Iṣe Apo 21
21
Ìrìn Àjò Paulu sí Jerusalẹmu
1O si ṣe, nigbati awa kuro lọdọ wọn, ti a sì ṣikọ̀, awa ba ọ̀na tàra wá si Kosi, ni ijọ keji a si lọ si Rodu, ati lati ibẹ̀ lọ si Patara:
2Nigbati awa si ri ọkọ̀ kan ti nrekọja lọ si Fenike, awa wọ̀ ọkọ̀, a si ṣí.
3Nigbati awa si ti ri Kipru li òkere, ti awa fi i si ọwọ́ òsi, awa gbé ori ọkọ̀ le Siria, a si gúnlẹ ni Tire: nitori nibẹ̀ li ọkọ̀ yio gbé kó ẹrù silẹ.
4Nigbati a si ri awọn ọmọ-ẹhin, awa duro nibẹ̀ ni ijọ meje: awọn ẹniti o tipa Ẹmí wi fun Paulu pe, ki o máṣe lọ si Jerusalemu.
5Nigbati a si ti lò ọjọ wọnni tan, awa jade, a si mu ọ̀na wa pọ̀n; gbogbo nwọn si sìn wa, pẹlu awọn obinrin ati awọn ọmọde titi awa fi jade si ẹhin ilu: nigbati awa si gunlẹ li ebute, awa si gbadura.
6Nigbati a si ti dágbere fun ara wa, awa bọ́ si ọkọ̀; ṣugbọn awọn si pada lọ si ile wọn.
7Nigbati a si ti pari àjo wa lati Tire, awa de Ptolemai; nigbati a si kí awọn ará, awa si ba wọn gbé ni ijọ kan.
8Ni ijọ keji awa lọ kuro, a si wá si Kesarea: nigbati awa si wọ̀ ile Filippi Efangelisti, ọkan ninu awọn meje nì; awa si wọ̀ sọdọ rẹ̀.
9Ọkunrin yi si li ọmọbinrin mẹrin, wundia, ti ima sọtẹlẹ.
10Bi a si ti wà nibẹ̀ li ọjọ pipọ, woli kan ti Judea sọkalẹ wá, ti a npè ni Agabu.
11Nigbati o si de ọdọ wa, o mu amure Paulu, o si de ara rẹ̀ li ọwọ́ on ẹsẹ, o si wipe, Bayi li Ẹmí Mimọ́ wi, Bayi li awọn Ju ti o wà ni Jerusalemu yio de ọkunrin ti o ni amure yi, nwọn o si fi i le awọn Keferi lọwọ.
12Nigbati a si ti gbọ́ nkan wọnyi, ati awa, ati awọn ará ibẹ̀ na bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣe gòke lọ si Jerusalemu.
13Nigbana ni Paulu dahùn wipe, Ewo li ẹnyin nṣe yi, ti ẹnyin nsọkun, ti ẹ si nmu ãrẹ̀ ba ọkàn mi; nitori emi mura tan, kì iṣe fun didè nikan, ṣugbọn lati kú pẹlu ni Jerusalemu, nitori orukọ Jesu Oluwa.
14Nigbati a kò le pa a li ọkàn dà, awa dakẹ, wipe, Ifẹ ti Oluwa ni ki a ṣe.
15Lẹhin ijọ wọnni, awa palẹmọ, a si gòke lọ si Jerusalemu.
16Ninu awọn ọmọ-ẹhin lati Kesarea ba wa lọ, nwọn si mu Mnasoni ọmọ-ẹhin lailai kan pẹlu wọn, ará Kipru, lọdọ ẹniti awa ó gbé wọ̀.
Paulu Lọ Bẹ Jakọbu Wò
17Nigbati awa si de Jerusalemu, awọn arakunrin si fi ayọ̀ gbà wa.
18Ni ijọ keji awa ba Paulu lọ sọdọ Jakọbu; gbogbo awọn alàgba si wà nibẹ̀.
19Nigbati o si kí wọn tan, o ròhin ohun gbogbo lẹsẹsẹ ti Ọlọrun ṣe lãrin awọn Keferi nipa iṣẹ-iranṣẹ rẹ̀.
20Nigbati nwọn si gbọ́, nwọn yin Ọlọrun logo, nwọn si wi fun u pe, Arakunrin, iwọ ri iye ẹgbẹgbẹrun ninu awọn Ju ti o gbagbọ, gbogbo nwọn li o si ni itara fun ofin.
21Nwọn si ti ròhin rẹ fun wọn pe, Iwọ nkọ́ gbogbo awọn Ju ti o wà lãrin awọn Keferi pe, ki nwọn ki o kọ̀ Mose silẹ, o si nwi fun wọn pe ki nwọn ki o máṣe kọ awọn ọmọ wọn ni ilà mọ́, ati ki nwọn ki o máṣe rìn gẹgẹ bi àṣa wọn.
22Njẹ ewo ni ṣiṣe? ijọ kò le ṣaima pejọ pọ̀: dajudaju nwọn ó gbọ́ pe, iwọ de.
23Njẹ eyi ti awa ó wi fun ọ yi ni ki o ṣe: Awa li ọkunrin mẹrin ti nwọn ni ẹ̀jẹ́ lara wọn;
24Awọn ni ki iwọ ki o mu, ki o si ṣe iwẹnumọ pẹlu wọn ki o si ṣe inawo wọn, ki nwọn ki o le fá ori wọn: gbogbo enia yio si mọ̀ pe, kò si otitọ kan ninu ohun ti nwọn gbọ si ọ; ṣugbọn pe, iwọ tikararẹ nrìn dede pẹlu, iwọ si npa ofin mọ́.
25Ṣugbọn niti awọn Keferi ti o gbagbọ́, awa ti kọwe, a si ti pinnu rẹ̀ pe, ki nwọn pa ara wọn mọ kuro ninu ohun ti a fi rubọ si oriṣa, ati ẹ̀jẹ ati ohun ilọlọrùnpa, ati àgbere.
26Nigbana ni Paulu mu awọn ọkunrin na; ni ijọ keji o ṣe iwẹnumọ pẹlu wọn, o si wọ̀ inu tẹmpili lọ, o sọ ìgba ti ọjọ ìwẹ̀numọ́ na yio pé titi a fi rubọ fun olukuluku wọn.
Wọ́n Mú Paulu ninu Tẹmpili
27Nigbati ọjọ meje si fẹrẹ pé, ti awọn Ju ti o ti Asia wa ri i ni tẹmpili, nwọn rú gbogbo awọn enia soke, nwọn nawọ́ mu u.
28Nwọn nkigbe wipe, Ẹnyin enia Israeli, ẹ gbà wa: Eyi li ọkunrin na, ti nkọ́ gbogbo enia nibigbogbo lòdi si awọn enia, ati si ofin, ati si ibi yi: ati pẹlu o si mu awọn ara Hellene wá si tẹmpili, o si ti ba ibi mimọ́ yi jẹ.
29Nitori nwọn ti ri Trofimu ará Efesu pẹlu rẹ̀ ni ilu, ẹniti nwọn ṣebi Paulu mu wá sinu tẹmpili.
30Gbogbo ilu si rọ́, awọn enia si sure jọ: nwọn si mu Paulu, nwọn si wọ́ ọ jade kuro ninu tẹmpili: lojukanna a si tì ilẹkun.
31Bi nwọn si ti nwá ọ̀na ati pa a, ìhin de ọdọ olori ẹgbẹ ọmọ-ogun pe, gbogbo Jerusalemu dàrú.
32Lojukanna o si ti mu awọn ọmọ-ogun ati awọn balogun ọrún, o si sure sọkalẹ tọ̀ wọn lọ: nigbati nwọn si ri olori ogun ati awọn ọmọ-ogun, nwọn dẹkun lilu Paulu.
33Nigbana li olori ogun sunmọ wọn, o si mu u, o paṣẹ pe ki a fi ẹ̀wọn meji dè e; o si bère ẹniti iṣe, ati ohun ti o ṣe.
34Awọn kan nkígbe ohun kan, awọn miran nkigbe ohun miran ninu awujọ: nigbati kò si le mọ̀ eredi irukerudò na dajudaju, o paṣẹ ki nwọn ki o mu u lọ sinu ile-olodi.
35Nigbati o si de ori atẹgùn, gbigbé li a gbé e soke lọwọ awọn ọmọ-ogun nitori iwa-ipa awọn enia.
36Nitori ọ̀pọ enia gbátì i, nwọn nkigbe pe, Mu u kuro.
Paulu Rojọ́
37Bi nwọn si ti fẹrẹ imu Paulu wọ̀ inu ile-olodi lọ, o wi fun olori-ogun pe, Emi ha gbọdọ ba ọ sọ̀rọ? O si dahùn wipe, Iwọ mọ̀ ède Hellene ifọ̀?
38Iwọ ha kọ́ ni ara Egipti nì, ti o ṣọ̀tẹ ṣaju ọjọ wọnyi, ti o si ti mu ẹgbaji ọkunrin ninu awọn ti iṣe apania lẹhin lọ si iju?
39Ṣugbọn Paulu si wipe, Ju li emi iṣe, ara Tarsu ilu Kilikia, ọlọ̀tọ ilu ti kì iṣe ilu lasan kan, emi si bẹ ọ, bùn mi lãye lati ba awọn enia sọrọ.
40Nigbati o si ti bùn u lãye, Paulu duro lori atẹgùn, o si juwọ́ si awọn enia. Nigbati nwọn si dakẹrọrọ o ba wọn sọrọ li ède Heberu, wipe,
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Iṣe Apo 21: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: