Iṣe Apo 11
11
Peteru Ròhìn fún Ìjọ ní Jerusalẹmu
1AWỌN aposteli ati awọn arakunrin ti o wà ni Judea si gbọ́ pe awọn Keferi pẹlu ti gba ọ̀rọ Ọlọrun.
2Nigbati Peteru si gòke wá si Jerusalemu, awọn ti ikọla mba a sọ,
3Wipe, Iwọ wọle tọ̀ awọn enia alaikọlà lọ, o si ba wọn jẹun.
4Ṣugbọn Peteru bẹ̀rẹ si ilà a fun wọn lẹsẹsẹ, wipe,
5Emi wà ni ilu Joppa, mo ngbadura: mo ri iran kan li ojuran, Ohun elo kan sọkalẹ bi gọgọwu nla, ti a ti igun mẹrẹrin sọ̀ ka ilẹ lati ọrun wá; o si wá titi de ọdọ mi:
6Mo tẹjumọ ọ, mo si fiyesi i, mo si ri ẹran ẹlẹsẹ mẹrin aiye, ati ẹranko igbẹ́, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju ọrun.
7Mo si gbọ́ ohùn kan ti o fọ̀ si mi pe, Dide, Peteru; mã pa, ki o si mã jẹ.
8Ṣugbọn mo dahùn wipe, Agbẹdọ, Oluwa: nitori ohun èwọ tabi alaimọ́ kan kò wọ̀ ẹnu mi ri lai.
9Ṣugbọn ohùn kan dahun lẹ̃keji lati ọrun wá pe, Ohun ti Ọlọrun ba ti wẹ̀nu, iwọ máṣe pè e li èwọ.
10Eyi si ṣe li ẹrinmẹta: a sì tun fà gbogbo rẹ̀ soke ọrun.
11Si wo o, lojukanna ọkunrin mẹta duro niwaju ile ti a gbé wà, ti a rán lati Kesarea si mi.
12Ẹmí si wi fun mi pe, ki emi ki o ba wọn lọ, ki emi máṣe kọminu ohunkohun. Awọn arakunrin mẹfa wọnyi si ba mi lọ, a si wọ̀ ile ọkunrin na:
13O si sọ fun wa bi on ti ri angẹli kan ti o duro ni ile rẹ̀, ti o si wipe, Ranṣẹ lọ si Joppa, ki o si pè Simoni ti apele rẹ̀ jẹ Peteru;
14Ẹniti yio sọ ọ̀rọ fun ọ, nipa eyiti a o fi gbà iwọ ati gbogbo ile rẹ là.
15Bi mo si ti bẹ̀rẹ si isọ, Ẹmí Mimọ́ si bà le wọn, gẹgẹ bi o ti bà le wa li àtetekọṣe.
16Nigbana ni mo ranti ọ̀rọ Oluwa, bi o ti wipe, Johanu fi omi baptisi nitõtọ; ṣugbọn a o fi Ẹmí Mimọ́ baptisi nyin.
17Njẹ bi Ọlọrun si ti fi iru ẹ̀bun kanna fun wọn ti o ti fifun awa pẹlu nigbati a gbà Jesu Kristi Oluwa gbọ́, tali emi ti emi ó fi le dè Ọlọrun li ọ̀na?
18Nigbati nwọn si gbọ́ nkan wọnyi, nwọn si pa ẹnu wọn mọ́, nwọn si yìn Ọlọrun logo wipe, Njẹ Ọlọrun fi ironupiwada si ìye fun awọn Keferi pẹlu.
Ìjọ ní Antioku
19Nitorina awọn ti a si tuka kiri niti inunibini ti o ṣẹ̀ niti Stefanu, nwọn rìn titi de Fenike, ati Kipru, ati Antioku, nwọn kò sọ ọ̀rọ na fun ẹnikan, bikoṣe fun kìki awọn Ju.
20Ṣugbọn awọn kan mbẹ ninu wọn ti iṣe ara Kipru, ati Kirene; nigbati nwọn de Antioku nwọn sọ̀rọ fun awọn Hellene pẹlu, nwọn nwasu Jesu Oluwa.
21Ọwọ́ Oluwa si wà pẹlu wọn: ọpọlọpọ awọn ti o gbagbọ́ yipada si Oluwa.
22Ihìn wọn si de etí ijọ ti o wà ni Jerusalemu: nwọn si rán Barnaba lọ titi de Antioku;
23Ẹniti, nigbati o de ti o si ri õre-ọfẹ Ọlọrun, o yọ̀, o si gba gbogbo wọn niyanju pe, pẹlu ipinnu ọkàn ni ki nwọn ki o fi ara mọ́ Oluwa.
24Nitori on jẹ enia rere, o si kún fun Ẹmí Mimọ́, ati fun igbagbọ́: enia pipọ li a si kà kún Oluwa.
25Barnaba si jade lọ si Tarsu lati wá Saulu.
26Nigbati o si ri i, o mu u wá si Antioku. O si ṣe, fun ọdun kan gbako ni nwọn fi mba ijọ pejọ pọ̀, ti nwọn si kọ́ enia pipọ. Ni Antioku li a si kọ́ pè awọn ọmọ-ẹhin ni Kristian.
27Li ọjọ wọnni li awọn woli si ti Jerusalemu sọkalẹ wá si Antioku.
28Nigbati ọkan ninu wọn, ti a npè ni Agabu si dide, o tipa Ẹmi sọ pe, ìyan nla yio mu ká gbogbo aiye: eyiti o si ṣẹ li ọjọ Klaudiu Kesari.
29Awọn ọmọ-ẹhin si pinnu, olukuluku gẹgẹ bi agbara rẹ̀ ti to, lati rán iranlọwọ si awọn arakunrin ti o wà ni Judea:
30Eyiti nwọn si ṣe, nwọn si fi i ranṣẹ si awọn àgba lati ọwọ́ Barnaba on Saulu.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Iṣe Apo 11: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: