Eks 7

7
1OLUWA si wi fun Mose pe, Wò o, emi fi ọ ṣe ọlọrun fun Farao: Aaroni arakunrin rẹ ni yio si ma ṣe wolĩ rẹ.
2Iwọ o sọ gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun ọ: Aaroni arakunrin rẹ ni yio si ma sọ fun Farao pe, ki o rán awọn ọmọ Israeli jade ni ilẹ rẹ̀.
3Emi o si mu Farao li àiya le, emi o si sọ iṣẹ-àmi mi ati iṣẹ-iyanu mi di pupọ̀ ni ilẹ Egipti.
4Ṣugbọn Farao ki yio gbọ́ ti nyin, emi o si fi ọwọ́ mi lé Egipti, emi o si fi idajọ nla mú awọn ogun mi, ani awọn ọmọ Israeli enia mi, jade kuro ni ilẹ Egipti.
5Awọn ara Egipti yio si mọ̀ pe, emi li OLUWA, nigbati mo ba nà ọwọ́ mi lé Egipti, ti mo si mú awọn ọmọ Israeli jade kuro lãrin wọn.
6Mose ati Aaroni si ṣe bẹ̃; bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn; bẹ̃ni nwọn ṣe.
7Mose jẹ́ ẹni ọgọrin ọdún, Aaroni si jẹ́ ẹni ọgọrin ọdún o le mẹta, nigbati nwọn sọ̀rọ fun Farao.
Ọ̀pá Aaroni
8OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe,
9Nigbati Farao yio ba wi fun nyin pe, Ẹ fi iṣẹ-iyanu kan hàn: nigbana ni ki iwọ ki o wi fun Aaroni pe, Mú ọpá rẹ, ki o si fi i lelẹ niwaju Farao, yio si di ejò.
10Mose ati Aaroni si wọle tọ̀ Farao lọ, nwọn si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn: Aaroni si fi ọpá rẹ̀ lelẹ niwaju Farao ati niwaju awọn iranṣẹ rẹ̀, o si di ejò.
11Nigbana ni Farao pẹlu pè awọn ọlọgbọ́n ati awọn oṣó: awọn pẹlu, ani awọn alalupayida Egipti, si fi idán wọn ṣe bẹ̃ gẹgẹ.
12Nitoriti olukuluku nwọn fi ọpá rẹ̀ lelẹ, nwọn si di ejò: ṣugbọn ọpá Aaroni gbe ọpá wọn mì.
13Aiya Farao si le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.
Ìṣẹ̀lẹ̀ Burúkú ṣẹ̀ ní Ijipti
14OLUWA si wi fun Mose pe, Aiya Farao di lile, o kọ̀ lati jẹ ki awọn enia na ki o lọ.
15Tọ̀ Farao lọ li owurọ̀; kiyesi i, o njade lọ si odò; ki iwọ ki o si duro lati pade rẹ̀ leti odò; ati ọpá nì ti o di ejò ni ki iwọ ki o mú li ọwọ́ rẹ.
16Iwọ o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu, li o rán mi si ọ wipe, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi ni ijù: si kiyesi i, titi di isisiyi iwọ kò gbọ́.
17Bayi li OLUWA wi, Ninu eyi ni iwọ o fi mọ̀ pe emi li OLUWA: kiyesi i, emi o fi ọpá ti o wà li ọwọ́ mi lù omi ti o wà li odò, nwọn o si di ẹ̀jẹ.
18Ẹja ti o wà ninu odò na yio si kú, odò na yio si ma rùn; awọn ara Egipti yio si korira ati ma mu ninu omi odò na.
19OLUWA si sọ fun Mose pe, Wi fun Aaroni pe, Mú ọpá rẹ, ki o si nà ọwọ́ rẹ si oju omi Egipti wọnni, si odò wọn, si omi ṣiṣàn wọn, ati ikudu wọn, ati si gbogbo ikojọpọ omi wọn, ki nwọn le di ẹ̀jẹ; ẹ̀jẹ yio si wà ni gbogbo ilẹ Egipti, ati ninu ohun-èlo igi, ati ninu ohun-èlo okuta.
20Mose ati Aaroni si ṣe bẹ̃ bi OLUWA ti fi aṣẹ fun wọn; o si gbé ọpá na soke o si lù omi ti o wà li odò li oju Farao, ati li oju awọn iranṣẹ rẹ̀; a si sọ gbogbo omi ti o wà li odò na di ẹ̀jẹ.
21Ẹja ti o wà li odò si kú; odò na si nrùn, awọn ara Egipti kò si le mu ninu omi odò na; ẹ̀jẹ si wà ni gbogbo ilẹ Egipti,
22Awọn alalupayida Egipti si fi idán wọn ṣe bẹ̃: àiya Farao si le, bẹ̃ni kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.
23Farao si pada o lọ si ile rẹ̀, kò si fi ọkàn rẹ̀ si eyi pẹlu.
24Gbogbo awọn ara Egipti si wàlẹ yi odò na ká fun omi mimu; nitoriti nwọn kò le mu ninu omi na.
25Ọjọ́ meje si pé, lẹhin igbati OLUWA lù odò na.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Eks 7: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀