Iṣe Apo Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Àfikún ati ìgbésẹ̀ siwaju àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kọ sinu Ìyhin Rere Luku ni Ìṣe Àwọn Aposteli jẹ́. Kókó ète ìwé náà ni láti sọ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe darí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu láti tan Ìròyìn Ayọ̀ náà káàkiri ní Jerusalẹmu ati ní Judia, títí dé òpin ayé (1:8). Ìtàn ìdìde ati ìdàgbàsókè igbagbọ ni, bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ láàrin àwọn Juu títí ó fi di igbagbọ gbogbo àgbáyé. Ọ̀kan ninu àwọn ohun tí ó jẹ ẹni tí ó kọ ìwé yìí lógún ni láti mú kí ó dá àwọn òǹkàwé rẹ̀ lójú pé àwọn onigbagbọ kì í ṣe òṣèlú onírúkèrúdò tí yóo dojú ìjọba Romu délẹ̀, àtipé igbagbọ ni ìmúṣẹ ìsìn àwọn Juu.
A lè pín ìwé Ìṣe Àwọn Aposteli sí ọ̀nà mẹta tí ó ń fi hàn bí àwọn ibi tí a ti ń waasu Ìròyìn Ayọ̀ nípa Jesu ti ń gbòòrò sí i, ati bí a ti ṣe fi ìdí ìjọ Ọlọrun múlẹ̀: (1) Ìbẹ̀rẹ̀ ìdàgbàsókè ati ìtànkálẹ̀ igbagbọ ní Jerusalẹmu lẹ́yìn ìgòkè-re-ọ̀run Jesu; (2) bí igbagbọ ṣe tàn káàkiri àwọn agbègbè mìíràn ní Palẹstini (3) ati bí ó ṣe tún tàn káàkiri àwọn agbègbè tí ó yí òkun Mẹditarenia ká, títí ó fi dé Romu.
Nǹkankan pataki tíí máa ń jẹ jáde lemọ́lemọ́ ninu Ìṣe Àwọn Aposteli ni iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́, tí ó fi tagbára-tagbára sọ̀kalẹ̀, tí ó sì bà lé àwọn onigbagbọ lórí ní Jerusalẹmu ní ọjọ́ Pẹntikọsti. Ẹ̀mí Mímọ́ yìí ní ń darí ìjọ ati àwọn adarí ìjọ, tí ó sì ń fún wọn ní agbára ninu gbogbo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a sọ nípa rẹ̀ ninu ìwé yìí. A ṣe àkójọ iṣẹ́ tí àwọn onigbagbọ àkọ́kọ́ níláti jẹ́ ní ṣókí ninu àwọn iwaasu bíi mélòó kan. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kọ sinu ìwé Ìṣe Àwọn Aposteli fi agbára iṣẹ́ tí wọn ń jẹ́ yìí hàn ninu ìgbé-ayé àwọn onigbagbọ ati ìrẹ́pọ̀ àwọn ọmọ ìjọ.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ìpalẹ̀mọ́ fún ìjẹ́rìí 1:1-26
a. Àṣẹ ìkẹyìn tí Jesu pa ati ìlérí tí ó ṣe 1:1-14
b. Ẹni tí ó gba ipò Judasi 1:15-26
Ìjẹ́rìí ní Jerusalẹmu 2:1—8:3
Ìjẹ́rìí ní Judia ati ní Samaria 8:4—12:25
Iṣẹ́ Paulu 13:1—28:31
a. Ìrìn àjò ìjíyìn rere kinni 13:1—14:28
b. Àjọ tí wọ́n ṣe ní Jerusalẹmu 15:1-35
d. Ìrìn àjò ìjíyìn rere keji 15:36—18:22
e. Ìrìn àjò ìjíyìn rere kẹta 18:23—21:16
ẹ. Paulu ṣe ẹ̀wọ̀n ní Jerusalẹmu, Kesaria ati Romu 21:17—28:31

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Iṣe Apo Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀