Deu 11
11
Títóbi OLUWA
1NITORINA ki iwọ ki o fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, ki o si ma pa ikilọ̀ rẹ̀, ati ìlana rẹ̀, ati idajọ rẹ̀, ati ofin rẹ̀ mọ́, nigbagbogbo.
2Ki ẹnyin ki o si mọ̀ li oni: nitoripe awọn ọmọ nyin ti emi nsọ fun ti kò mọ̀, ti kò si ri ibawi OLUWA Ọlọrun nyin, titobi rẹ̀, ọwọ́ agbara rẹ̀, ati ninà apa rẹ̀,
3Ati iṣẹ-àmi rẹ̀, ati iṣẹ rẹ̀, ti o ṣe lãrin Egipti, si Farao ọba Egipti, ati si gbogbo ilẹ rẹ̀;
4Ati ohun ti o ṣe si ogun Egipti, si ẹṣin wọn, ati kẹkẹ́-ogun wọn; bi o ti mu ki omi Okun Pupa bò wọn mọlẹ bi nwọn ti nlepa nyin lọ, ati bi OLUWA ti run wọn titi di oni-oloni;
5Ati bi o ti ṣe si nyin li aginjù, titi ẹnyin fi dé ihin yi;
6Ati bi o ti ṣe si Datani ati Abiramu, awọn ọmọ Eliabu, ọmọ Reubeni; bi ilẹ ti yà ẹnu rẹ̀, ti o si gbe wọn mì, ati ara ile wọn, ati agọ́ wọn, ati ohun alãye gbogbo ti o tẹle wọn, lãrin gbogbo Israeli:
7Ṣugbọn oju nyin ti ri gbogbo iṣẹ nla OLUWA ti o ṣe.
Ibukun Ilẹ̀ Ìlérí náà
8Nitorina ki ẹnyin ki o pa gbogbo ofin mọ́ ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin li oni, ki ẹnyin ki o le lagbara, ki ẹnyin ki o si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, ki ẹ si gbà ilẹ na, nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a;
9Ati ki ẹnyin ki o le mu ọjọ́ nyin pẹ ni ilẹ na, ti OLUWA ti bura fun awọn baba nyin, lati fi fun wọn ati fun irú-ọmọ wọn, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.
10Nitoripe ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a, kò dabi ilẹ Egipti, nibiti ẹnyin ti jade wá, nibiti iwọ gbìn irugbìn rẹ, ti iwọ si nfi ẹsẹ̀ rẹ bomirin i, bi ọgbà ewebẹ̀:
11Ṣugbọn ilẹ na, nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a, ilẹ òke ati afonifoji ni, ti o si nmu omi òjo ọrun:
12Ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ nṣe itọju; oju OLUWA Ọlọrun rẹ mbẹ lara rẹ̀ nigbagbogbo, lati ìbẹrẹ ọdún dé opin ọdún.
13Yio si ṣe, bi ẹnyin ba fetisi ofin mi daradara, ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin li oni, lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin, ati lati ma sìn i pẹlu àiya nyin gbogbo, ati pẹlu ọkàn nyin gbogbo,
14Nigbana li emi o ma fun nyin li òjo ilẹ nyin li akokò rẹ̀, òjo akọ́rọ̀ ati òjo àrọkuro, ki iwọ ki o le ma kó ọkà rẹ, ati ọti-waini rẹ, ati oróro rẹ sinu ile.
15Emi o si fi koriko sinu pápa rẹ fun ohunọ̀sin rẹ, ki iwọ ki o le jẹun ki o si yó.
16Ẹ ma ṣọ́ ara nyin, ki a má ba tàn àiya nyin jẹ, ki ẹ má si ṣe yapa, ki ẹ si sìn ọlọrun miran, ki ẹ si ma bọ wọn;
17Ibinu OLUWA a si rú si nyin, on a si sé ọrun, ki òjo ki o má ba sí, ati ki ilẹ ki o má ba so eso rẹ̀; ẹnyin a si run kánkán kuro ni ilẹ rere na ti OLUWA fi fun nyin.
18Ẹ fi ọ̀rọ mi wọnyi si àiya nyin ati si ọkàn nyin, ki ẹ si so wọn mọ́ ọwọ́ nyin fun àmi, ki nwọn ki o si ma ṣe ọjá-igbaju niwaju nyin.
19Ki ẹnyin ki o si ma fi wọn kọ́ awọn ọmọ nyin, ki ẹnyin ma fi wọn ṣe ọ̀rọ isọ nigbati iwọ ba joko ninu ile rẹ, ati nigbati iwọ ba nrìn li ọ̀na, nigbati iwọ ba dubulẹ, ati nigbati iwọ ba dide.
20Ki iwọ ki o si kọ wọn sara opó ile rẹ, ati sara ilẹkun-ọ̀na-ode rẹ:
21Ki ọjọ́ nyin ki o le ma pọ̀si i, ati ọjọ́ awọn ọmọ nyin, ni ilẹ na ti OLUWA bura fun awọn baba nyin lati fi fun wọn, bi ọjọ́ ọrun lori ilẹ aiye.
22Nitoripe bi ẹnyin ba pa gbogbo ofin yi mọ́ gidigidi, ti mo palaṣẹ fun nyin, lati ma ṣe e; lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin, lati ma rìn ni gbogbo ọ̀na rẹ̀, ati lati faramọ́ ọ;
23Nigbana ni OLUWA yio lé gbogbo awọn orilẹ-ède wọnyi jade kuro niwaju nyin, ẹnyin o si gbà orilẹ-ède ti o tobi ti o si lagbara jù nyin lọ.
24Ibi gbogbo ti atẹlẹsẹ̀ nyin ba tẹ̀ yio jẹ́ ti nyin: lati aginjù nì, ati Lebanoni, lati odò nla nì, odò Euferate, ani dé ikẹhin okun ni yio jẹ́ opinlẹ nyin.
25Kò sí ọkunrin kan ti yio le duro niwaju nyin: OLUWA Ọlọrun nyin, yio fi ìbẹru nyin ati ìfoiya nyin sara gbogbo ilẹ ti ẹnyin o tẹ̀, bi on ti wi fun nyin.
26Wò o, emi fi ibukún ati egún siwaju nyin li oni;
27Ibukún, bi ẹnyin ba gbà ofin OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́, ti mo palaṣẹ fun nyin li oni:
28Ati egún, bi ẹnyin kò ba gbà ofin OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́ ti ẹnyin ba si yipada kuro li ọ̀na ti mo palaṣẹ fun nyin li oni, lati ma tọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ti ẹnyin kò mọ̀ rí.
29Yio si ṣe, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a, ki iwọ ki o ma sure lori òke Gerisimu, ki iwọ ki o si ma gegun lori òke Ebali.
30Awọn kọ ha wà ni ìha keji Jordani, li ọ̀na ìwọ-õrùn, ni ilẹ awọn ara Kenaani, ti ngbé Araba ti o kọjusi Gilgali, lẹba igbó More?
31Nitoripe ẹnyin o gòke Jordani lati wọle ati lati gbà ilẹ na, ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin, ẹnyin o si gbà a, ẹnyin o si ma gbé inu rẹ̀.
32Ki ẹnyin ki o si ma kiyesi ati ma ṣe gbogbo ìlana ati idajọ wọnni, ti mo fi siwaju nyin li oni.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Deu 11: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: