Njẹ onirũru ẹ̀bun li o wà, ṣugbọn Ẹmí kanna ni. Onirũru iṣẹ-iranṣẹ li ó si wà, Oluwa kanna si ni. Onirũru iṣẹ li o si wà, ṣugbọn Ọlọrun kanna ni ẹniti nṣiṣẹ gbogbo wọn ninu gbogbo wọn. Ṣugbọn a nfi ifihàn Ẹmí fun olukuluku enia lati fi jère. Nitoriti a fi ọ̀rọ ọgbọ́n fun ẹnikan nipa Ẹmí; ati fun ẹlomiran ọ̀rọ-ìmọ nipa Ẹmí kanna; Ati fun ẹlomiran igbagbọ́ nipa Ẹmí kanna; ati fun ẹlomiran ẹ̀bun imularada nipa Ẹmí kanna; Ati fun ẹlomiran iṣẹ iyanu iṣe; ati fun ẹlomiran isọtẹlẹ; ati fun ẹlomiran ìmọ ẹmí yatọ; ati fun ẹlomiran onirũru ède; ati fun ẹlomiran itumọ̀ ède: Ṣugbọn gbogbo wọnyi li ẹnikan nì, ani Ẹmí kanna nṣe, o npín fun olukuluku gẹgẹ bi o ti wù u.
Kà I. Kor 12
Feti si I. Kor 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kor 12:4-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò