II. A. Ọba 6
6
Irin Àáké Léfòó
1AWỌN ọmọ awọn woli wi fun Eliṣa pe, Sa wò o na, ibiti awa gbe njoko niwaju rẹ, o há jù fun wa.
2Jẹ ki awa ki o lọ, awa bẹ̀ ọ, si Jordani, ki olukulùku wa ki o mu iti igi kọ̃kan wá, si jẹ ki awa ki o ṣe ibikan, ti awa o ma gbe. On si dahùn wipe, Ẹ mã lọ.
3Ẹnikan si wipe, Ki o wu ọ, emi bẹ̀ ọ, lati ba awọn iranṣẹ rẹ lọ. On si dahùn pe, Emi o lọ.
4Bẹ̃li o ba wọn lọ. Nigbati nwọn si de Jordani, nwọn ké igi.
5O si ṣe, bi ẹnikan ti nké iti-igi, ãke yọ sinu omi: o si kigbe, o si wipe, Yẽ! oluwa mi, a tọrọ rẹ̀ ni.
6Enia Ọlọrun si wipe, Nibo li o bọ́ si? O si fi ibẹ hàn a. On si ké igi kan, o si sọ́ ọ sinu rẹ̀; irin na si fó soke.
7Nitorina o wipe, Mu u. On si nà ọwọ rẹ̀, o si mu u.
Israẹli Ṣẹgun Siria
8Nigbana ni ọba Siria mba Israeli jagun, o si ba awọn iranṣẹ rẹ̀ gbèro wipe, Ni ibi bayibayi ni ibùba mi yio gbe wà.
9Enia Ọlọrun si ranṣẹ si ọba Israeli wipe Kiye sara, ki iwọ ki o máṣe kọja si ibi bayi; nitori nibẹ ni awọn ara Siria ba si.
10Ọba Israeli si ranṣẹ si ibẹ na ti enia Ọlọrun ti sọ fun u, ti o si ti kilọ fun u, o si gbà ara rẹ̀ nibẹ, kì iṣe nigbà kan tabi nigba meji.
11Nitorina li ọkàn ọba Siria bajẹ gidigidi nitori nkan yi: o si pè awọn iranṣẹ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin kì yio ha fihan mi, tani ninu wa ti o nṣe ti ọba Israeli?
12Ọkan ninu awọn iranṣẹ rẹ̀ si wipe, Kò si ẹnikan, oluwa mi, ọba; bikoṣe Eliṣa, woli ti mbẹ ni Israeli, ni nsọ fun ọba Israeli gbogbo ọ̀rọ ti iwọ nsọ ninu iyẹ̀wu rẹ.
13On si wipe, Ẹ lọ iwò ibi ti on gbe wà, ki emi o le ranṣẹ lọ mu u wá. A si sọ fun u, wipe, Wò o, o wà ni Dotani.
14Nitorina li o ṣe rán awọn ẹṣin ati kẹkẹ́ ati ogun nla sibẹ: nwọn si de li oru, nwọn si yi ilu na ka.
15Nigbati iranṣẹ enia Ọlọrun na si dide ni kùtukutu ti o si jade lọ, wõ, ogun yi ilu na ka, ati ẹṣin ati kẹkẹ́. Iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Yẽ! baba mi, awa o ti ṣe?
16On si dahùn wipe, Má bẹ̀ru: nitori awọn ti o wà pẹlu wa, jù awọn ti o wà pẹlu wọn lọ.
17Eliṣa si gbadura, o si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, là a li oju, ki o lè riran. Oluwa si là oju ọdọmọkunrin na; on si riran: si wò o, òke na kún fun ẹṣin ati kẹkẹ́-iná yi Eliṣa ka.
18Nigbati nwọn si sọ̀kalẹ tọ̀ ọ wá, Eliṣa gbadura si Oluwa, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, bù ifọju lù awọn enia yi. On si bù ifọju lù wọn gẹgẹ bi ọ̀rọ Eliṣa.
19Eliṣa si wi fun wọn pe, Eyi kì iṣe ọ̀na, bẹ̃ni eyi kì iṣe ilu na: ẹ ma tọ̀ mi lẹhin, emi o si mu nyin wá ọdọ ọkunrin ti ẹnyin nwá. O si ṣe amọ̀na wọn lọ si Samaria.
20O si ṣe, nigbati nwọn de Samaria ni Eliṣa wipe, Oluwa la oju awọn enia wọnyi, ki nwọn ki o lè riran. Oluwa si là oju wọn; nwọn si riran; si kiyesi i, nwọn mbẹ li ãrin Samaria.
21Ọba Israeli si wi fun Eliṣa, nigbati o ri wọn pe, Baba mi, ki emi ki o mã pa wọn bi? ki emi ki o mã pa wọn bi?
22On si dahùn pe, Iwọ kò gbọdọ pa wọn: iwọ jẹ pa awọn ti iwọ fi idà rẹ ati ọrun rẹ kó ni igbèkun? Gbe onjẹ ati omi kalẹ niwaju wọn, ki nwọn ki o jẹ, ki nwọn ki o si mu, ki nwọn ki o si tọ̀ oluwa wọn lọ.
23On si pèse ọ̀pọlọpọ onjẹ fun wọn; nigbati nwọn si ti jẹ, ti nwọn si ti mu tan, o rán wọn lọ, nwọn si tọ̀ oluwa wọn lọ. Bẹ̃ni ẹgbẹ́ ogun Siria kò tun wá si ilẹ Israeli mọ.
Ogun Dóti Samaria
24O si ṣe lẹhìn eyi, ni Benhadadi ọba Siria ko gbogbo ogun rẹ̀ jọ, nwọn si gòke, nwọn si dó tì Samaria.
25Iyàn nla kan si mu ni Samaria: si kiyesi i, nwọn dó tì i, tobẹ̃ ti a si fi ntà ori kẹtẹkẹtẹ kan ni ọgọrun iwọ̀n fadakà, ati idamẹrin oṣuwọn kabu imi ẹiyẹle, ni iwọ̀n fàdakà marun.
26O si ṣe ti ọba Israeli nkọja lọ lori odi, obinrin kan sọkún tọ̀ ọ wá wipe, Gbà mi, oluwa mi, ọba!
27On si wipe, Bi Oluwa kò ba gbà ọ, nibo li emi o gbe ti gbà ọ? Lati inu ilẹ-ipakà, tabi lati inu ibi ifunti?
28Ọba si wi fun u pe, Ẽṣe ọ? On si dahùn wipe, Obinrin yi wi fun mi pe, Mu ọmọkunrin rẹ wá, ki awa ki o le jẹ ẹ loni, awa o si jẹ ọmọ ti emi li ọla.
29Bẹ̃ni awa sè ọmọ mi, awa si jẹ ẹ́: emi si wi fun u ni ijọ keji pe, Mu ọmọ rẹ wá ki awa ki o jẹ́ ẹ; on si ti fi ọmọ rẹ̀ pamọ́.
30O si ṣe, nigbati ọba gbọ́ ọ̀rọ obinrin na, o fà aṣọ rẹ̀ ya; o si kọja lọ lori odi, awọn enia si wò, si kiyesi i, o ni aṣọ-ọfọ̀ labẹ aṣọ rẹ̀ li ara rẹ̀.
31Nigbana ni o wipe, Ki Ọlọrun ki o ṣe bayi ati jù bẹ̃ lọ si mi, bi ori Eliṣa ọmọ Ṣafati yio duro li ọrùn rẹ̀ li oni.
32Ṣugbọn Eliṣa joko ninu ile rẹ̀, ati awọn àgbagba joko pẹlu rẹ̀; ọba si rán ọkunrin kan ṣãju rẹ̀ lọ: ṣugbọn ki iranṣẹ na ki o to dé ọdọ rẹ̀, on wi fun awọn àgbagba pe, Ẹ wò bi ọmọ apania yi ti ranṣẹ lati mu ori mi kuro? ẹ wò, nigbati iranṣẹ na ba de, ẹ tì ilẹ̀kun, ki ẹ si dì i mu ṣinṣin li ẹnu-ọ̀na: iro-ẹsẹ̀ oluwa rẹ̀ kò ha wà lẹhin rẹ̀?
33Bi on ti mba wọn sọ̀rọ lọwọ, kiyesi i, iranṣẹ na sọ̀kalẹ tọ̀ ọ wá: on si wipe, Wò o, lati ọwọ Oluwa ni ibi yi ti wá, kili emi o ha duro dè Oluwa mọ si?
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. A. Ọba 6: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: