Dan 6

6
Daniẹli ninu Ihò Kinniun
1O ṣe didùn inu Dariusi lati fi ọgọfa arẹ bãlẹ sori ijọba na, ti yio wà lori gbogbo ijọba;
2Ati lori awọn wọnyi ni alakoso mẹta: Danieli si jẹ ọkan ninu wọn: ki awọn arẹ bãlẹ ki o le ma jiyin fun wọn, ki ọba ki o má ṣe ni ipalara.
3Danieli yi si bori gbogbo awọn alakoso ati arẹ bãlẹ wọnyi, nitoripe ẹmi titayọ wà lara rẹ̀: ọba si ngbiro lati fi i ṣe olori gbogbo ijọba.
4Nigbana ni awọn alakoso, ati awọn arẹ bãlẹ nwá ẹ̀sùn si Danieli lẹsẹ̀ nipa ọ̀rọ ijọba, ṣugbọn nwọn kò le ri ẹ̀sùn tabi ẹ̀ṣẹkẹṣẹ lọwọ rẹ̀; niwọn bi on ti jẹ olododo enia tobẹ̃ ti a kò si ri iṣina tabi ẹ̀ṣẹ kan lọwọ rẹ̀.
5Nigbana ni awọn ọkunrin wọnyi wipe, Awa kì yio le ri ẹ̀sùn kan si Danieli bikoṣepe a ba ri i si i nipasẹ ofin Ọlọrun rẹ̀.
6Nigbana ni awọn alakoso ati awọn arẹ bãlẹ wọnyi pejọ pọ̀ lẹsẹkanna lọdọ ọba, nwọn si wi bayi pe ki Dariusi ọba, ki o pẹ́.
7Gbogbo awọn olori alakoso ijọba, awọn bãlẹ ati awọn arẹ bãlẹ, awọn ìgbimọ, ati olori ogun jọ gbìmọ pọ̀ lati fi ofin ọba kan lelẹ, ati lati paṣẹ lile kan, pe ẹnikẹni ti o ba bère nkan lọwọ Ọlọrun tabi eniakenia niwọn ọgbọ̀n ọjọ bikoṣepe lọwọ rẹ, ọba, a o gbé e sọ sinu ihò kiniun.
8Njẹ nisisiyi, ọba, fi aṣẹ na lelẹ, ki o si fi ọwọ rẹ sinu iwe ki o máṣe yipada, gẹgẹ bi ofin awọn ara Media ati Persia, eyi ti a kò gbọdọ pada.
9Nigbana ni Dariusi fi ọwọ sinu iwe ati aṣẹ na.
10Nigbati Danieli si ti mọ̀ pe a kọ iwe na tan, o wọ ile rẹ̀ lọ; (a si ṣi oju ferese yara rẹ̀ silẹ siha Jerusalemu) o kunlẹ li ẽkun rẹ̀ nigba mẹta lõjọ, o gbadura, o si dupẹ niwaju Ọlọrun rẹ̀, gẹgẹ bi on ti iṣe nigba atijọ ri.
11Nigbana ni awọn ọkunrin wọnyi rìn wọle, nwọn si ri Danieli ngbadura, o si mbẹbẹ niwaju Ọlọrun rẹ̀.
12Nigbana ni nwọn wá, nwọn si wi niwaju ọba niti aṣẹ ọba pe, Kò ṣepe iwọ fi ọwọ sinu iwe pe, ẹnikan ti o ba bère ohunkohun lọwọ Ọlọrun tabi lọwọ enia kan niwọn ọgbọ̀n ọjọ, bikoṣe lọwọ rẹ, ọba, pe a o gbé e sọ sinu iho kiniun? Ọba si dahùn o wipe, Otitọ li ọ̀ran na, gẹgẹ bi ofin awọn ara Media ati Persia, ti a kò gbọdọ pada.
13Nigbana ni nwọn dahùn nwọn si wi niwaju ọba pe, Danieli ọkan ninu awọn ọmọ igbekun Juda kò kà ọ si, ọba, ati aṣẹ, nitori eyi ti iwọ fi ọwọ rẹ sinu iwe, ṣugbọn o ngbadura rẹ̀ nigba mẹta lõjọ.
14Nigbati ọba gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, inu rẹ̀ bajẹ gidigidi o si fi ọkàn rẹ̀ si Danieli lati gbà a silẹ: o si ṣe lãlã ati gbà a silẹ titi fi di igbati õrun wọ̀.
15Nigbana ni awọn ọkunrin wọnyi pejọ lẹsẹkanna lọdọ ọba, nwọn si wi fun ọba pe, Iwọ mọ̀, ọba, pe ofin awọn ara Media ati Persia ni pe: kò si aṣẹ tabi ofin ti ọba fi lelẹ ti a gbọdọ yipada.
16Nigbana ni ọba paṣẹ, nwọn si mu Danieli wá, nwọn si gbé e sọ sinu iho kiniun. Ọba si dahùn o wi fun Danieli pe, Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ nsìn laisimi, on o gbà ọ la.
17A si yi okuta kan wá, nwọn si gbé e ka oju iho na; ọba si fi oruka edidi rẹ̀ sami si i, ati oruka edidi awọn ijoye rẹ̀, ki ohunkohun máṣe yipada nitori Danieli.
18Nigbana ni Ọba wọ̀ ãfin rẹ̀ lọ, o si fi oru na gbàwẹ: bẹ̃li a kò si gbé ohun-elo orin kan wá siwaju rẹ̀: orun kò si wá si oju rẹ̀.
19Nigbana ni Ọba dide li afẹmọjumọ, o si yara kánkan lọ si ibi iho kiniun na.
20Nigbati o si sunmọ iho na o fi ohùnrére ẹkun kigbe si Danieli: ọba dahùn o si wi fun Danieli pe, Danieli! iranṣẹ Ọlọrun alãye! Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ nsìn laisimi, ha le gbà ọ lọwọ awọn kiniun bi?
21Nigbana ni Danieli wi fun ọba pe, ki ọba ki o pẹ.
22Ọlọrun mi ti ran angeli rẹ̀, o si dì awọn kiniun na lẹnu, ti nwọn kò fi le pa mi lara: gẹgẹ bi a ti ri mi lailẹṣẹ niwaju rẹ̀; ati niwaju rẹ pẹlu, ọba, emi kò si ṣe ohun buburu kan.
23Nigbana ni ọba yọ̀ gidigidi, o si paṣẹ pe, ki nwọn ki o fà Danieli jade kuro ninu iho. Bẹ̃li a si fa Danieli jade kuro ninu iho, a kò si ri ipalara lara rẹ̀, nitoriti o gbà Ọlọrun rẹ̀ gbọ́.
24Ọba si paṣẹ, pe ki a mu awọn ọkunrin wọnni wá, ti o fi Danieli sùn, nwọn si gbé wọn sọ sinu iho kiniun, awọn, ati awọn ọmọ wọn, ati awọn aya wọn. Ki nwọn ki o to de isalẹ iho, awọn kiniun bori wọn, nwọn si fọ egungun wọn tũtu.
25Nigbana ni Dariusi, ọba kọwe si gbogbo enia, orilẹ, ati ède ti o wà ni gbogbo aiye pe, Ki alafia ki o ma bi si i fun nyin.
26Mo paṣẹ pe, Ni gbogbo igberiko ijọba mi, ki awọn enia ki o ma warìri, ki nwọn si ma bẹ̀ru niwaju Ọlọrun Danieli, nitoripe on li Ọlọrun alãye, on si duro lailai, ati ijọba rẹ̀, eyi ti a kì yio le parun ni, ati agbara ijọba rẹ̀ yio si wà titi de opin.
27O ngbà ni, o si nyọ ni, o si nṣe iṣẹ-ami ati iṣẹ-iyanu li ọrun ati li aiye, ẹniti o gbà Danieli là lọwọ awọn kiniun.
28Bẹ̃ni Danieli yi si nṣe rere ni igba ijọba Dariusi, ati ni igba ijọba Kirusi, ara Persia.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Dan 6: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀