Eks 16

16
1NWỌN si ṣí lati Elimu, gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli si dé ijù Sini, ti o wà li agbedemeji Elimu on Sinai, ni ijọ́ kẹdogun oṣù keji, lẹhin igbati nwọn jade kuro ni ilẹ Egipti.
2Gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli si nkùn si Mose ati si Aaroni ni ijù na:
3Awọn ọmọ Israeli si wi fun wọn pe, Awa iba ti ti ọwọ́ OLUWA kú ni Egipti, nigbati awa joko tì ìkoko ẹran, ti awa njẹ ajẹyo; ẹnyin sá mú wa jade wá si ijù yi, lati fi ebi pa gbogbo ijọ yi.
4Nigbana li OLUWA sọ fun Mose pe, Kiyesi i, emi o rọ̀jo onjẹ fun nyin lati ọrun wá; awọn enia yio si ma jade lọ ikó ìwọn ti õjọ li ojojumọ́, ki emi ki o le dan wọn wò, bi nwọn o fẹ́ lati ma rìn nipa ofin mi, bi bẹ̃kọ.
5Yio si ṣe, li ọjọ́ kẹfa, nwọn o si pèse eyiti nwọn múwa; yio si to ìwọn meji eyiti nwọn ima kó li ojojumọ́.
6Mose ati Aaroni si wi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli pe, Li aṣalẹ, li ẹnyin o si mọ̀ pe, OLUWA li o mú nyin jade lati Egipti wá:
7Ati li owurọ̀ li ẹnyin o si ri ogo OLUWA; nitoriti o gbọ́ kikùn nyin si OLUWA: ta si li awa, ti ẹnyin nkùn si wa?
8Mose si wi pe, Bayi ni yio ri nigbati OLUWA yio fun nyin li ẹran jẹ li aṣalẹ, ati onjẹ ajẹyo li owurọ̀; nitoriti OLUWA gbọ́ kikùn nyin ti ẹnyin kùn si i: ta si li awa? kikùn nyin ki iṣe si wa, bikoṣe si OLUWA.
9Mose si sọ fun Aaroni pe, Sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ sunmọ iwaju OLUWA, nitoriti o ti gbọ́ kikùn nyin.
10O si ṣe, nigbati Aaroni nsọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, nwọn si bojuwò ìha ijù, si kiyesi i, ogo OLUWA hàn li awọsanma na.
11OLUWA si sọ fun Mose pe,
12Emi ti gbọ́ kikùn awọn ọmọ Israeli: sọ fun wọn pe, Li aṣalẹ ẹnyin o jẹ ẹran, ati li owurọ̀ a o si fi onjẹ kún nyin; ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
13O si ṣe li aṣalẹ ni aparò fò dé, nwọn si bò ibudó mọlẹ; ati li owurọ̀ ìri si sẹ̀ yi gbogbo ibudó na ká.
14Nigbati ìri ti o sẹ̀ bolẹ si fà soke, si kiyesi i, lori ilẹ ijù na, ohun ribiribi, o kere bi ìri didì li ori ilẹ.
15Nigbati awọn ọmọ Israeli si ri i, nwọn wi fun ara wọn pe, Kili eyi? nitoriti nwọn kò mọ̀ ohun na. Mose si wi fun wọn pe, Eyi li onjẹ ti OLUWA fi fun nyin lati jẹ.
16Eyi li ohun ti OLUWA ti palaṣẹ, ki olukuluku ki o ma kó bi ìwọn ijẹ rẹ̀; òṣuwọn omeri kan fun ẹni kọkan, gẹgẹ bi iye awọn enia nyin, ki olukuluku nyin mú fun awọn ti o wà ninu agọ́ rẹ̀.
17Awọn ọmọ Israeli si ṣe bẹ̃, nwọn si kó, ẹlomiran pupọ̀jù, ẹlomiran li aito.
18Nigbati nwọn si fi òṣuwọn omeri wọ̀n ọ, ẹniti o kó pupọ̀ kò ni nkan lé, ẹniti o si kó kere jù, kò ṣe alaito nwọn si kó olukuluku bi ijẹ tirẹ̀.
19Mose si wi fun wọn pe, Ki ẹnikan ki o má kùsilẹ ninu rẹ̀ titi di owurọ̀.
20Ṣugbọn nwọn kò gbọ́ ti Mose; bẹ̃li ẹlomiran si kùsilẹ ninu rẹ̀ titi di owurọ̀, o si di idin, o si rùn; Mose si binu si wọn.
21Nwọn si nkó o li orowurọ̀, olukuluku bi ijẹ tirẹ̀; nigbati õrùn si mu, o yọ́.
22O si ṣe ni ijọ́ kẹfa, nwọn kó ìwọn onjẹ ẹrinmeji, omeri meji fun ẹni kọkan: gbogbo awọn olori ijọ na si wá nwọn sọ fun Mose.
23O si wi fun wọn pe, Eyi na li OLUWA ti wi pe, Ọla li ọjọ́ isimi, isimi mimọ́ fun OLUWA; ẹ yan eyiti ẹnyin ni iyan, ki ẹ si bọ̀ eyiti ẹnyin ni ibọ̀; eyiti o si kù, ẹ fi i silẹ lati pa a mọ́ dé owurọ̀.
24Nwọn si fi i silẹ titi di owurọ̀, bi Mose ti paṣẹ fun wọn; kò si rùn, bẹ̃ni kò sí idin ninu rẹ̀.
25Mose si wi pe, Ẹ jẹ eyinì li oni; nitori oni li ọjọ́ isimi fun OLUWA: li oni ẹnyin ki yio ri i ninu igbẹ́.
26Li ọjọ́ mẹfa li ẹ o ma kó o; ṣugbọn li ọjọ́ keje li ọjọ́ isimi, ninu rẹ̀ ni ki yio si nkan.
27O si ṣe li ọjọ́ keje awọn kan ninu awọn enia jade lọ ikó, nwọn kò si ri nkan.
28OLUWA si wi fun Mose pe, Ẹ o ti kọ̀ lati pa aṣẹ mi ati ofin mi mọ́ pẹ to?
29Wò o, OLUWA sa ti fi ọjọ́ isimi fun nyin, nitorina li o ṣe fi onjẹ ijọ́ meji fun nyin li ọjọ́ kẹfa; ki olukuluku ki o joko ni ipò rẹ̀, ki ẹnikẹni ki o máṣe jade kuro ni ipò rẹ̀ li ọjọ́ keje.
30Bẹ̃li awọn enia na simi li ọjọ́ keje.
31Awọn ara ile Israeli si pè orukọ rẹ̀ ni Manna; o si dabi irugbìn korianderi, funfun; adùn rẹ̀ si dabi àkara fẹlẹfẹlẹ ti a fi oyin ṣe.
32Mose si wipe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ, Ẹ kún òṣuwọn omeri kan ninu rẹ̀ lati pamọ́ fun irandiran nyin; ki nwọn ki o le ma ri onjẹ ti mo fi bọ́ nyin ni ijù, nigbati mo mú nyin jade kuro ni ilẹ Egipti.
33Mose si wi fun Aaroni pe, Mú ìkoko kan, ki o si fi òṣuwọn omeri kan ti o kún fun manna sinu rẹ̀, ki o si gbé e kalẹ niwaju OLUWA, lati pa a mọ́ fun irandiran nyin.
34Bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃li Aaroni gbé e kalẹ niwaju ibi Ẹrí lati pa a mọ́.
35Awọn ọmọ Israeli si jẹ manna li ogoji ọdún, titi nwọn fi dé ilẹ ti a tẹ̀dó; nwọn jẹ manna titi nwọn fi dé àgbegbe ilẹ Kenaani.
36Njẹ òṣuwọn omeri kan ni idamẹwa efa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Eks 16: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀