PAULU, Aposteli Jesu Kristi nipa ifẹ Ọlọrun, si awọn enia mimọ́ ti o wà ni Efesu, ati si awọn onigbagbọ ninu Kristi Jesu:
Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kristi Oluwa.
Olubukún li Ọlọrun ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, ẹniti o ti fi gbogbo ibukún ẹmí ninu awọn ọrun bukún wa ninu Kristi:
Ani gẹgẹ bi o ti yàn wa ninu rẹ̀ ṣaju ipilẹṣẹ aiye, ki awa ki o le jẹ mimọ́ ati alailabùku niwaju rẹ̀ ninu ifẹ:
Ẹniti o ti yàn wa tẹlẹ si isọdọmọ nipa Jesu Kristi fun ara rẹ̀, gẹgẹ bi ìdunnú ifẹ rẹ̀:
Fun iyin ogo ore-ọfẹ rẹ̀, eyiti o dà lù wa ninu Ayanfẹ nì:
Ninu ẹniti awa ni irapada wa nipa ẹjẹ rẹ̀, idariji ẹ̀ṣẹ wa, gẹgẹ bi ọrọ̀ ore-ọfẹ rẹ̀;
Eyiti o sọ di pupọ fun wa ninu gbogbo ọgbọ́n ati oye,
Ẹniti o ti sọ ohun ijinlẹ ifẹ rẹ̀ di mimọ̀ fun wa, gẹgẹ bi idunnú rẹ̀, eyiti o ti pinnu ninu rẹ̀,
Fun iṣẹ iriju ti kikun akoko na, ki o le ko ohun gbogbo jọ ninu Kristi, iba ṣe eyiti mbẹ ninu awọn ọrun, tabi eyiti mbẹ li aiye, ani ninu rẹ̀:
Ninu ẹniti a fi wa ṣe ini rẹ̀ pẹlu, awa ti a ti yan tẹlẹ, gẹgẹ bi ipinnu ẹniti nṣiṣẹ ohun gbogbo gẹgẹ bi ìmọ ifẹ rẹ̀:
Ki awa ki o le jẹ fun iyin ogo rẹ̀, awa ti a ti ni ireti ṣaju ninu Kristi;
Ninu ẹniti, ẹnyin pẹlu, nigbati ẹnyin ti gbọ ọrọ otitọ nì, ihinrere igbala nyin, ninu ẹniti nigbati ẹnyin ti gbagbọ pẹlu, a fi Ẹmi Mimọ́ ileri nì ṣe edidi nyin,
Eyiti iṣe ẹri ini wa, fun irapada ohun ini Ọlọrun si iyìn ogo rẹ̀.
Nitori eyi, emi pẹlu, nigbati mo ti gburó igbagbọ ti mbẹ larin nyin ninu Jesu Oluwa, ati ifẹ nyin si gbogbo awọn enia mimọ́