Dan 9
9
Daniẹli Gbadura fún Àwọn Eniyan Rẹ̀
1LI ọdun kini Dariusi, ọmọ Ahasuerusi, lati iru-ọmọ awọn ara Media wá, ti a fi jọba lori ilẹ-ọba awọn ara Kaldea;
2Li ọdun kini ijọba rẹ̀ li emi Danieli fiyesi lati inu iwe, iye ọdun, nipa eyi ti ọ̀rọ Oluwa tọ Jeremiah, woli wá, pe adọrin ọdun li on o mu pé lori idahoro Jerusalemu.
3Emi si kọju mi si Oluwa Ọlọrun, lati ma ṣafẹri nipa adura ati ẹ̀bẹ, pẹlu àwẹ, ninu aṣọ-ọ̀fọ, ati ẽru.
4Emi si gbadura si Oluwa Ọlọrun mi, mo si ṣe ijẹwọ mi, mo si wipe, Oluwa, iwọ Ọlọrun ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru, ti npa majẹmu ati ãnu mọ́ fun awọn ti o fẹ ẹ, ati fun awọn ti o pa ofin rẹ̀ mọ́;
5Awa ti ṣẹ̀, awa si ti nda ẹ̀ṣẹ, awa si ti ṣe buburu gidigidi, awa si ti ṣọ̀tẹ, ani nipa kikuro ninu ẹkọ́ rẹ, ati idajọ rẹ:
6Bẹ̃li awa kò si fi eti si awọn iranṣẹ rẹ, awọn woli, ti o sọ̀rọ li orukọ rẹ fun awọn ọba wa, awọn ọmọ-alade wa, ati awọn baba wa, ati fun gbogbo awọn enia ilẹ wa.
7Oluwa tirẹ li ododo, ṣugbọn tiwa ni itiju, gẹgẹ bi o ti ri loni; fun awọn enia Juda, ati fun awọn olugbe Jerusalemu, ati fun gbogbo Israeli, ti o sunmọ tosi, ati awọn ti o jina rére; ni gbogbo ilẹkilẹ, nibiti o gbe ti le wọn rè, nitori ẹ̀ṣẹ wọn ti nwọn ti ṣẹ̀ si ọ.
8Oluwa, tiwa ni itiju, ti awọn ọba wa, ati awọn olori wa, ati ti awọn baba wa, nitori ti awa ti ṣọ̀tẹ si ọ.
9Sibẹ ti Oluwa Ọlọrun wa li ãnu ati idariji bi awa tilẹ ṣọ̀tẹ si i;
10Bẹ̃li awa kò si gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́, lati ma rìn nipa ofin ti o gbé kalẹ niwaju wa lati ọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn woli wá.
11Bẹ̃ni gbogbo Israeli ti ṣẹ̀ si ofin rẹ, ani nipa kikuro, ki nwọn ki o máṣe gbà ohùn rẹ gbọ́; nitorina li a ṣe yi egún dà si ori wa, ati ibura na ti a kọ sinu ofin Mose, iranṣẹ Ọlọrun, nitori ti awa ti ṣẹ̀ si i.
12On si mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ, eyi ti o sọ si wa, ati si awọn onidajọ wa ti o nṣe idajọ fun wa, nipa eyi ti o fi mu ibi nla bá wa: iru eyi ti a kò ti iṣe si gbogbo abẹ ọrun, gẹgẹ bi a ti ṣe sori Jerusalemu.
13Gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin Mose, gbogbo ibi wọnyi wá sori wa: bẹ̃li awa kò si wá ojurere niwaju Oluwa, Ọlọrun wa, ki awa ki o le yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ wa, ki a si moye otitọ rẹ.
14Nitorina li Oluwa ṣe fiyesi ibi na, ti o si mu u wá sori wa; nitoripe olododo li Oluwa Ọlọrun wa ni gbogbo iṣẹ rẹ̀ ti o nṣe: ṣugbọn awa kò gbà ohùn rẹ̀ gbọ́.
15Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun wa, iwọ ti o ti fi ọwọ agbara mu awọn enia rẹ jade lati Egipti wá, ti iwọ si ti gba orukọ fun ara rẹ gẹgẹ bi o ti wà loni: awa ti ṣẹ̀, awa si ti ṣe buburu gidigidi.
16Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo ododo rẹ, lõtọ, jẹ ki ibinu ati irunu rẹ yi kuro lori Jerusalemu, ilu rẹ, òke mimọ́ rẹ: nitori ẹ̀ṣẹ wa, ati ẹ̀ṣẹ awọn baba wa ni Jerusalemu, ati awọn enia rẹ fi di ẹ̀gan si gbogbo awọn ti o yi wa ka.
17Njẹ nitorina, Ọlọrun wa, gbọ́ adura ọmọ-ọdọ rẹ, ati ẹ̀bẹ rẹ̀, ki o si mu ki oju rẹ ki o mọlẹ si ibi-mimọ́ rẹ ti o dahoro, nitori ti Oluwa.
18Tẹ eti rẹ silẹ, Ọlọrun mi, ki o si gbọ́: ṣi oju rẹ, ki o si wò idahoro wa, ati ilu ti a nfi orukọ rẹ pè: nitoriti awa kò gbé ẹ̀bẹ wa kalẹ niwaju rẹ nitori ododo wa, ṣugbọn nitori ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ nla.
19Oluwa, gbọ́, Oluwa, dariji: Oluwa, tẹ eti rẹ silẹ ki o si ṣe; máṣe jafara, nitori ti iwọ tikararẹ, Ọlọrun mi: nitori orukọ rẹ li a fi npè ilu rẹ, ati awọn enia rẹ.
Gabraeli Túmọ̀ Àlá náà
20Bi emi si ti nwi, ti emi ngbadura, ati bi emi si ti njẹwọ ẹṣẹ mi, ati ẹ̀ṣẹ Israeli awọn enia mi, ti emi si ngbé ẹbẹ mi kalẹ niwaju Oluwa, Ọlọrun mi, nitori òke mimọ́ Ọlọrun mi.
21Bẹni, bi mo ti nwi lọwọ ninu adura mi, ọkunrin na, Gabrieli ti mo ti ri ni iran mi li atetekọṣe, li a mu lati fò wá kankan, o de ọdọ mi niwọn akokò ẹbọ aṣãlẹ.
22O mu mi mọ̀, o si mba mi sọ̀rọ wipe, Danieli, mo jade wá nisisiyi lati fi oye fun ọ.
23Ni ipilẹṣẹ ẹ̀bẹ rẹ li ọ̀rọ ti jade wá, emi si wá lati fi hàn fun ọ, nitoriti iwọ iṣe ayanfẹ gidigidi: nitorina, moye ọ̀ran na, ki o si kiyesi iran na.
24Adọrin ọ̀sẹ li a pinnu sori awọn enia rẹ, ati sori ilu mimọ́ rẹ, lati ṣe ipari irekọja, ati lati fi edidi di ẹ̀ṣẹ, ati lati ṣe ilaja fun aiṣedẽde ati lati mu ododo ainipẹkun wá ati lati ṣe edidi iran ati woli, ati lati fi ororo yàn Ẹni-mimọ́ julọ nì.
25Nitorina ki iwọ ki o mọ̀, ki o si ye ọ, pe lati ijade lọ ọ̀rọ na lati tun Jerusalemu ṣe, ati lati tun u kọ́, titi de igba ọmọ-alade Ẹni-ororo na, yio jẹ ọ̀sẹ meje, ati ọ̀sẹ mejilelọgọta: a o si tun igboro rẹ̀ ṣe, a o mọdi rẹ̀, ṣugbọn ni igba wahala.
26Lẹhin ọ̀sẹ mejilelọgọta na li a o ke Ẹni-ororo na kuro, kì yio si si ẹnikan fun u, ati awọn enia ọmọ-alade kan ti yio wá ni yio pa ilu na ati ibi-mimọ́ run; opin ẹniti mbọ yio dabi ikún omi, ati ogun titi de opin, eyi ni ipari idahoro.
27On o si fi idi majẹmu kan mulẹ fun ọ̀pọlọpọ niwọn ọ̀sẹ kan: ati lãrin ọ̀sẹ na ni yio mu ki a dẹkun ẹbọ, ati ọrẹ-ẹbọ, irira isọdahoro yio si duro lori ibi-mimọ́ titi idajọ ti a pinnu yio túdà sori asọnidahoro.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Dan 9: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: