Dan 11
11
1PẸLUPẸLU li ọdun kini Dariusi ara Media, emi pãpa duro lati mu u lọkàn le, ati lati fi idi rẹ̀ kalẹ.
2Njẹ nisisiyi li emi o fi otitọ hàn ọ, Kiyesi i, ọba mẹta pẹlu ni yio dide ni Persia; ẹkẹrin yio si ṣe ọlọrọ̀ jù gbogbo wọn lọ: ati nipa agbara rẹ̀ ni yio fi fi ọrọ̀ rú gbogbo wọn soke si ijọba Hellene.
Ìjọba Egypti ati ti Siria
3Ọba alagbara kan yio si dide, yio si fi agbara nla ṣe akoso, yio si ma ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀.
4Nigbati on ba dide tan, ijọba rẹ̀ yio fọ́, a o si pin i si orígun mẹrẹrin ọrun; kì si iṣe fun ọmọ rẹ̀, pẹlupẹlu kì si iṣe ninu agbara rẹ̀ ti on fi jọba, nitoriti a o fa ijọba rẹ̀ tu, ani fun ẹlomiran lẹhin awọn wọnyi.
5Ọba iha gusu yio si lagbara; ṣugbọn ọkan ninu awọn balogun rẹ̀, on o si lagbara jù u lọ, yio si jọba, ijọba rẹ̀ yio jẹ ijọba nla.
6Lẹhin ọdun pipọ nwọn o si kó ara wọn jọ pọ̀; ọmọbinrin ọba gusu yio wá sọdọ ọba ariwa, lati ba a dá majẹmu: ṣugbọn on kì yio le di agbara apá na mu; bẹ̃ni on kì yio le duro, tabi apá rẹ̀: ṣugbọn a o fi on silẹ, ati awọn ti o mu u wá, ati ẹni ti o bi i, ati ẹniti nmu u lọkàn le li akokò ti o kọja.
7Ṣugbọn ninu ẹka gbòngbo rẹ̀ li ẹnikan yio dide ni ipò rẹ̀, ẹniti yio wá pẹlu ogun, yio si wọ̀ ilu-olodi ọba ariwa, yio si ba wọn ṣe, yio si bori.
8On o si kó oriṣa wọn pẹlu ere didà wọn, ati ohunelo wọn daradara, ti fadaka, ati ti wura ni igbekun lọ si Egipti; on o si duro li ọdun melokan kuro lọdọ ọba ariwa.
9On o si lọ si ijọba ọba gusu, ṣugbọn yio yipada si ilẹ ontikararẹ̀.
10Ṣugbọn awọn ọmọ rẹ̀ yio ru soke, nwọn o si gbá ogun nla ọ̀pọlọpọ enia jọ; ẹnikan yio wọle wá, yio si bolẹ̀, yio si kọja lọ. Nigbana ni yio pada yio si gbé ogun lọ si ilu olodi rẹ̀.
11Ọba gusu yio si fi ibinu ru soke, yio si jade wá ba a jà, ani, ọba ariwa na: on o si kó enia pipọ jọ; ṣugbọn a o fi ọ̀pọlọpọ na le e lọwọ.
12Yio si kó ọ̀pọlọpọ na lọ, ọkàn rẹ̀ yio si gbé soke; on o si bì ọ̀pọlọpọ ẹgbãrun enia ṣubu; ṣugbọn a kì yio fi ẹsẹ rẹ̀ mulẹ nipa eyi.
13Nitoripe ọba ariwa yio si yipada, yio si kó ọ̀pọlọpọ enia jọ ti yio pọ̀ jù ti iṣaju lọ, yio si wá lẹhin ọdun melokan pẹlu ogun nla, ati ọ̀pọlọpọ ọrọ̀.
14Li akoko wọnni li ọ̀pọlọpọ yio si dide si ọba gusu; awọn ọlọ̀tẹ ninu awọn enia rẹ̀ yio si gbé ara wọn ga lati fi ẹsẹ iran na mulẹ pẹlu: ṣugbọn nwọn o ṣubu.
15Bẹ̃li ọba ariwa yio si wá, yio si mọdi, yio si gbà ilu olodi; apá ogun ọba gusu kì yio le duro, ati awọn ayanfẹ enia rẹ̀, bẹ̃ni kì yio si agbara lati da a duro.
16Ṣugbọn ẹniti o tọ̀ ọ wá yio mã ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu ara rẹ̀, kì yio si si ẹniti yio duro niwaju rẹ̀; on o si duro ni ilẹ daradara nì, ti yio si fi ọwọ rẹ̀ parun.
17On o si gbé oju rẹ̀ soke lati wọ̀ ọ nipa agbara gbogbo ijọba rẹ̀, yio si ba a dá majẹmu, bẹ̃ni yio ṣe; on o si fi ọmọbinrin awọn obinrin fun u, lati bà a jẹ: ṣugbọn on kì yio duro, bẹ̃ni kì yio si ṣe tirẹ̀.
18Lẹhin eyi, yio kọ oju rẹ̀ si erekuṣu wọnni, yio si gbà ọ̀pọlọpọ: ṣugbọn balogun kan fun ara rẹ̀, yio fi opin si ẹ̀gan rẹ̀: ati nipò eyi, yio mu ẹ̀gan rẹ̀ pada wá sori ara rẹ̀.
19Nigbana ni yio si yi oju rẹ̀ pada si ilu olodi ontikararẹ̀: ṣugbọn yio kọsẹ, yio si ṣubu, a kì yio si ri i mọ.
20Nigbana ni ẹnikan yio dide ni ipò rẹ̀ ti yio mu agbowode kan rekọja ninu ogo ijọba (ilẹ Juda): ṣugbọn niwọn ijọ melokan li a o si pa a run, kì yio ṣe nipa ibinu tabi loju ogun.
Ọba Burúkú tí Ó Jẹ ní Siria
21Ni ipò rẹ̀ li enia lasan kan yio dide, ẹniti nwọn kì yio fi ọlá ọba fun: ṣugbọn yio wá lojiji, yio si fi arekereke gbà ijọba.
22Ogun ti mbò ni mọlẹ li a o fi bò wọn mọlẹ niwaju rẹ̀, a o si fọ ọ tũtu, ati pẹlu ọmọ-alade majẹmu kan.
23Ati lẹhin igbati a ba ti ba a ṣe ipinnu tan, yio fi ẹ̀tan ṣiṣẹ: yio si gòke lọ, yio si fi enia diẹ bori.
24Yio si wọ̀ gbogbo ibi igberiko ọlọra; yio si ṣe ohun ti awọn baba rẹ̀ kò ṣe ri, tabi awọn baba nla rẹ̀; yio si fọn ikogun, ìfa, ati ọ̀pọlọpọ ọrọ̀ ká si ãrin wọn: yio si gbèro tẹlẹ si ilu olodi, ani titi akokò kan.
25Yio si rú agbara ati igboya rẹ̀ soke si ọba gusu ti on ti ogun nla; a o si rú ọba gusu soke si ija pẹlu ogun nlanla ati alagbara pupọ; ṣugbọn on kì yio le duro: nitori nwọn o gba èro tẹlẹ si i.
26Awọn ẹniti o jẹ ninu adidùn rẹ̀ ni yio si pa a run, ogun rẹ̀ yio si tàn kalẹ; ọ̀pọlọpọ ni yio si ṣubu ni pipa.
27Ọkàn awọn ọba mejeji wọnyi ni yio wà lati ṣe buburu, nwọn o si mã sọ̀rọ eké lori tabili kan, ṣugbọn kì yio jẹ rere; nitoripe opin yio wà li akokò ti a pinnu.
28Nigbana ni yio pada lọ si ilẹ ontikararẹ̀ ti on ti ọrọ̀ pupọ: ọkàn rẹ̀ yio si lodi si majẹmu mimọ́ nì, yio ṣe e, yio si pada lọ si ilẹ ontikararẹ̀.
29Yio si pada wá li akokò ti a pinnu, yio si wá si iha gusu; ṣugbọn kì yio ri bi ti iṣaju, ni ikẹhin.
30Nitoripe ọkọ̀ awọn ara Kittimu yio tọ̀ ọ wá, nitorina ni yio ṣe dãmu, yio si yipada, yio si ni ibinu si majẹmu mimọ́ nì; bẹ̃ni yio ṣe; ani on o yipada, yio si tun ni idapọ pẹlu awọn ti o kọ̀ majẹmu mimọ́ na silẹ.
31Agbara ogun yio si duro li apa tirẹ̀, nwọn o si sọ ibi mimọ́, ani ilu olodi na di aimọ́, nwọn o si mu ẹbọ ojojumọ kuro, nwọn o si gbé irira isọdahoro nì kalẹ.
32Ati iru awọn ti nṣe buburu si majẹmu nì ni yio fi ọ̀rọ ipọnni mu ṣọ̀tẹ: ṣugbọn awọn enia ti o mọ̀ Ọlọrun yio mu ọkàn le, nwọn o si ma ṣe iṣẹ agbara.
33Awọn ti o moye ninu awọn enia yio ma kọ́ ọ̀pọlọpọ: ṣugbọn nwọn o ma ti ipa oju idà ṣubu, ati nipa iná, ati nipa igbekun, ati nipa ikogun nijọmelo kan.
34Njẹ nisisiyi, nigbati nwọn o ṣubu, a o fi iranlọwọ diẹ ràn wọn lọwọ: ṣugbọn ọ̀pọlọpọ ni yio fi ẹ̀tan fi ara mọ́ wọn.
35Awọn ẹlomiran ninu awọn ti o moye yio si ṣubu, lati dan wọn wò, ati lati wẹ̀ wọn mọ́, ati lati sọ wọn di funfun, ani titi fi di akokò opin: nitoripe yio wà li akokò ti a pinnu.
36Ọba na yio si ma ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀; on o si gbé ara rẹ̀ ga, yio si gbéra rẹ̀ ga jù gbogbo ọlọrun lọ, yio si ma sọ̀rọ ohun iyanu si Ọlọrun awọn ọlọrun, yio si ma ṣe rere titi a o fi pari ibinu: nitori a o mu eyi ti a ti pinnu rẹ̀ ṣẹ.
37Bẹ̃li on kì yio si kà Ọlọrun awọn baba rẹ̀ si, tabi ifẹ awọn obinrin, on kì yio si kà ọlọrun kan si: nitoriti yio gbé ara rẹ̀ ga jù ẹni gbogbo lọ.
38Ṣugbọn ni ipò rẹ̀, yio ma bu ọlá fun ọlọrun awọn ilu olodi, ani ọlọrun kan ti awọn baba rẹ̀ kò mọ̀ ri ni yio ma fi wura, ati fadaka, ati okuta iyebiye, ati ohun daradara bu ọlá fun.
39Bẹ̃ gẹgẹ ni yio ṣe ninu ilu olodi wọnni ti o lagbara julọ nipa iranlọwọ ọlọrun ajeji, ẹniti o jẹ́wọ rẹ̀ ni yio fi ogo fun, ti yio si mu ṣe alakoso ọ̀pọlọpọ, yio si pín ilẹ fun li ère.
40Li akokò opin, ọba gusu yio kàn a, ọba ariwa yio si fi kẹkẹ́, ati ẹlẹṣin, ati ọ̀pọlọpọ ọkọ̀, kọ lu u bi afẹyika-ìji: on o si wọ̀ ilẹ wọnni yio si bò wọn mọlẹ, yio si rekọja.
41Yio si wọ̀ ilẹ ologo nì pẹlu, ọ̀pọlọpọ li a o si bì ṣubu: ṣugbọn awọn wọnyi ni yio si bọ lọwọ rẹ̀, ani Edomu, ati Moabu, ati olori awọn ọmọ Ammoni.
42On o si nà ọwọ rẹ̀ jade si ilẹ wọnni pẹlu, ilẹ Egipti kì yio si là a.
43Ṣugbọn on o lagbara lori iṣura wura, ati ti fadaka, ati lori gbogbo ohun daradara ni ilẹ Egipti: ati awọn ara Libia, awọn ara Etiopia yio si wà lẹhin rẹ̀.
44Ṣugbọn ìhin lati ila-õrùn, ati lati iwọ-õrùn wá yio dãmu rẹ̀: nitorina ni yio ṣe fi ìbinu nla jade lọ lati ma parun, ati lati mu ọ̀pọlọpọ kuro patapata.
45On o si pagọ ãfin rẹ̀ lãrin omi kọju si òke mimọ́ ologo nì; ṣugbọn on o si de opin rẹ̀, kì yio si si ẹniti yio ràn a lọwọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Dan 11: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: