Kol 2:13-14

Kol 2:13-14 YBCV

Ati ẹnyin, ẹniti o ti kú nitori ẹ̀ṣẹ nyin ati aikọla ara nyin, mo ni, ẹnyin li o si ti sọdi ãye pọ̀ pẹlu rẹ̀, o si ti dari gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin; O si ti pa iwe majẹmu nì rẹ́, ti o lodi si wa, ti a kọ ninu ofin, eyiti o lodi si wa: on li o si ti mu kuro loju ọ̀na, o si kàn a mọ agbelebu