SAKARAYA 9
9
Ìdájọ́ lórí Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tí Wọ́n Wà ní Agbègbè Israẹli
1OLUWA ní ilẹ̀ Hadiraki yóo jìyà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìlú Damasku. Nítorí pé OLUWA ló ni àwọn ìlú Aramu, bí ó ti ni àwọn ẹ̀yà Israẹli.#Ais 17:1-3; Jer 49:23-27; Amos 1:3-5 2Tirẹ̀ ni ilẹ̀ Hamati tí ó bá Israẹli pààlà. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ìlú Tire ati Sidoni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n. 3Ìlú Tire ti mọ odi ààbò yí ara rẹ̀ ká, ó ti kó fadaka jọ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ó sì rọ́ wúrà jọ bíi pàǹtí láàrin ìta gbangba. 4Ṣugbọn OLUWA yóo gba gbogbo ohun ìní Tire, yóo kó gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ dà sinu òkun, iná yóo sì jó o ní àjórun.#Ais 23: 1-18; Isi 26:1-28:26; Joẹl 3:4-8; Amos 1:9-10; Mat 11:21-22; Luk 10:13-14
5Ìlú Aṣikeloni yóo rí i, ẹ̀rù yóo sì bà á, ìlú Gasa yóo rí i, yóo sì máa joró nítorí ìrora. Bákan náà ni yóo rí fún ìlú Ekironi, nítorí ìrètí rẹ̀ yóo di òfo. Ọba ìlú Gasa yóo ṣègbé, ìlú Aṣikeloni yóo sì di ahoro. 6Oríṣìíríṣìí ẹ̀yà ni yóo máa gbé Aṣidodu; ìgbéraga Filistia yóo sì dópin. 7N óo gba ẹ̀jẹ̀ ati ohun ìríra kúrò ní ẹnu rẹ̀, àwọn tí yóo kù ninu wọn yóo di ti Ọlọrun wa; wọn yóo dàbí ìdílé kan ninu ẹ̀yà Juda, ìlú Ekironi yóo sì dàbí ìlú Jebusi.#Ais 14:29-31; Jer 47:1-7; Isi 25:15-17; Joẹl 3:4-8; Amos 1:6-8; Sef 2:4-7 8Ṣugbọn n óo dáàbò bo ilé mi, kí ogun ọ̀tá má baà kọjá níbẹ̀; aninilára kò ní mú wọn sìn mọ́, nítorí nisinsinyii, èmi fúnra mi ti fi ojú rí ìyà tí àwọn eniyan mi ti jẹ.
Ọba Tí Ń Bọ̀ Wá Jẹ
9Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni!
Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu!
Wò ó! Ọba yín ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín;
ajagun-ṣẹ́gun ni,
sibẹsibẹ ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
kódà, ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni ó gùn.#Mat 21:5; Joh 12:15
10OLUWA ní, òun óo kó kẹ̀kẹ́ ogun kúrò ní Efuraimu,
òun óo kó ẹṣin ogun kúrò ní Jerusalẹmu,
a óo sì ṣẹ́ ọfà ogun.
Yóo fún àwọn orílẹ̀-èdè ní alaafia,
ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ yóo jẹ́ láti òkun dé òkun
ati láti odò Yufurate títí dé òpin ayé.#O. Daf 72:8
Ìmúpadà sípò Àwọn Eniyan Mi
11Ìwọ ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ tí mo fi bá ọ dá majẹmu,
n óo dá àwọn eniyan rẹ tí a kó lẹ́rú sílẹ̀ láti inú kànga tí kò lómi.#9:11 Eks 24:8
12Ẹ pada sí ibi ààbò yín,
ẹ̀yin tí a kó lẹ́rú lọ tí ẹ sì ní ìrètí;
mo ṣèlérí lónìí pé,
n óo dá ibukun yín pada ní ìlọ́po meji.
13Nítorí mo ti tẹ Juda bí ọrun mi,
mo sì ti fi Efuraimu ṣe ọfà rẹ̀.
Ìwọ Sioni, n óo lo àwọn ọmọ rẹ bí idà,
láti pa àwọn ará Giriki run,
n óo sì fi tagbára tagbára lò yín
bí idà àwọn jagunjagun.
14OLUWA yóo fara han àwọn eniyan rẹ̀,
yóo ta ọfà rẹ̀ bíi mànàmáná.
OLUWA Ọlọrun yóo fọn fèrè ogun
yóo sì rìn ninu ìjì líle ti ìhà gúsù.
15OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo dáàbò bo àwọn eniyan rẹ̀.
Wọn óo borí àwọn ọ̀tá wọn,
wọn óo fi idà pa àwọn ọ̀tá wọn,
ẹ̀jẹ̀ wọn yóo sì máa ṣàn bíi ti ẹran ìrúbọ,
tí a dà sórí pẹpẹ,
láti inú àwo tí wọ́n fi ń gbe ẹ̀jẹ̀ ẹran.
16Ní ọjọ́ náà, OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n,
bí ìgbà tí olùṣọ́-aguntan bá gba àwọn aguntan rẹ̀.
Wọn óo máa tàn ní ilẹ̀ rẹ̀,
bí òkúta olówó iyebíye tíí tàn lára adé.
17Báwo ni ilẹ̀ náà yóo ti dára tó, yóo sì ti lẹ́wà tó?
Ọkà yóo sọ àwọn ọdọmọkunrin di alágbára
ọtí waini titun yóo sì fún àwọn ọdọmọbinrin ní okun.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
SAKARAYA 9: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: