SAKARAYA 3

3
Ìran wolii náà nípa Olórí Alufaa
1Lẹ́yìn náà, OLUWA fi Joṣua olórí alufaa hàn mí; ó dúró níwájú angẹli OLUWA, Satani sì dúró lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ láti fi ẹ̀sùn kàn án. 2Angẹli OLUWA sọ fún Satani pé, “OLUWA óo bá ọ wí, ìwọ Satani! OLUWA tí ó yan Jerusalẹmu óo bá ọ wí! Ṣebí ẹ̀ka igi tí a yọ jáde láti inú iná ni ọkunrin yìí?”#Ẹsr 5:2; Ifi 12:10 #Jud 9
3Joṣua dúró níwájú angẹli Ọlọrun, pẹlu aṣọ tí ó dọ̀tí ní ọrùn rẹ̀. 4Angẹli náà bá sọ fún àwọn tí wọ́n dúró tì í pé, “Ẹ bọ́ aṣọ tí ó dọ̀tí yìí kúrò lọ́rùn rẹ̀.” Ó bá sọ fún Joṣua pé, “Wò ó! Mo ti mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò, n óo sì fi aṣọ tí ó lẹ́wà wọ̀ ọ́.”
5Ó bá pàṣẹ pé, “Ẹ fi aṣọ mímọ́ wé e lórí.” Wọ́n bá fi aṣọ mímọ́ wé e lórí, wọ́n wọ̀ ọ́ ní aṣọ funfun, angẹli OLUWA sì dúró tì í.
6Angẹli náà kìlọ̀ fún Joṣua pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, 7“Bí o bá tẹ̀lé ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin mi mọ́, o óo di alákòóso ilé mi ati àwọn àgbàlá rẹ̀. N óo sì fún ọ ní ipò láàrin àwọn tí wọ́n dúró wọnyi. 8Gbọ́ nisinsinyii, ìwọ Joṣua, olórí alufaa, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin alufaa alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀, ẹ̀yin ni àmì ohun rere tí ń bọ̀, pé n óo mú iranṣẹ mi wá, tí a pè ní Ẹ̀ka. 9Wò ó! Nítorí mo gbé òkúta kan tí ó ní ojú meje siwaju Joṣua, n óo sì kọ àkọlé kan sórí rẹ̀. Lọ́jọ́ kan ṣoṣo ni n óo mú ẹ̀ṣẹ̀ ilẹ̀ yìí kúrò. 10Ní ọjọ́ náà, olukuluku yóo pe aládùúgbò rẹ̀ láti wá bá a ṣe fàájì lábẹ́ àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀.”#Jer 23:5; 33:15; Sak 6:12 #Mika 4:4

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

SAKARAYA 3: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀