Iṣe Apo 8:29-31

Iṣe Apo 8:29-31 YBCV

Ẹmí si wi fun Filippi pe, Lọ ki o si da ara rẹ pọ̀ mọ́ kẹkẹ́ yi. Filippi si sure lọ, o gbọ́, o nkà iwe woli Isaiah, o si bi i pe, Ohun ti iwọ nkà nì, o yé ọ? O si dahùn wipe, Yio ha ṣe yé mi, bikoṣepe ẹnikan tọ́ mi si ọna? O si bẹ̀ Filippi ki o gòke wá, ki o si ba on joko.