I. Tes 2
2
Iṣẹ́ Paulu ní Tẹsalonika
1NITORI ẹnyin tikaranyin mọ̀, ará, irú iwọle wa si nyin pe kì iṣe lasan:
2Ṣugbọn lẹhin ti awa ti jìya ṣaju, ti a si ti lo wa ni ilo itiju ni Filippi gẹgẹ bi ẹnyin ti mọ̀, awa ni igboiya ninu Ọlọrun wa lati sọ̀rọ ihinrere Ọlọrun fun nyin pẹlu ọ̀pọlọpọ ìwàyá ìjà.
3Nitori ọ̀rọ iyanju wa kì iṣe ti ẹ̀tan, tabi ti ìwa aimọ́, tabi ninu arekereke:
4Ṣugbọn bi a ti kà wa yẹ lati ọdọ Ọlọrun wá bi ẹniti a fi ihinrere le lọwọ, bẹ̃ li awa nsọ; kì iṣe bi ẹniti nwù enia bikoṣe Ọlọrun, ti ndan ọkàn wa wò.
5Nitori awa kò lo ọrọ ipọnni nigbakan rí gẹgẹ bi ẹnyin ti mọ̀, tabi iboju ojukòkoro; Ọlọrun li ẹlẹri:
6Bẹni awa kò wá ogo lọdọ enia, tabi lọdọ nyin, tabi lọdọ awọn ẹlomiran, nigbati awa iba fẹ ọla lori nyin bi awọn aposteli Kristi.
7Ṣugbọn awa nṣe pẹlẹ lọdọ nyin, gẹgẹ bi abiyamọ ti ntọju awọn ọmọ on tikararẹ:
8Bẹ̃ gẹgẹ bi awa ti ni ifẹ inu rere si nyin, inu wa dun jọjọ lati fun nyin kì iṣe ihinrere Ọlọrun nikan, ṣugbọn ẹmí awa tikarawa pẹlu, nitoriti ẹnyin jẹ ẹni ọ̀wọ́n fun wa.
9Nitori ẹnyin ranti, ará, ìṣẹ́ ati lãlã wa: nitori awa nṣe lãlã li ọsán ati li oru, ki awa ko má bã di ẹrù ru ẹnikẹni ninu nyin, awa wasu ihinrere Ọlọrun fun nyin.
10Ẹnyin si li ẹlẹri, ati Ọlọrun pẹlu, bi awa ti wà lãrin ẹnyin ti o gbagbọ́ ni mimọ́ iwà ati li ododo, ati li ailẹgan:
11Gẹgẹ bi ẹnyin si ti mọ̀ bi awa ti mba olukuluku nyin lo gẹgẹ bi baba si awọn ọmọ rẹ̀, a ngba nyin niyanju, a ntu nyin ninu, a si kọ́,
12Ki ẹnyin ki o le mã rìn ni yiyẹ Ọlọrun, ẹniti o npè nyin sinu ijọba ati ogo On tikararẹ.
13Nitori eyi li awa ṣe ndupẹ lọwọ Ọlọrun pẹlu li aisimi, pe nigbati ẹnyin gba ọ̀rọ ti ẹnyin gbọ lọdọ wa, ani ọ̀rọ Ọlọrun, ẹnyin kò gbà a bi ẹnipe ọ̀rọ enia, ṣugbọn gẹgẹ bi o ti jẹ nitõtọ, bi ọ̀rọ Ọlọrun, eyiti o ṣiṣẹ gidigidi ninu ẹnyin ti o gbagbọ́ pẹlu.
14Nitori, ará, ẹnyin di alafarawe awọn ijọ Ọlọrun ti mbẹ ni Judea, ninu Kristi Jesu: nitoripe ẹnyin pẹlu jìya iru ohun kanna lọwọ awọn ara ilu nyin, gẹgẹ bi awọn pẹlu ti jìya lọwọ awọn Ju:
15Awọn ẹniti o pa Jesu Oluwa, ati awọn woli, nwọn si tì wa jade; nwọn kò si ṣe eyiti o wu Ọlọrun, nwọn si wà lodi si gbogbo enia:
16Nwọn kọ̀ fun wa lati sọ̀rọ fun awọn Keferi ki nwọn ki o le là, lati mã sọ ẹ̀ṣẹ wọn di kikun nigbagbogbo: ṣugbọn ibinu de bá wọn titi de opin.
17Ṣugbọn, ará, awa ti a gbà kuro lọdọ nyin fun sã kan li ara, ki iṣe li ọkàn, pẹlu itara ọpọlọpọ li awa ṣe aniyan ti a si fẹ gidigidi lati ri oju nyin.
18Nitori awa fẹ lati tọ̀ nyin wá, ani emi Paulu lẹ̃kini ati lẹ̃keji; Satani si dè wa li ọ̀na.
19Nitori kini ireti wa, tabi ayọ̀ wa, tabi ade iṣogo wa? kì ha iṣe ẹnyin ni niwaju Jesu Oluwa wa ni àbọ rẹ̀?
20Nitori ẹnyin ni ogo ati ayọ̀ wa.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
I. Tes 2: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: