Eks 11

11
Mose Kéde Ikú Àwọn Àkọ́bí
1OLUWA si wi fun Mose pe, Emi o tun mú iyọnu kan wá sara Farao, ati sara Egipti; lẹhin eyinì ni on o jọwọ nyin lọwọ lọ lati ihin: nigbati on o jẹ ki ẹ lọ, àtitán ni yio tì nyin jade nihin.
2Wi nisisiyi li eti awọn enia wọnyi, ki olukuluku ọkunrin ki o bère lọdọ aladugbo rẹ̀ ati olukuluku obinrin lọdọ aladugbo rẹ̀, ohun-èlo fadaka, ati ohun-èlo wurà.
3OLUWA si fi ojurere fun awọn enia na li oju awọn ara Egipti. Pẹlupẹlu Mose ọkunrin nì o pọ̀ gidigidi ni ilẹ Egipti, li oju awọn iranṣẹ Farao, ati li oju awọn enia na.
4Mose si wipe, Bayi li OLUWA wi, Lãrin ọganjọ li emi o jade lọ sãrin Egipti:
5Gbogbo awọn akọ́bi ti o wà ni ilẹ Egipti ni yio si kú, lati akọ́bi Farao lọ ti o joko lori itẹ́ rẹ̀, titi yio si fi dé akọ́bi iranṣẹbinrin ti o wà lẹhin ọlọ; ati gbogbo akọ́bi ẹran.
6Ẹkún nla yio si wà ni gbogbo ilẹ Egipti, eyiti irú rẹ̀ kò si ri, ti ki yio si si irú rẹ̀ mọ́.
7Ṣugbọn si ọkan ninu awọn ọmọ Israeli li ajá ki yio yọ ahọn rẹ̀, si enia tabi si ẹran: ki ẹnyin ki o le mọ̀ bi OLUWA ti fi ìyatọ sãrin awọn ara Egipti ati Israeli.
8Gbogbo awọn iranṣẹ rẹ wọnyi ni yio si sọkalẹ tọ̀ mi wá, ti nwọn o si fori wọn balẹ fun mi pe, Iwọ jade lọ ati gbogbo awọn enia ẹhin rẹ: lẹhin ìgba na li emi o to jade. O si jade kuro niwaju Farao ni ibinu nla.
9OLUWA si wi fun Mose pe, Farao ki yio gbọ́ tirẹ; ki a le sọ iṣẹ-iyanu mi di pupọ̀ ni ilẹ Egipti.
10Mose ati Aaroni si ṣe gbogbo iṣẹ-iyanu wọnyi niwaju Farao: OLUWA si mu àiya Farao le, bẹ̃ni kò si fẹ́ jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o jade lọ kuro ni ilẹ rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Eks 11: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀