Deu 6
6
Òfin Ńlá
1NJẸ wọnyi li ofin, ìlana, ati idajọ, ti OLUWA Ọlọrun nyin ti palaṣẹ lati ma kọ́ nyin, ki ẹnyin ki o le ma ṣe wọn ni ilẹ nibiti ẹnyin gbé nlọ lati gbà a:
2Ki iwọ ki o le ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ, lati pa gbogbo ìlana rẹ̀ ati ofin rẹ̀ mọ́, ti emi fi fun ọ, iwọ, ati ọmọ rẹ, ati ọmọ ọmọ rẹ, li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo; ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ.
3Nitorina gbọ́, Israeli, ki o si ma kiyesi i lati ṣe e; ki o le dara fun ọ, ati ki ẹnyin ki o le ma pọ̀si i li ọ̀pọlọpọ, bi OLUWA Ọlọrun awọn baba rẹ ti ṣe ileri fun ọ, ni ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.
4Gbọ́, Israeli: OLUWA Ọlọrun wa, OLUWA kan ni.
5Ki iwọ ki o si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbara rẹ fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ.
6Ati ọ̀rọ wọnyi, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ki o ma wà ni àiya rẹ:
7Ki iwọ ki o si ma fi wọn kọ́ awọn ọmọ rẹ gidigidi, ki iwọ ki o si ma fi wọn ṣe ọ̀rọ isọ nigbati iwọ ba joko ninu ile rẹ, ati nigbati iwọ ba nrìn li ọ̀na, ati nigbati iwọ ba dubulẹ, ati nigbati iwọ ba dide.
8Ki iwọ ki o si so wọn mọ́ ọwọ́ rẹ fun àmi, ki nwọn ki o si ma ṣe ọja-igbaju niwaju rẹ.
9Ki iwọ ki o si kọ wọn sara opó ile rẹ, ati sara ilẹkun ọ̀na-ode rẹ.
Ìkìlọ̀ nípa Ìwà Àìgbọràn
10Yio si ṣe, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na, ti o bura fun awọn baba rẹ, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, lati fun ọ ni ilu ti o tobi ti o si dara, ti iwọ kò mọ̀,
11Ati ile ti o kún fun ohun rere gbogbo, ti iwọ kò kún, ati kanga wiwà, ti iwọ kò wà, ọgbà-àjara ati igi oróro, ti iwọ kò gbìn; nigbati iwọ ba jẹ tán ti o ba si yó;
12Kiyesara rẹ ki iwọ ki o má ba gbagbé OLUWA ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá, kuro li oko-ẹrú.
13Bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ, ki o si ma sìn i, ki o si ma bura li orukọ rẹ̀.
14Ẹnyin kò gbọdọ tọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ninu oriṣa awọn enia, ti o yi nyin ká kiri;
15Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ Ọlọrun owú ni ninu nyin; ki ibinu OLUWA Ọlọrun rẹ ki o má ba rú si ọ, on a si run ọ kuro lori ilẹ.
16Ẹnyin kò gbọdọ dán OLUWA Ọlọrun nyin wò, bi ẹnyin ti dan a wò ni Massa.
17Ki ẹnyin ki o pa ofin OLUWA Ọlọrun nyin mọ́ gidigidi, ati ẹrí rẹ̀, ati ìlana rẹ̀, ti o filelẹ li aṣẹ fun ọ.
18Ki iwọ ki o ma ṣe eyiti o tọ́, ti o si dara li oju OLUWA: ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le wọ̀ ilẹ rere nì lọ ki o si gbà a, eyiti OLUWA bura fun awọn baba rẹ,
19Lati tì awọn ọtá rẹ gbogbo jade kuro niwaju rẹ, bi OLUWA ti wi.
20Nigbati ọmọ rẹ ba bi ọ lère lẹhin-ọla, wipe, Kini èredi ẹrí, ati ìlana, ati idajọ wọnyi, ti OLUWA Ọlọrun filelẹ li aṣẹ fun nyin?
21Nigbana ni ki iwọ ki o wi fun ọmọ rẹ pe, Ẹrú Farao li awa ti ṣe ni Egipti; OLUWA si fi ọwọ́ agbara mú wa jade lati Egipti wá.
22OLUWA si fi àmi ati iṣẹ-iyanu, ti o tobi ti o si buru hàn lara Egipti, lara Farao, ati lara gbogbo ara ile rẹ̀ li oju wa:
23O si mú wa jade lati ibẹ̀ wá, ki o le mú wa wọ̀ inu rẹ̀, lati fun wa ni ilẹ na ti o bura fun awọn baba wa.
24OLUWA si pa a laṣẹ fun wa, lati ma ṣe gbogbo ìlana wọnyi, lati ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun wa, fun ire wa nigbagbogbo, ki o le pa wa mọ́ lãye, bi o ti ri li oni yi.
25Yio si jẹ́ ododo wa, bi awa ba nṣọ́ ati ma ṣe gbogbo ofin wọnyi niwaju OLUWA Ọlọrun wa, bi o ti paṣẹ fun wa.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Deu 6: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: