II. Sam 10
10
Dafidi Ṣẹgun Àwọn Ará Amoni ati Àwọn Ará Siria
(I. Kro 19:1-19)
1O si ṣe lẹhin eyi, ọba awọn ọmọ Ammoni si kú, Hanuni ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
2Dafidi si wipe, Emi o ṣe ore fun Hanuni ọmọ Nahaṣi gẹgẹ bi baba rẹ̀ si ti ṣe ore fun mi. Dafidi si ranṣẹ lati tù u ninu lati ọwọ́ awọn iranṣẹ rẹ̀ wá, nitori ti baba rẹ̀. Awọn iranṣẹ Dafidi si wá si ilẹ awọn ọmọ Ammoni.
3Awọn olori awọn ọmọ Ammoni si wi fun Hanuni oluwa wọn pe, Li oju rẹ, ọlá ni Dafidi mbù fun baba rẹ, ti o fi ran awọn olutùnú si ọ? ko ha se pe, Dafidi ran awọn iranṣẹ rẹ̀ si ọ, lati wa wò ilu, ati lati ṣe alami rẹ̀, ati lati bà a jẹ?
4Hanuni si mu awọn iranṣẹ Dafidi, o fá apakan irungbọ̀n wọn, o si ke abọ̀ kuro ni agbáda wọn, titi o fi de idi wọn, o si rán wọn lọ.
5Nwọn si sọ fun Dafidi, o si ranṣẹ lọ ipade wọn, nitoriti oju tì awọn ọkunrin na pupọ̀: ọba si wipe. Ẹ duro ni Jeriko titi irungbọ̀n nyin yio fi hù, nigbana ni ki ẹ padà bọ̀.
6Awọn ọmọ Ammoni si ri pe, nwọn di ẹni irira niwaju Dafidi, awọn ọmọ Ammoni si ranṣẹ, nwọn si fi owo bẹ̀ ogun awọn ara Siria ti Betrehobu; ati Siria ti Soba, ẹgbãwa ẹlẹsẹ ati ti ọba Maaka, ẹgbẹrun ọkunrin, ati ti Iṣtobu ẹgbãfa ọkunrin.
7Dafidi si gbọ́, o si rán Joabu, ati gbogbo ogun awọn ọkunrin alagbara.
8Awọn ọmọ Ammoni si jade, nwọn si tẹ́ ogun li ẹnu odi; ara Siria ti Soba, ati ti Rehobu, ati Iṣtobu, ati Maaka, nwọn si tẹ́ ogun ni papa fun ara wọn.
9Nigbati Joabu si ri i pe ogun na doju kọ on niwaju ati lẹhin, o si yàn ninu gbogbo awọn akikanju ọkunrin ni Israeli, o si tẹ́ ogun kọju si awọn ara Siria.
10O si fi awọn enia ti o kù le Abiṣai aburo rẹ̀ lọwọ, ki o le tẹ́ ogun kọju si awọn ọmọ Ammoni.
11O si wipe, Bi agbara awọn ara Siria ba si pọ̀ jù emi lọ, iwọ o si wá ràn mi lọwọ: ṣugbọn bi ọwọ́ awọn ọmọ Ammoni ba si pọ̀ jù ọ lọ, emi o si wá ràn ọ lọwọ.
12Mu ọkàn le, jẹ ki a ṣe onigboya nitori awọn enia wa, ati nitori awọn ilu Ọlọrun wa; Oluwa o si ṣe eyi ti o dara li oju rẹ̀.
13Joabu ati awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ si ba awọn ara Siria pade ijà: nwọn si sa niwaju rẹ̀.
14Nigbati awọn ọmọ Ammoni si ri pe awọn ara Siria sá, awọn si sá niwaju Abiṣai, nwọn si wọ inu ilu lọ. Joabu si pada kuro lẹhin awọn ọmọ Ammoni, o si pada wá si Jerusalemu.
15Nigbati awọn ara Siria si ri pe nwọn di bibì ṣubu niwaju Israeli, nwọn si ko ara wọn jọ.
16Hadareseri si ranṣẹ, o si mu awọn ara Siria ti o wà li oke odo jade wá: nwọn si wá si Helami; Ṣobaki olori ogun ti Hadareseri si ṣolori wọn.
17Nigbati a sọ fun Dafidi, o si ko gbogbo Israeli jọ, nwọn si kọja Jordani, nwọn si wá si Helami. Awọn ara Siria si tẹ́ ogun kọju si Dafidi, nwọn si ba a jà.
18Awọn ara Siria si sa niwaju Israeli; Dafidi si pa ninu awọn ara Siria ẽdẹgbẹrin awọn onikẹkẹ́, ati ọkẹ meji ẹlẹṣin, nwọn si kọlu Ṣobaki olori ogun wọn, o si kú nibẹ.
19Nigbati gbogbo awọn ọba ti o wà labẹ Hadareseri si ri pe nwọn di bibì ṣubu niwaju Israeli, nwọn si ba Israeli lajà, nwọn si nsìn wọn. Awọn ara Siria si bẹ̀ru lati ràn awọn ọmọ Ammoni lọwọ mọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Sam 10: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: