Kol Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìjọ tí ó wà ní Kolose ni Paulu kọ ìwé tí ó kọ sí àwọn ará Kolose sí. Kolose jẹ́ ìlú kan ní Esia. Ó wà ní apá ìlà oòrùn Efesu. Kì í ṣe Paulu ni ó dá ìjọ yìí sílẹ̀, ṣugbọn Kolose wà ninu agbègbè tí Paulu kà kún iṣẹ́ rẹ̀ bí ó ti ń rán àwọn oníṣẹ́ jáde láti Efesu, tíí ṣe olú-ìlú ìpínlẹ̀ Esia, tí ó wà lábẹ́ ìjọba Romu. Wọ́n ti sọ fún Paulu pé àwọn olùkọ́ni èké wà ninu ìjọ ní Kolose. Àwọn olùkọ́ni èké wọnyi tẹnumọ́ ọn pé dandan ni kí eniyan máa bọ àwọn aláṣẹ ati àwọn alágbára ojú ọ̀run kí ó tó lè mọ Ọlọrun, kí ó sì ní ìgbàlà lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Àwọn olùkọ́ni èké wọnyi kò fi mọ bẹ́ẹ̀; wọ́n ní dandan ni pé kí eniyan pa àwọn ìlànà ìsìn bíi ilà kíkọ mọ. Bẹ́ẹ̀ náà ni òfin tí ó jẹ mọ́ oúnjẹ, ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Paulu kọ ìwé yìí láti lòdì sí irú àwọn ẹ̀kọ́ wọnyi. Ó ń kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ igbagbọ tòótọ́. Kókó ìdáhùn rẹ̀ ni pé Jesu Kristi nìkan tó láti fún eniyan ní ìgbàlà kíkún, ati pé irú igbagbọ ati ìṣẹ́ tí àwọn olùkọ́ni èké wọnyi ń kọ́ni ń mú kí eniyan jìnnà sí Kristi. Nípasẹ̀ Kristi ni Ọlọrun fi dá ayé, nípasẹ̀ rẹ̀ náà sì ni yóo fi mú ayé pada sọ́dọ̀ ara rẹ̀. Ninu ìṣọ̀kan pẹlu Kristi nìkan ni ìrètí ìgbàlà wà fún ayé. Paulu wá ṣe àlàyé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ lórí àyọrísí tí ẹ̀kọ́ ńlá yìí gbọdọ̀ ní ninu ìgbé-ayé onigbagbọ.
Nǹkan kan tí a tún gbọdọ̀ kíyèsí ninu ìwé yìí ni pé Tukikọsi tí ó bá Paulu mú ìwé yìí lọ sí Kolose mú Onisimu lẹ́yìn, ati pé nítorí ẹrú tí ń jẹ́ Onisimu yìí ni Paulu ṣe kọ Ìwé Filemoni.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-8
Ẹ̀dá ati iṣẹ́ Jesu 1:9—2:19
Ìgbé-ayé titun ninu Kristi 2:20—4:6
Ọ̀rọ̀ ìparí 4:7-18
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Kol Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: