SAKARAYA 6
6
Ìran nípa Àwọn Kẹ̀kẹ́ Ogun Mẹrin
1Mo tún gbé ojú sókè, mo rí kẹ̀kẹ́ ogun mẹrin tí ń bọ̀ láàrin òkè meji; òkè idẹ ni àwọn òkè náà. 2Àwọn ẹṣin pupa ni wọ́n ń fa kẹ̀kẹ́ ogun àkọ́kọ́, àwọn ẹṣin dúdú ń fa kẹ̀kẹ́ ogun keji, 3ẹṣin funfun ń fa ẹkẹta, àwọn tí wọn ń fa ẹkẹrin sì jẹ́ kàláńkìnní. 4Mo bi angẹli náà pé, “Oluwa mi, kí ni ìtumọ̀ ìwọ̀nyí?”#Ifi 6:4; Ifi 6:5 #Ifi 6:2
5Angẹli náà bá dáhùn pé, “Àwọn wọnyi ni wọ́n ń lọ sí igun mẹrẹẹrin ayé lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn han Ọlọrun ẹlẹ́dàá gbogbo ayé.”#Ifi 7:1
6Àwọn ẹṣin dúdú ń fa kẹ̀kẹ́ tiwọn lọ sí ìhà àríwá, àwọn ẹṣin funfun ń lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, àwọn tí wọ́n jẹ́ kàláńkìnní ń lọ sí ìhà gúsù. 7Bí àwọn ẹṣin tí wọ́n jẹ́ kàláńkìnní ti jáde, wọ́n ń kánjú láti lọ máa rin ayé ká. Angẹli náà bá pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n lọ; wọ́n sì lọ. 8Angẹli náà bá ké sí mi, ó ní, “Àwọn ẹṣin tí wọn ń lọ sí ìhà àríwá ti jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀ nípa ibẹ̀.”
Àṣẹ nípa ati Dé Joṣua ládé
9OLUWA pàṣẹ fún mi pé, 10“Lára àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ti oko ẹrú Babiloni dé, mú Helidai, Tobija ati Jedaaya lẹsẹkẹsẹ, kí o lọ sí ilé Josaya ọmọ Sefanaya. 11Gba fadaka ati wúrà lọ́wọ́ wọn, kí o fi ṣe adé, kí o sì fi adé náà dé Joṣua olórí alufaa, ọmọ Jehosadaki lórí. 12Kí o sì sọ ohun tí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí fún un, pé, ‘Wò ó! Ọkunrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀ka ni yóo gba ipò rẹ̀, òun ni yóo sì kọ́ ilé OLUWA.#Jer 23:5; 33:15; Sak 3:8 13Òun gan-an ni yóo kọ́ ọ, tí yóo sì gba ògo ati ẹ̀yẹ tí ó yẹ fún ọba, yóo sì jọba lórí ìtẹ́ rẹ̀. Yóo ní alufaa gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn, wọn yóo sì máa ṣiṣẹ́ pọ̀ ní alaafia.’ 14Adé náà yóo wà ní ilé OLUWA gẹ́gẹ́ bí ohun ìrántí fún Helidai ati Tobija ati Jedaaya ati Josaya, ọmọ Sefanaya.
15“Àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn réré yóo wá láti ba yín kọ́ ilé OLUWA. Ẹ óo wá mọ̀ dájú pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó rán mi si yín. Gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹ patapata bí ẹ bá pa òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
SAKARAYA 6: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: