo ilẹ̀ náà di pẹ̀tẹ́lẹ̀, láti Geba ní ìhà àríwá, títí dé Rimoni ní ìhà gúsù. Ṣugbọn Jerusalẹmu yóo yọ kedere láàrin àwọn ilẹ̀ tí ó yí i ká, láti ẹnubodè Bẹnjamini, lọ dé ẹnubodè àtijọ́ ati dé ẹnubodè Igun, láti ilé-ìṣọ́ Hananeli dé ibi tí wọ́n ti ń pọn ọtí fún ọba. 11Àwọn eniyan yóo máa gbé inú ìlú Jerusalẹmu, kò ní sí ègún mọ́, ìlú Jerusalẹmu yóo sì wà ní alaafia.#Ifi 22:3
12Àjàkálẹ̀ àrùn tí OLUWA yóo fi bá àwọn tí wọ́n bá gbógun ti ilẹ̀ Jerusalẹmu jà nìyí: Ẹran ara wọn yóo rà nígbà tí wọ́n ṣì wà láàyè, ojú wọn yóo rà ninu ihò rẹ̀, ahọ́n wọn yóo sì rà lẹ́nu wọn.
13Tó bá di ìgbà náà, OLUWA yóo mú ìbẹ̀rùbojo bá wọn tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóo fi máa pa ara wọn; 14Àwọn ará Juda pàápàá yóo máa bá àwọn ará Jerusalẹmu jà. A óo kó ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i ká jọ: ati fadaka, ati wúrà, ati ọpọlọpọ aṣọ.
15Àjàkálẹ̀ àrùn burúkú náà yóo kọlu àwọn ẹṣin, ìbakasíẹ, ràkúnmí, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati gbogbo àwọn ẹran tí wọ́n bá wà ní ibùdó ogun wọn.
16Àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù láti àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo tí ó gbógun ti ilẹ̀ Jerusalẹmu yóo máa wá lọdọọdun láti sin Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ní ìlú Jerusalẹmu ati láti ṣe Àjọ̀dún Àgọ́.#Lef 23:39-43 17Bí ẹnikẹ́ni bá kọ̀ tí kò lọ sí ìlú Jerusalẹmu lọ sin Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun, òjò kò ní rọ̀ sí ilẹ̀ rẹ̀. 18Bí ó bá ṣe pé àwọn ará Ijipti ni wọ́n kọ̀ tí wọn kò wá síbi Àjọ̀dún Àgọ́ náà, irú àrùn tí OLUWA fi bá àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò wá sí ibi Àjọ Àgọ́ jà, ni yóo dà lé wọn lórí. 19Èyí ni ìyà tí yóo jẹ ilẹ̀ Ijipti ati gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò bá wá síbi Àjọ Àgọ́.
20Tó bá di ìgbà náà, a óo máa kọ “MÍMỌ́ SÍ OLUWA,” sí ara aago tí wọn ń so mọ́ ẹṣin lára. Ìkòkò inú ilé OLUWA, yóo sì máa dàbí àwọn àwo tí ó wà níwájú pẹpẹ. 21Gbogbo ìkòkò tí ó wà ní Jerusalẹmu ati ní Juda yóo di mímọ́ fún OLUWA àwọn ọmọ ogun. Àwọn tí wọ́n wá ṣe ìrúbọ yóo máa se ẹran ẹbọ wọn ninu ìkòkò wọnyi. Kò ní sí oníṣòwò ní ilé OLUWA àwọn ọmọ ogun mọ́ tó bá di ìgbà náà.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
SAKARAYA 14: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: