NIGBATI ọjọ Pentekosti si de, gbogbo nwọn fi ọkàn kan wà nibikan. Lojijì iró si ti ọrun wá, gẹgẹ bi iró ẹ̀fũfu lile, o si kún gbogbo ile nibiti nwọn gbé joko. Ẹla ahọn bi ti iná si yọ si wọn, o pin ara rẹ̀ o si bà le olukuluku wọn. Gbogbo nwọn si kún fun Ẹmí Mimọ́, nwọn si bẹ̀rẹ si ifi ède miran sọrọ, gẹgẹ bi Ẹmí ti fun wọn li ohùn. Awọn Ju olufọkànsin lati orilẹ-ede gbogbo labẹ ọrun si ngbe Jerusalemu. Nigbati nwọn si gbọ iró yi, ọ̀pọlọpọ enia pejọ, nwọn si damu, nitoriti olukuluku gbọ́ nwọn nsọ̀rọ li ède rẹ̀. Hà si ṣe gbogbo wọn, ẹnu si yà wọn, nwọn nwi fun ara wọn pe, Wo o, ara Galili ki gbogbo awọn ti nsọ̀rọ wọnyi iṣe?
Kà Iṣe Apo 2
Feti si Iṣe Apo 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 2:1-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò